Jeremaya 26 BM

A Pe Jeremaya Lẹ́jọ́

1 Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba Jehoiakimu ọba Juda, ọmọ Josaya,

2 OLUWA bá mi sọ̀rọ̀; ó ní, “Dúró sí gbọ̀ngàn ilé OLUWA, kí o sọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo pa láṣẹ fún ọ pé kí o sọ fún gbogbo àwọn ará ìlú Juda tí wọn ń wá jọ́sìn níbẹ̀. Má fi ọ̀rọ̀ kankan pamọ́.

3 Ó ṣeéṣe kí wọ́n gbọ́, kí olukuluku wọn sì yipada kúrò ní ọ̀nà ibi rẹ̀; kí n lè yí ọkàn mi pada nípa ibi tí mo fẹ́ ṣe sí wọn nítorí iṣẹ́ burúkú wọn.

4 “Sọ fún wọn pé, èmi OLUWA ní bí wọn kò bá fetí sí ọ̀rọ̀ mi, kí wọn máa pa òfin tí mo gbé kalẹ̀ fún wọn mọ́,

5 kí wọn sì máa gbọ́ràn sí àwọn iranṣẹ mi lẹ́nu, ati àwọn wolii mi tí mò ń rán sí wọn léraléra, bí wọn kò tilẹ̀ kà wọ́n sí,

6 nítorí náà ni n óo ṣe ṣe ilé yìí bí mo ti ṣe Ṣilo; n óo sì sọ ìlú yìí di ohun tí gbogbo orílẹ̀-èdè ayé yóo máa fi gégùn-ún.”

7 Àwọn alufaa, àwọn wolii ati gbogbo àwọn eniyan gbọ́ tí Jeremaya ń sọ ọ̀rọ̀ yìí ní ilé OLUWA.

8 Nígbà tí ó sọ gbogbo ohun tí OLUWA pa láṣẹ fún un pé kí ó sọ fún gbogbo àwọn eniyan náà tán, gbogbo wọn rá a mú, wọ́n ní, “Kíkú ni o óo kú!

9 Kí ló dé tí o fi sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní orúkọ OLUWA pé ‘Ilé yìí yóo dàbí Ṣilo, ati pé ìlú yìí yóo di ahoro, ẹnikẹ́ni kò sì ní gbébẹ̀ mọ́?’ ” Gbogbo eniyan bá pé lé Jeremaya lórí ninu ilé OLUWA.

10 Nígbà tí àwọn ìjòyè Juda gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, wọ́n lọ sí ilé OLUWA láti ààfin ọba, wọ́n sì jókòó ní Ẹnu Ọ̀nà Titun tí ó wà ní ilé OLUWA.

11 Àwọn alufaa ati àwọn wolii bá sọ fún àwọn ìjòyè ati gbogbo àwọn eniyan pé, “Ẹjọ́ ikú ni ó yẹ kí a dá fún ọkunrin yìí nítorí àsọtẹ́lẹ̀ tí ó ń sọ nípa ìlú yìí, ẹ̀yin náà sá fi etí ara yín gbọ́.”

12 Jeremaya bá sọ fún àwọn ìjòyè ati gbogbo àwọn eniyan pé, “OLUWA ni ó rán mi láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ tí ẹ gbọ́ sí ilé yìí ati ìlú yìí.

13 Nítorí náà, ẹ tún ọ̀nà yín ṣe, ẹ pa ìṣe yín dà, kí ẹ sì gbọ́ràn sí OLUWA Ọlọrun yín lẹ́nu, yóo sì yí ọkàn rẹ̀ pada kúrò ninu ibi tí ó sọ pé òun yóo ṣe sí i yín.

14 Ní tèmi, mo wà lọ́wọ́ yín, ohun tí ó bá dára lójú yín ni kí ẹ fi mí ṣe.

15 Ṣugbọn kí ẹ mọ̀ dájú pé bí ẹ bá pa mí, ẹ óo fa ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sórí ara yín, ati ìlú yìí ati àwọn ará ìlú yìí, nítorí pé nítòótọ́ ni OLUWA rán mi pé kí n sọ gbogbo ohun tí mo sọ kí ẹ gbọ́.”

16 Àwọn ìjòyè ati gbogbo àwọn eniyan bá sọ fún àwọn alufaa ati àwọn wolii pé, “Ẹjọ́ ikú kò tọ́ sí ọkunrin yìí, nítorí pé orúkọ OLUWA Ọlọrun wa ni ó fi ń bá wa sọ̀rọ̀.”

17 Àwọn kan ninu àwọn àgbààgbà ìlú dìde, wọ́n bá gbogbo ìjọ eniyan sọ̀rọ̀; wọ́n ní,

18 “Ní ìgbà Hesekaya ọba Juda, Mika ará Moreṣeti sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún gbogbo àwọn ará Juda pé OLUWA àwọn ọmọ ogun ní,‘A óo kọ Sioni bí ilẹ̀ oko,Jerusalẹmu yóo di òkítì àlàpà;òkè ilé yìí yóo sì di igbó kìjikìji.’

19 Ǹjẹ́ Hesekaya ati gbogbo eniyan Juda pa Mika bí? Ṣebí OLUWA yí ibi tí ó ti pinnu láti ṣe sí wọn pada, nítorí pé Hesekaya bẹ̀rù OLUWA ó sì wá ojurere rẹ̀. Ṣugbọn ní tiwa ibi ńláńlá ni a fẹ́ fà lé orí ara wa yìí.”

20 Ọkunrin kan tún wà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Uraya, ọmọ Ṣemaaya, láti ìlú Kiriati Jearimu. Òun náà sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ilẹ̀ yìí ati ilẹ̀ wa bí Jeremaya ti sọ yìí.

21 Nígbà tí ọba Jehoiakimu ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀, ati àwọn ìjòyè gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, ọba wá ọ̀nà láti pa á. Nígbà tí Uraya gbọ́, ẹ̀rù bà á, ó sì sálọ sí ilẹ̀ Ijipti.

22 Ṣugbọn ọba Jehoiakimu rán Elinatani, ọmọ Akibori, ati àwọn ọkunrin kan lọ sí Ijipti,

23 wọ́n mú Uraya jáde ní ilẹ̀ Ijipti, wọ́n mú un tọ ọba Jehoiakimu wá. Ọba Jehoiakimu fi idà pa á, ó sì ju òkú rẹ̀ sí ibi tí wọn ń sin àwọn talaka sí.

24 Ṣugbọn Ahikamu ọmọ Ṣafani fọwọ́ sí ọ̀rọ̀ mi, kò sì jẹ́ kí á fà mí lé àwọn eniyan lọ́wọ́ láti pa.