1 Ní oṣù kẹwaa, ọdún kẹsan-an ìjọba Sedekaya, ọba Juda, Nebukadinesari, ọba Babiloni, ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ gbógun ti Jerusalẹmu, wọ́n sì dótì í.
2 Ní ọjọ́ kẹsan-an, oṣù kẹrin, ọdún kọkanla ìjọba rẹ̀, wọ́n wọ ìlú náà.
3 Lẹ́yìn tí ogun ti kó Jerusalẹmu, gbogbo àwọn ìjòyè ọba Babiloni péjọ, wọ́n sì jókòó ní bodè ààrin: Negali Sareseri, Samgari Nebo, Sarisekimu Rabusarisi, Negali Sareseri, Rabumagi ati àwọn ìjòyè ọba Babiloni yòókù.
4 Nígbà tí Sedekaya ọba Juda ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ rí wọn, wọ́n sá. Wọ́n fòru bojú, wọ́n bá jáde ní ìlú; wọ́n gba ọ̀nà ọgbà ọba, ní ọ̀nà ibodè tí ó wà láàrin odi meji, wọ́n sì dojú kọ ọ̀nà Araba.
5 Ṣugbọn àwọn ọmọ ogun Kalidea lé wọn, wọ́n bá Sedekaya ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jẹriko; wọ́n mú un lọ sí ọ̀dọ̀ Nebukadinesari ọba Babiloni ní Ribila ní ilẹ̀ Hamati, ó sì dá Sedekaya lẹ́jọ́.
6 Ọba Babiloni pa àwọn ọmọ Sedekaya ní Ribila níṣojú rẹ̀, ó sì pa gbogbo àwọn ìjòyè Juda pẹlu.
7 Ó yọ ojú Sedekaya, ó sì fi ẹ̀wọ̀n bàbà dè é láti mú un lọ sí Babiloni.
8 Àwọn ará Kalidea jó ààfin ọba ati ilé àwọn ará ìlú, wọ́n sì wó odi Jerusalẹmu lulẹ̀.
9 Nebusaradani olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ bá kó àwọn eniyan tí wọn ṣẹ́kù ní Jerusalẹmu ní ìgbèkùn, lọ sí Babiloni pẹlu àwọn tí wọn kọ́ sá lọ bá a tẹ́lẹ̀.
10 Nebusaradani olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ fi díẹ̀ ninu àwọn talaka sílẹ̀ ní ilẹ̀ Juda, ó sì fún wọn ní ọgbà àjàrà ati oko.
11 Nebukadinesari ọba Babiloni pàṣẹ fún Nebusaradani olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ pé
12 kí wọn mú Jeremaya, kí wọn tọ́jú rẹ̀ dáradára, kí wọn má pa á lára, ṣugbọn kí wọn ṣe ohunkohun tí ó bá ń fẹ́ fún un.
13 Nebusaradani olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ ati Nebuṣasibani, ìjòyè pataki kan, ati Negali Sareseri olóyè pataki mìíràn ati gbogbo àwọn olóyè jàǹkànjàǹkàn ninu àwọn ìjòyè ọba Babiloni,
14 wọ́n ranṣẹ lọ mú Jeremaya jáde kúrò ní ìgbèkùn. Wọ́n bá fà á lé Gedalaya ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani lọ́wọ́, pé kí ó mú un lọ sí ilé rẹ̀. Ó bá ń gbé ààrin àwọn eniyan náà.
15 OLUWA sọ fún Jeremaya nígbà tí ó wà ní àtìmọ́lé ní gbọ̀ngàn àwọn tí wọn ń ṣọ́ ààfin ọba, pé,
16 kí ó lọ sọ fún Ebedimeleki ará Etiopia pé, OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní, “Wò ó, n óo mú ìpinnu ibi tí mo ṣe lórí ìlú yìí ṣẹ, lójú rẹ ni yóo sì ṣẹ.
17 N óo gbà ọ́ sílẹ̀ ní ọjọ́ náà, wọn kò ní fà ọ́ lé àwọn tí ò ń bẹ̀rù lọ́wọ́. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
18 Nítorí pé, dájúdájú n óo gbà ọ́ sílẹ̀, o ò ní kú ikú idà, ṣugbọn o óo sá àsálà, nítorí pé o gbẹ́kẹ̀lé mi.”