1 Ọ̀rọ̀ Jeremaya, ọmọ Hilikaya, ọ̀kan ninu àwọn alufaa tí ó wà ní Anatoti, ní ilẹ̀ Bẹnjamini nìyí.
2 Nígbà ayé Josaya, ọmọ Amoni, ọba Juda, ní ọdún kẹtala tí Josaya gun orí oyè ni OLUWA bá Jeremaya sọ̀rọ̀.
3 Ó sì tún gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA ní ìgbà ayé Jehoiakimu, ọmọ Josaya, ọba Juda títí di òpin ọdún kọkanla tí Sedekaya ọmọ Josaya jọba ní ilẹ̀ Juda, títí tí ogun fi kó Jerusalẹmu ní oṣù karun-un ọdún náà.
4 OLUWA sọ fún mi pé,
5 “Kí n tó dá ọ sinu ìyá rẹ ni mo ti mọ̀ ọ́,kí wọ́n sì tó bí ọ ni mo ti yà ọ́ sọ́tọ̀,mo yàn ọ́ ní wolii fún àwọn orílẹ̀-èdè.”
6 Mo bá dáhùn pé,“Háà! OLUWA Ọlọrun!Wò ó! N kò mọ ọ̀rọ̀ sọ, nítorí pé ọmọde ni mí.”
7 Ṣugbọn OLUWA dá mi lóhùn, ó ní,“Má pe ara rẹ ní ọmọde,nítorí pé gbogbo ẹni tí mo bá rán ọ sí ni o gbọdọ̀ tọ̀ lọ.Gbogbo ohun tí mo bá pa láṣẹ fún ọ ni o gbọdọ̀ sọ.
8 Má bẹ̀rù wọn,nítorí mo wà pẹlu rẹ, n óo sì gbà ọ́.”
9 OLUWA bá na ọwọ́, ó fi kàn mí lẹ́nu, ó sì wí fún mi pé,“Wò ó, mo ti fi ọ̀rọ̀ mi sí ọ lẹ́nu.
10 Mo ti fi ọ́ ṣe orí fún àwọn orílẹ̀-èdè ati ìjọba lónìí,láti fà wọ́n tu ati láti bì wọ́n lulẹ̀,láti pa wọ́n run ati láti bì wọ́n ṣubú,láti tún wọn kọ́ ati láti gbé wọn ró.”
11 OLUWA bi mí pé, “Jeremaya, kí ni o rí yìí?”Mo dáhùn, pé, “Ọ̀pá igi Alimọndi ni.”
12 OLUWA bá wí fún mi pé, “Òtítọ́ ni ohun tí o rí, nítorí mò ń sọ ọ̀rọ̀ tí mo sọ, n óo sì mú un ṣẹ.”
13 OLUWA tún bi mí lẹẹkeji, ó ní, “Kí ni o rí?”Mo bá dáhùn pé, “Mo rí ìkòkò kan tí ó ń hó lórí iná, ó tẹ̀ láti ìhà àríwá sí ìhà gúsù.”
14 OLUWA bá sọ fún mi pé, “Láti ìhà àríwá ni ibi yóo ti dé bá gbogbo àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ náà.
15 Nítorí pé mò ń pe gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ó wà ní ìjọba àríwá, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀, àwọn ọba wọn yóo sì tẹ́ ìtẹ́ wọn kalẹ̀ ní ẹnubodè Jerusalẹmu, ati yíká odi gbogbo ìlú Juda.
16 N óo dá wọn lẹ́jọ́ nítorí gbogbo ibi tí wọ́n ti ṣe, tí wọ́n kọ̀ mí sílẹ̀, tí wọn ń sun turari fún àwọn oriṣa, tí wọ́n sì ń bọ ohun tí wọ́n fi ọwọ́ ara wọn ṣe.
17 Ṣugbọn, ìwọ dìde, di àmùrè rẹ, kí o sì sọ gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún ọ fún wọn. Má jẹ́ kí ẹ̀rù wọn ó bà ọ́, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, n óo dẹ́rù bà ọ́ níwájú wọn.
18 Wò ó, mo ti sọ ọ́ di ìlú tí a mọ odi yíká lónìí, o di òpó irin ati ògiri tí a fi bàbà mọ fún gbogbo ilẹ̀ yìí, ati fún àwọn ọba ilẹ̀ Juda, àwọn ìjòyè, ati àwọn alufaa rẹ̀, ati àwọn eniyan ilẹ̀ náà.
19 Wọn yóo gbógun tì ọ́, ṣugbọn wọn kò ní ṣẹgun rẹ. Nítorí pé mo wà pẹlu rẹ láti gbà ọ́ kalẹ̀. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”