Jeremaya 37 BM

Ohun Tí Sedekaya Bèèrè lọ́wọ́ Jeremaya

1 Nebukadinesari, ọba Babiloni fi Sedekaya, ọmọ Josaya, jọba ní ilẹ̀ Juda dípò Jehoiakini, ọmọ Jehoiakimu.

2 Ṣugbọn Sedekaya ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ ati àwọn eniyan náà kò pa ọ̀rọ̀ tí OLUWA ní kí Jeremaya wolii sọ fún wọn mọ́.

3 Ọba Sedekaya rán Jehukali, ọmọ Ṣelemaya, ati Sefanaya, alufaa, ọmọ Maaseaya, sí Jeremaya wolii, pé kí ó jọ̀wọ́ bá àwọn gba adura sí OLUWA Ọlọrun.

4 Ní àkókò yìí Jeremaya sì ń rìn káàkiri láàrin àwọn eniyan, nítorí wọn kò tíì jù ú sẹ́wọ̀n nígbà náà.

5 Àwọn ọmọ ogun Farao ti jáde, wọ́n ń bọ̀ láti Ijipti; nígbà tí àwọn ará Kalidea tí wọn dóti Jerusalẹmu gbọ́ pé wọ́n ń bọ̀, wọ́n kúrò ní Jerusalẹmu.

6 OLUWA sọ fún Jeremaya wolii pé kí ó sọ fún àwọn tí ọba Juda rán láti wá wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀ pé,

7 OLUWA Ọlọrun Israẹli ní kí òun Jeremaya sọ fún ọba pé, àwọn ọmọ ogun Farao tí wọn wá ràn wọ́n lọ́wọ́ ti ń múra láti pada sí Ijipti, ilẹ̀ wọn.

8 Àwọn ará Kalidea sì ń pada bọ̀ wá gbé ogun ti ìlú yìí; wọn yóo gbà á, wọn yóo sì dáná sun ún.

9 OLUWA ní kí wọn sọ fún Sedekaya ati àwọn ará Juda kí wọn má tan ara wọn jẹ, kí wọn má sì rò pé àwọn ará Kalidea kò ní pada wá sọ́dọ̀ wọn mọ́, nítorí wọn kò ní lọ.

10 Bí àwọn ará Juda bá tilẹ̀ ṣẹgun gbogbo ọmọ ogun àwọn ará Kalidea, tí wọ́n gbógun tì wọ́n, títí tí ó fi jẹ́ pé àwọn tí wọ́n ti fara gbọgbẹ́ nìkan ni wọ́n kù ninu àgọ́ wọn, wọn yóo dìde sí àwọn ará Juda, wọn yóo sì sun ìlú yìí níná.

Wọ́n Mú Jeremaya, Wọ́n sì Tì Í Mọ́lé

11 Lẹ́yìn tí àwọn ọmọ ogun Kalidea ti kúrò ní Jerusalẹmu, nígbà tí wọ́n rí i pé àwọn ọmọ ogun Farao ń bọ̀,

12 Jeremaya jáde ní Jerusalẹmu ó fẹ́ lọ sí ilẹ̀ Bẹnjamini kí ó lọ gba ilẹ̀ rẹ̀ kan lọ́wọ́ àwọn eniyan tí wọ́n wà níbẹ̀.

13 Bí Jeremaya wolii ti dé bodè Bẹnjamini ọ̀kan ninu àwọn oníbodè tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Irija ọmọ Ṣelemaya ọmọ Hananaya mú un, ó ní, “O fẹ́ sálọ bá àwọn ará Kalidea ni.”

14 Jeremaya dá a lóhùn, pé, “Rárá o, n kò sálọ sọ́dọ̀ àwọn ará Kalidea.” Ṣugbọn Irija kọ̀, kò gbọ́, ó sá mú Jeremaya lọ sọ́dọ̀ àwọn ìjòyè.

15 Inú bí àwọn ìjòyè sí Jeremaya, wọ́n lù ú, wọ́n sì jù ú sẹ́wọ̀n ní ilé Jonatani akọ̀wé, nítorí pé wọ́n ti sọ ibẹ̀ di ọgbà ẹ̀wọ̀n.

16 Lẹ́yìn tí Jeremaya ti wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n fún ọpọlọpọ ọjọ́,

17 Sedekaya ọba ranṣẹ lọ mú un wá sí ààfin rẹ̀, ó sì fi ọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò níkọ̀kọ̀, ó ní, “Ǹjẹ́ OLUWA ranṣẹ kankan?”Jeremaya dáhùn, ó ní, “Bẹ́ẹ̀ ni, ohun tí OLUWA sọ ni pé, a óo fi ọ́ lé ọba Babiloni lọ́wọ́.”

18 Jeremaya wá bi Sedekaya ọba pé, “Ẹ̀ṣẹ̀ wo ni mo ṣẹ̀ ọ́, tabi àwọn ẹmẹ̀wà rẹ, tabi àwọn ará ìlú yìí, tí ẹ fi jù mí sẹ́wọ̀n?

19 Níbo ni àwọn wolii rẹ wà, àwọn tí wọn ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún ọ pé, ‘Ọba Babiloni kò ní gbógun ti ìwọ ati ilẹ̀ yìí?’

20 Nisinsinyii, kabiyesi, oluwa mi, jọ̀wọ́ fetí sí ẹ̀bẹ̀ mi, má dá mi pada sí ilé Jonatani akọ̀wé, kí n má baà kú sibẹ.”

21 Sedekaya ọba bá pàṣẹ, wọ́n sì fi Jeremaya sinu gbọ̀ngàn ọgbà àwọn tí ń ṣọ́ ààfin. Wọ́n sì ń fún un ní burẹdi kan lojumọ láti òpópónà àwọn oníburẹdi títí tí gbogbo burẹdi fi tán ní ìlú. Bẹ́ẹ̀ ni Jeremaya ṣe bẹ̀rẹ̀ sí gbé gbọ̀ngàn àwọn tí ń ṣọ́ ààfin.