Jeremaya 32 BM

Jeremaya Ra Ilẹ̀

1 OLUWA bá Jeremaya sọ̀rọ̀ ní ọdún kẹwaa tí Sedekaya jọba ní Juda, tí ó jẹ́ ọdún kejidinlogun tí Nebukadinesari jọba.

2 Àwọn ọmọ ogun Babiloni dó ti Jerusalẹmu ní àkókò yìí, Jeremaya wolii sì wà ní ẹ̀wọ̀n tí wọ́n sọ ọ́ sí, ní àgbàlá ààfin ọba Juda.

3 Sedekaya ọba Juda ni ó sọ Jeremaya sẹ́wọ̀n, ó ní, kí ló dé tí Jeremaya fi sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé OLUWA ní òun óo fi Jerusalẹmu lé ọba Babiloni lọ́wọ́, yóo sì gbà á;

4 ati pé Sedekaya ọba Juda kò ní bọ́ lọ́wọ́ àwọn ará Kalidea. Ó ní Jeremaya sọ pé dájúdájú, OLUWA óo fi òun Sedekaya lé ọba Babiloni lọ́wọ́, àwọn yóo rí ara àwọn lojukooju, àwọn yóo sì bá ara àwọn sọ̀rọ̀.

5 Yóo mú òun Sedekaya lọ sí Babiloni, ibẹ̀ ni òun óo sì wà títí OLUWA yóo fi ṣe ẹ̀tọ́ fún òun. Ó ní bí àwọn tilẹ̀ bá àwọn ará Kalidea jagun, àwọn kò ní borí.

6 Jeremaya ní, “OLUWA sọ fún mi pé,

7 ‘Hanameli ọmọ Ṣalumu, arakunrin baba rẹ, yóo wá bá ọ pé kí o ra oko òun tí ó wà ní Anatoti, nítorí pé ìwọ ni ó tọ́ sí láti rà á pada.’

8 Lẹ́yìn náà Hanameli ọmọ arakunrin baba mi tọ̀ mí wá sí àgbàlá àwọn olùṣọ́ gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti sọ, ó sì wí fún mi pé, ‘Jọ̀wọ́ ra oko mi tí ó wà ní Anatoti ní ilẹ̀ Bẹnjamini, nítorí pé ìwọ ni ó tọ́ sí láti rà á pada; rà á fún ara rẹ.’“Nígbà náà ni mo wá mọ̀ pé àṣẹ OLUWA ni.

9 Mo bá ra oko náà lọ́wọ́ Hanameli ọmọ arakunrin baba mi, mo sì wọn fadaka ṣekeli mẹtadinlogun fún un.

10 Mo kọ ọ́ sinu ìwé, mo fi òǹtẹ̀ tẹ̀ ẹ́, mo pe àwọn eniyan láti ṣe ẹlẹ́rìí; mo sì fi òṣùnwọ̀n wọn fadaka náà.

11 Mo mú ìwé ilẹ̀ náà tí a ti fi òǹtẹ̀ tẹ̀ ati ẹ̀dà rẹ̀,

12 mo sì fún Baruku ọmọ Neraya ọmọ Mahiseaya ní èyí tí a fi òǹtẹ̀ tẹ̀, níṣojú Hanameli, ọmọ arakunrin baba mi ati níṣojú àwọn ẹlẹ́rìí tí wọn fọwọ́ sí ìwé ilẹ̀ náà, ati níṣojú gbogbo àwọn ará Juda tí wọn jókòó ní àgbàlá àwọn olùṣọ́ náà.

13 Mo pàṣẹ fún Baruku níṣojú wọn pé,

14 ‘OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní kí o mú ìwé ilẹ̀ yìí, ati èyí tí a fi òǹtẹ̀ tẹ̀ tí a sì ká, ati ẹ̀dà rẹ̀, kí o fi wọ́n sinu ìkòkò amọ̀ kí wọ́n lè wà níbẹ̀ fún ọjọ́ pípẹ́.

15 Nítorí pé OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli sọ pé: wọn yóo tún máa ra ilẹ̀ ati oko ati ọgbà àjàrà ní ilẹ̀ yìí.’

Adura Jeremaya

16 “Lẹ́yìn tí mo ti fi ìwé ilẹ̀ náà lé Baruku ọmọ Neraya lọ́wọ́, mo gbadura sí OLUWA, mo ní:

17 ‘OLUWA, Ọlọrun! Ìwọ tí o dá ọ̀run ati ayé pẹlu agbára ńlá ati ipá rẹ! Kò sí ohun tí ó ṣòro fún ọ,

18 ìwọ tí ò ń fi ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ hàn fún ẹgbẹẹgbẹrun eniyan, ṣugbọn tí ò ń gba ẹ̀san àwọn baba lára àwọn ọmọ wọn lẹ́yìn ikú wọn, ìwọ Ọlọrun alágbára ńlá tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ OLUWA àwọn ọmọ ogun,

19 ìwọ Olùdámọ̀ràn ńlá, tí ó lágbára ní ìṣe; ìwọ tí ojú rẹ ń rí sí gbogbo ọ̀nà àwọn ọmọ eniyan, tí o sì ń san ẹ̀san fún olukuluku gẹ́gẹ́ bí ìwà ati iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀;

20 ìwọ tí o ṣe iṣẹ́ abàmì, ati iṣẹ́ ìyanu ní ilẹ̀ Ijipti, o sì tún ń ṣe iṣẹ́ náà títí di òní ní Israẹli ati láàrin gbogbo eniyan; o sì ti fìdí orúkọ rẹ múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti rí lónìí.

21 Ìwọ ni o kó àwọn ọmọ Israẹli, àwọn eniyan rẹ, jáde láti ilẹ̀ Ijipti pẹlu iṣẹ́ abàmì ati iṣẹ́ ìyanu, pẹlu ọwọ́ agbára, ipá ati ìbẹ̀rù ńlá.

22 O sì fún wọn ní ilẹ̀ yìí, ilẹ̀ tí o búra fún àwọn baba ńlá wọn pé o óo fún wọn, ilẹ̀ tí ó kún fún wàrà ati oyin.

23 Wọ́n dé ilẹ̀ náà, wọ́n sì gbà á; ṣugbọn wọn kò gbọ́rọ̀ sí ọ lẹ́nu, wọn kò sì pa òfin rẹ mọ́. Wọn kò ṣe ọ̀kan kan ninu gbogbo ohun tí o pàṣẹ fún wọn láti máa ṣe; nítorí náà ni o ṣe mú kí gbogbo ibi tí ó ṣẹlẹ̀ sí wọn bá wọn!

24 “ ‘Wo bí àwọn ọ̀tá ti mọ òkítì sí ara odi wa láti gba ìlú wa. Nítorí ogun, ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn, a óo fi ìlú yìí lé àwọn ará Kalidea tí wọn gbógun tì í lọ́wọ́. Ohun tí o wí ṣẹ, o sì ti rí i.

25 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti fi ìlú yìí lé àwọn ará Kalidea lọ́wọ́, sibẹsibẹ, ìwọ OLUWA Ọlọrun ni o sọ fún mi pé kí n ra ilẹ̀, kí n sì ní àwọn ẹlẹ́rìí.’ ”

26 OLUWA sọ fún Jeremaya pé,

27 “Wò ó! Èmi ni OLUWA, Ọlọrun gbogbo eniyan, ǹjẹ́ nǹkankan wà tí ó ṣòro fún mi láti ṣe?

28 Nítorí náà èmi OLUWA ni mo sọ pé, n óo fi ìlú yìí lé àwọn ará Kalidea ati Nebukadinesari, ọba Babiloni lọ́wọ́, yóo sì gbà á.

29 Àwọn ará Kalidea tí wọn gbógun ti ìlú yìí, yóo wọ inú rẹ̀, wọn yóo sì dáná sun ún pẹlu àwọn ilẹ̀ tí wọ́n tí ń sun turari sí oriṣa Baali lórí wọn, tí wọ́n sì tí ń rú ẹbọ ohun mímu sí àwọn oriṣa tí wọn ń mú mi bínú.

30 Nítorí láti ìgbà èwe àwọn ọmọ Israẹli ati àwọn eniyan Juda ni wọ́n tí ń ṣe kìkì nǹkan tí ó burú lójú mi, kìkì nǹkan tí yóo bí mi ninu ni àwọn ọmọ Israẹli náà sì ń ṣe. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

31 Láti ọjọ́ tí wọn ti tẹ ìlú yìí dó títí di òní, ni àwọn ará ilẹ̀ yìí tí ń mú mi bínú, tí wọn sì ń mú kí inú mi ó máa ru, kí n lè pa wọ́n rẹ́ kúrò níwájú mi,

32 nítorí gbogbo ibi tí àwọn ọmọ Israẹli ati àwọn ará ilẹ̀ Juda ṣe láti mú mi bínú, àtàwọn ọba wọn, àtàwọn ìjòyè wọn, àtàwọn alufaa wọn, àtàwọn wolii wọn; àtàwọn ará Juda àtàwọn tí ń gbé Jerusalẹmu.

33 Wọ́n ti yíjú kúrò lọ́dọ̀ mi, wọ́n sì kẹ̀yìn sí mi. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti kọ́ wọn ni àkọ́túnkọ́, wọn kò gba ẹ̀kọ́.

34 Wọ́n gbé àwọn ère wọn, tí ó jẹ́ ohun ìríra fun mi sinu ilé tí à ń fi orúkọ mi pè, kí wọ́n lè sọ ọ́ di ibi àìmọ́.

35 Wọ́n kọ́ ojúbọ oriṣa tí ó wà ní àfonífojì ọmọ Hinomu láti máa fi àwọn ọmọ wọn, lọkunrin ati lobinrin rú ẹbọ sí oriṣa Moleki, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò pa á láṣẹ fún wọn, tí kò sì wá sí mi lọ́kàn pé wọ́n lè ṣe irú ohun ìríra bẹ́ẹ̀, láti mú Juda dẹ́ṣẹ̀.”

Ìlérí Ìrètí

36 Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun Israẹli sọ fún mi pé, “Ìlú tí àwọn eniyan ń sọ pé ọwọ́ ọba Babiloni ti tẹ̀, nítorí ogun, ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn,

37 n óo kó àwọn eniyan ibẹ̀ jọ láti gbogbo orílẹ̀-èdè tí mo ti fi ibinu, ìrúnú, ati ìkanra lé wọn lọ; n óo kó wọn pada sí ibí yìí, n óo sì mú kí wọn máa gbé ní àìléwu.

38 Wọn yóo máa jẹ́ eniyan mi, Èmi náà óo sì máa jẹ́ Ọlọrun wọn.

39 N óo fún wọn ní ọkàn ati ẹ̀mí kan, kí wọn lè máa bẹ̀rù mi nígbà gbogbo, kí ó lè dára fún àwọn ati àwọn ọmọ wọn lẹ́yìn wọn.

40 N óo bá wọn dá majẹmu ayérayé, pé n kò ní dẹ́kun ati máa ṣe wọ́n lóore. N óo fi ẹ̀rù mi sí wọn lọ́kàn, kí wọn má baà yapa kúrò lọ́dọ̀ mi mọ́.

41 Yóo máa jẹ́ ohun ayọ̀ fún mi láti ṣe wọ́n lóore, n óo fi tẹ̀mítẹ̀mí ati tọkàntọkàn fi ìdí wọn múlẹ̀ ninu jíjẹ́ olóòótọ́ ní ilẹ̀ yìí.

42 “Bí mo ṣe mú gbogbo ibi ńlá yìí bá àwọn eniyan wọnyi, bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe mú kí gbogbo ohun rere tí mo ti ṣe ìlérí fún wọn dé bá wọn.

43 Wọn yóo ra oko ní ilẹ̀ yìí, ilẹ̀ tí ẹ̀ ń sọ pé ó ti di ahoro, tí kò sí eniyan tabi ẹranko ninu rẹ̀, tí ẹ̀ ń sọ pé a ti fi lé àwọn ará Kalidea lọ́wọ́.

44 Wọn yóo máa fi owó ra oko, wọn yóo máa ṣe ìwé ilẹ̀, wọn yóo máa fi òǹtẹ̀ tẹ̀ ẹ́; wọn yóo máa fi èdìdì dì í, àwọn ẹlẹ́rìí yóo sì máa fi ọwọ́ sí i, bẹ́ẹ̀ ni yóo máa rí ní ilẹ̀ Bẹnjamini. Nígbà tí mo bá dá ire wọn pada, ati ní àwọn agbègbè Jerusalẹmu, ní àwọn ìlú Juda, ati àwọn ìlú agbègbè olókè, ní àwọn ìlú pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ṣefela, ati àwọn ìlú ilẹ̀ Nẹgẹbu. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”