Jeremaya 51 BM

Ọlọrun Tún Dá Babiloni lẹ́jọ́ sí i

1 OLUWA ní,“Wò ó! N óo gbé ẹ̀mí apanirun kan dìde sí Babiloni,ati sí àwọn ará Kalidea;

2 n óo rán ìjì líle kan sí Babiloni,ìjì náà yóo fẹ́ ẹ dànù bí ìyàngbò ọkàyóo sì sọ ilẹ̀ rẹ̀ di ahoro,nígbà tí wọ́n bá gbógun tì í yípo, ní ọjọ́ ìpọ́njú.

3 Kí tafàtafà má kẹ́ ọrun rẹ̀,kí ó má sì gbé ẹ̀wù irin rẹ̀ wọ̀.Má ṣe dá àwọn ọdọmọkunrin rẹ̀ sí,pa gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ run patapata.

4 Kí wọ́n ṣubú, kí wọ́n sì kú ní ilẹ̀ Kalidea,kí wọ́n gún wọn ní àgúnyọ láàrin ìgboro.

5 Nítorí pé OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ati Juda kò kọ̀ wọ́n sílẹ̀;ṣugbọn ilẹ̀ Kalidea kún fún ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀,tí wọ́n dá sí Ẹni Mímọ́ Israẹli.

6 Ẹ sá kúrò láàrin Babiloni,kí olukuluku sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ̀!Ẹ má parun nítorí ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ Babiloni;nítorí àkókò ẹ̀san OLUWA nìyí,yóo sì san ẹ̀san fún Babiloni.

7 Ife wúrà ni Babiloni jẹ́ lọ́wọ́ OLUWA,ó ń pa gbogbo ayé bí ọtí;àwọn orílẹ̀-èdè mu ninu ọtí rẹ̀,wọ́n sì ń ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n.

8 Babiloni ṣubú lójijì, ó sì fọ́;ẹ sun ẹkún arò nítorí rẹ̀!Ẹ fi ìwọ̀ra pa á lára nítorí ìrora rẹ̀,bóyá ara rẹ̀ yóo yá.

9 À bá wo Babiloni sàn,ṣugbọn a kò rí i wòsàn.Ẹ pa á tì, ẹ jẹ́ kí á lọ,kí olukuluku máa lọ sí ilẹ̀ rẹ̀;nítorí ẹjọ́ tí a dá a ti dé òkè ọ̀run,a sì ti gbé e sókè dé ojú ọ̀run.”

10 OLUWA ti dá wa láre;ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á lọ ròyìn iṣẹ́ OLUWA Ọlọrun wa ní Sioni.

11 Ẹ pọ́n ọfà yín!Ẹ gbé asà yín!Nítorí OLUWA ti ru ẹ̀mí àwọn ọba Media sókè,nítorí pé ó ti pinnu láti pa Babiloni run.Ẹ̀san OLUWA ni, ẹ̀san nítorí tẹmpili rẹ̀ tí wọ́n wó.

12 Ẹ gbé àsíá kan sókè, ẹ gbé e ti odi Babiloni;ẹ ṣe ìsénà tí ó lágbára.Ẹ fi àwọn aṣọ́nà sí ipò wọn;ẹ dira fún àwọn kan, kí wọn sápamọ́,nítorí OLUWA ti pinnu, ó sì ti ṣe ohun tí ó sọ nípa àwọn ará Babiloni.

13 Ìwọ Babiloni, tí odò yí ká,tí ìṣúra rẹ pọ̀ lọpọlọpọ,òpin ti dé bá ọ,okùn tí ó so ayé rẹ rọ̀ ti já.

14 OLUWA àwọn ọmọ ogun ti fi ara rẹ̀ búra,pé òun yóo mú kí àwọn eniyan kún inú rẹ bí eṣú,wọn yóo sì kígbe ìṣẹ́gun lé ọ lórí.

Orin Ìyìn sí Ọlọrun

15 OLUWA ni ó fi agbára rẹ̀ dá ilé ayé,tí ó fi ìdí ayé múlẹ̀ pẹlu ìmọ̀ rẹ̀,ó sì fi òye rẹ̀ ta àwọn ọ̀run bí aṣọ.

16 Nígbà tí ó bá sọ̀rọ̀,ojú ọ̀run yóo kún fún alagbalúgbú omi,ó sì ń mú ìkùukùu gòkè láti òpin ilẹ̀ ayé.Ó dá mànàmáná fún òjò,ó sì mú ìjì jáde láti inú ilé ìṣúra rẹ̀.

17 Òmùgọ̀ ni gbogbo eniyan, wọn kò sì ní ìmọ̀,gbogbo alágbẹ̀dẹ wúrà sì gba ìtìjú lórí oriṣa tí wọn dà;nítorí pé irọ́ ni ère tí wọ́n rọ,wọn kò ní èémí.

18 Asán ni wọ́n, wọ́n ń ṣini lọ́nà,píparun ni wọn yóo parun, ní ọjọ́ ìjìyà wọn.

19 Ọlọrun ti Jakọbu kò dàbí àwọn wọnyi,nítorí pé òun ní ẹlẹ́dàá ohun gbogbo;ẹ̀yà Israẹli ni eniyan tirẹ̀,OLUWA àwọn ọmọ ogun sì ni orúkọ rẹ̀.OLUWA sọ fún Babiloni pé,

Òòlù OLUWA

20 “Ìwọ ni òòlù ati ohun ìjà mi:ìwọ ni mo fi wó àwọn orílẹ̀-èdè wómúwómú,ìwọ ni mo sì fi pa àwọn ìjọba run.

21 Ìwọ ni mo fi lu ẹṣin ati ẹni tí ń gùn ún pa;ìwọ ni mo fi wó kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn tí ń bẹ ninu wọn.

22 Ìwọ ni mo fi lu tọkunrin tobinrin pa,ìwọ ni mo fi lu tọmọde, tàgbà pa,ìwọ ni mo sì fi run àwọn ọdọmọkunrin ati ọdọmọbinrin.

23 Ìwọ ni mo fi pa olùṣọ́-aguntan ati agbo ẹran rẹ̀ rẹ́,ìwọ ni mo fi run àgbẹ̀ ati àwọn alágbàro rẹ̀,ìwọ ni mo fi ṣẹ́ apá àwọn gomina ati ti àwọn olórí ogun.”

Ìjìyà Babiloni

24 OLUWA ní,“Níṣojú yín ni n óo fi san ẹ̀san fún Babiloni,ati gbogbo àwọn tí wọn ń gbé Kalidea,fún gbogbo ibi tí wọ́n ṣe sí Sioni;èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

25 Wò ó! Mo lòdì sí ọ, ìwọ òkè ìparun,tí ò ń pa gbogbo ayé run.N óo gbá ọ mú, n óo tì ọ́ lulẹ̀ láti orí àpáta,n óo sì sọ ọ́ di òkè tí ó jóná.

26 Wọn kò ní rí òkúta kan mú jáde ninu rẹ,tí eniyan lè fi ṣe òkúta igun ilé;tabi tí wọn lè fi ṣe ìpìlẹ̀ ilé,ń ṣe ni o óo wó lulẹ̀ títí ayé.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

27 “Ẹ ta àsíá sórí ilẹ̀ ayé,ẹ fun fèrè ogun láàrin àwọn orílẹ̀-èdè;kí àwọn orílẹ̀-èdè múra láti gbógun tì í,ẹ sì pe àwọn ìjọba jọ láti dojú kọ ọ́;àwọn ìjọba orílẹ̀-èdè bíi Ararati, Minni, ati Aṣikenasi.Ẹ yan balogun tí yóo gbógun tì í;ẹ kó ẹṣin wá, kí wọn pọ̀ bí eṣú.

28 Kí àwọn orílẹ̀-èdè múra láti gbógun tì í,kí àwọn ọba ilẹ̀ Media múra, pẹlu àwọn gomina wọn,ati àwọn ẹmẹ̀wà wọn,ati gbogbo ilẹ̀ tí ó wà lábẹ́ wọn.

29 Jìnnìjìnnì bo gbogbo ilẹ̀ náà,wọ́n wà ninu ìrora,nítorí pé OLUWA kò yí ìpinnu rẹ̀ lórí Babiloni pada,láti sọ ilẹ̀ náà di ahoro,láìsí ẹnìkan kan ninu rẹ̀ mọ́.

30 Àwọn ọmọ ogun Babiloni ti ṣíwọ́ ogun jíjà,wọ́n wà ní ibi ààbò wọn;àárẹ̀ ti mú wọn, wọ́n sì ti di obinrin.Àwọn ilé inú rẹ̀ ti ń jóná,àwọn ọ̀pá ìdábùú ìlẹ̀kùn bodè rẹ̀ sì ti ṣẹ́.

31 Àwọn tí ń sáré ń pàdé ara wọn lọ́nà,bẹ́ẹ̀ ni àwọn ikọ̀ ń pàdé ara wọn,bí wọ́n ti ń sáré lọ sọ fún ọba Babiloni pé ogun ti gba ìlú rẹ̀ patapata.

32 Wọ́n ti gba ibi ìsọdá odò,wọ́n ti dáná sun àwọn ibi ààbò,ìbẹ̀rùbojo sì ti mú àwọn ọmọ ogun.

33 Babiloni dàbí ibi ìpakà, tí a tẹ̀ mọ́lẹ̀ nígbà tí à ń pa ọkà.Láìpẹ́ ọ̀tá yóo dà á wó, yóo sì di àtẹ̀mọ́lẹ̀.Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

34 “Nebukadinesari ọba Babiloni ti run Jerusalẹmu,ó ti tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀,ó ti sọ ọ́ di ohun èlò òfìfo,ó gbé e mì bí erinmi,ó ti kó gbogbo ohun àdídùn inú rẹ̀ jẹ ní àjẹrankùn,ó ti da ìyókù nù.

35 Jẹ́ kí àwọn tí ń gbé Sioni wí pé,‘Kí ibi tí àwọn ará Babiloni ṣe sí wa ati sí àwọn arakunrin wa dà lé wọn lórí.’Kí àwọn ará Jerusalẹmu sì wí pé,‘Ẹ̀jẹ̀ wa ń bẹ lórí àwọn ará ilẹ̀ Kalidea.’ ”

OLUWA Yóo Ran Israẹli lọ́wọ́

36 Nítorí náà, OLUWA sọ fún àwọn ará Jerusalẹmu pé,“Ẹ wò ó, n óo gba ẹjọ́ yín rò,n óo sì ba yín gbẹ̀san.N óo jẹ́ kí omi òkun Babiloni gbẹ,n óo sì jẹ́ kí orísun odò rẹ̀ gbẹ.

37 Babiloni yóo sì di òkítì àlàpà, ati ibùgbé ajáko,yóo di ibi àríbẹ̀rù ati àrípòṣé, láìsí ẹnìkan kan ninu rẹ̀.

38 Gbogbo wọn yóo bú papọ̀ bíi kinniun,wọn yóo sì ké bí àwọn ọmọ kinniun.

39 Nígbà tí ara wọn bá gbóná,n óo se àsè kan fún wọn.N óo rọ wọ́n lọ́tí yó,títí tí wọn óo fi máa yọ ayọ̀ ẹ̀sín,tí wọn óo sì sùn lọ títí ayé.Wọn óo sùn, wọn kò sì ní jí mọ́.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

40 N óo fà wọ́n lọ sí ibi tí wọn tí ń pa ẹran,bí ọ̀dọ́ aguntan, ati àgbò ati òbúkọ.”

Ìpín Babiloni

41 OLUWA ní,“Ẹ wò ó bí ogun ti kó Babiloni,Babiloni tí gbogbo ayé ń pọ́nlé!Ó wá di àríbẹ̀rù láàrin àwọn orílẹ̀-èdè!

42 Òkun ti ru bo Babiloni mọ́lẹ̀.Ìgbì òkun ti bò ó mọ́lẹ̀.

43 Àwọn ìlú rẹ̀ ti di àríbẹ̀rù,wọ́n ti di ilẹ̀ gbígbẹ ati aṣálẹ̀,ilẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò gbé mọ́,tí ọmọ eniyan kò sì gbà kọjá mọ́.

44 N óo fìyà jẹ oriṣa Bẹli ní Babiloni,n óo jẹ́ kí ó pọ ohun tí ó gbé mì.Àwọn orílẹ̀-èdè kò ní lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ mọ́,odi Babiloni pàápàá yóo wó lulẹ̀.

45 “Ẹ̀yin eniyan mi, ẹ jáde kúrò níbẹ̀!Kí olukuluku sá àsálà, kúrò lọ́wọ́ ibinu gbígbóná OLUWA!

46 Ẹ mọ́kàn, ẹ má bẹ̀rù,nítorí ìròyìn tí ẹ̀ ń gbọ́ nípa ilẹ̀ náà,nígbà tí ẹ bá gbọ́ ìròyìn kan ní ọdún yìí,tí ẹ tún gbọ́ òmíràn ní ọdún tí ń bọ̀,tí ìwà ipá sì wà ní ilẹ̀ náà,tí àwọn ìjòyè sì ń dojú ìjà kọ ara wọn.

47 Nítorí náà, wò ó, ọjọ́ ń bọ̀tí n óo fìyà jẹ àwọn ère ilẹ̀ Babiloni.Ojú yóo ti gbogbo ilẹ̀ rẹ̀,òkú àwọn eniyan rẹ̀ tí ogun yóo pa,yóo wà nílẹ̀ káàkiri ìgboro.

48 Nítorí náà, ọ̀run ati ayé, ati gbogbo ohun tí ó wà ninu wọn,yóo yọ̀ nítorí ìṣubú Babiloni,nítorí pé apanirun yóo wá gbógun tì í, láti ìhà àríwá,Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

49 Bí àwọn tí ogun Babiloni pa ní àwọn orílẹ̀-èdè ayé,ti ṣubú níwájú rẹ̀.Bẹ́ẹ̀ ni Babiloni náà gbọdọ̀ ṣubú,nítorí àwọn tí wọ́n pa ní Israẹli.”

Ọlọrun Ranṣẹ sí Israẹli ní Babiloni

50 OLUWA sọ fún àwọn eniyan rẹ̀ ní Babiloni pé,“Ẹ̀yin tí ẹ bọ́ lọ́wọ́ idà,ẹ má dúró, ẹ máa sálọ!Ẹ ranti OLUWA ní ilẹ̀ òkèèrè,kí ẹ sì máa ronú nípa Jerusalẹmu pẹlu.

51 Ẹ̀ ń sọ pé ojú ń tì yín nítorí pé wọ́n kẹ́gàn yín;ẹ ní ìtìjú dà bò yín,nítorí pé àwọn àjèjì ti wọ ibi mímọ́ ilé OLUWA.

52 Nítorí náà, èmi OLUWA ń sọ nisinsinyii pé,ọjọ́ ń bọ̀, tí n óo ṣe ìdájọ́ lórí àwọn ère rẹ̀;àwọn tí wọ́n fara gbọgbẹ́ yóo máa kérora,ní gbogbo ilẹ̀ rẹ̀.

53 Bí Babiloni tilẹ̀ ga tí ó kan ojú ọ̀run,tí ó sì mọ odi yí àwọn ibi ààbò rẹ̀ gíga ká,sibẹsibẹ n óo rán apanirun sí i.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Ìparun Túbọ̀ Dé Bá Babiloni

54 OLUWA ní,“Ẹ gbọ́ igbe kan láti Babiloni!Igbe ìparun ńlá láti ilẹ̀ àwọn ará Kalidea!

55 Nítorí OLUWA ń wó Babiloni lulẹ̀,ó sì ń pa á lẹ́nu mọ́.Igbe wọn ta sókè bíi híhó omi òkun ńlá

56 nítorí pé apanirun ti dé sí i,àní ó ti dé sí Babiloni.Ogun ti kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀,àwọn ọ̀tá ti rún àwọn ọfà rẹ̀ jégéjégé,nítorí pé Ọlọrun ẹ̀san ni èmi OLUWA,dájúdájú n óo gbẹ̀san.

57 N óo jẹ́ kí àwọn ìjòyè rẹ̀ ati àwọn ọlọ́gbọ́n rẹ̀ mu ọtí ní àmuyó,pẹlu àwọn gomina rẹ̀, àwọn ọ̀gágun rẹ̀, ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀.Wọn yóo sun oorun àsùnrayè,wọn kò sì ní jí mọ́ laelae.Bẹ́ẹ̀ ni èmi ọba, tí orúkọ mi ń jẹ́ OLUWA àwọn ọmọ ogun sọ.

58 Odi Babiloni tí ó fẹ̀, yóo wó lulẹ̀,a óo sì dáná sun àwọn ẹnubodè rẹ̀ tí ó ga fíofío.Iṣẹ́ lásán ni àwọn eniyan ń ṣe,àwọn orílẹ̀-èdè sì ń yọ ara wọn lẹ́nu lásán ni,nítorí pé iná yóo jó gbogbo làálàá wọn.”

Jeremaya Ranṣẹ sí Babiloni

59 Jeremaya wolii pa àṣẹ kan fún Seraaya, alabojuto ibùdó ogun, ọmọ Neraya, ọmọ Mahiseaya nígbà tí ó ń bá Sedekaya ọba Juda lọ sí Babiloni ní ọdún kẹrin ìjọba Sedekaya.

60 Jeremaya kọ gbogbo nǹkan burúkú tí yóo ṣẹlẹ̀ sí Babiloni ati gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ tí ó sọ nípa rẹ̀ sinu ìwé kan.

61 Ó bá pàṣẹ fún Seraaya pé nígbà tí ó bá dé Babiloni, kí ó rí i dájú pé ó ka gbogbo ohun tí òun kọ sinu ìwé náà sókè.

62 Kí ó sọ pé, “OLUWA, o ti sọ pé o óo pa ibí yìí run, tóbẹ́ẹ̀ tí kò fi ní sí nǹkankan tí yóo máa gbé inú rẹ̀ mọ́, ìbáà ṣe eniyan tabi ẹranko. O ní títí lae ni yóo di ahoro.”

63 Jeremaya ní nígbà tí Seraaya bá ka ìwé yìí tán, kí ó di òkúta kan mọ́ ọn kí ó jù ú sí ààrin odò Yufurate,

64 kí ó sì sọ wí pé, “Báyìí ni yóo rí fún Babiloni, kò sì ní gbérí mọ́, nítorí ibi tí OLUWA yóo mú kí ó dé bá a.”Ibí yìí ni àwọn ọ̀rọ̀ tí Jeremaya sọ parí sí.