Jeremaya 16 BM

Ìfẹ́ OLUWA ní Ìgbésí Ayé Jeremaya

1 OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní:

2 “O kò gbọdọ̀ fẹ́ iyawo tabi kí o bímọ ní ibí yìí.

3 Nítorí ohun tí OLUWA sọ nípa àwọn ọmọkunrin ati àwọn ọmọbinrin tí a bí ní ibí yìí, ati nípa ìyá tí ó bí wọn, ati baba tí a bí wọn fún ni pé,

4 àìsàn burúkú ni yóo pa wọ́n. Ẹnìkan kò ní ṣọ̀fọ̀ wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní sin wọ́n; bí ìgbọ̀nsẹ̀ ni wọn yóo rí lórí ilẹ̀. Ogun ati ìyàn ni yóo pa wọ́n run, òkú wọn yóo sì di oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ati àwọn ẹranko.

5 “Má wọ ilé tí wọ́n ti ń ṣọ̀fọ̀, má lọ máa kọrin arò, tabi kí o bá wọn kẹ́dùn, nítorí mo ti mú alaafia mi ati ìfẹ́ mi ati àánú mi kúrò lọ́dọ̀ àwọn eniyan wọnyi.

6 Àtàwọn eniyan pataki pataki, ati mẹ̀kúnnù, ni yóo kú ní ilẹ̀ yìí, wọn kò ní rí ẹni sin òkú wọn, kò ní sí ẹni tí yóo sọkún wọn; ẹnìkan kò ní fi abẹ ya ara, tabi kí ẹnìkan fá orí nítorí wọn.

7 Kò ní sí ẹni tí yóo fún ẹni tí ń ṣọ̀fọ̀ ní oúnjẹ láti tù ú ninu, bẹ́ẹ̀ ni ẹnìkan kò sì ní bu omi fún ẹnìkan mu, nítorí ikú baba tabi ìyá rẹ̀.

8 “O kò gbọdọ̀ lọ sí ilé tí wọ́n ti ń se àsè, má bá wọn jókòó láti jẹ tabi láti mu.

9 Nítorí pé OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní: ‘Wò ó! N óo fi òpin sí ẹ̀rín ati ìró ayọ̀ ní ibí yìí, n óo sì fi òpin sí ohùn iyawo àṣẹ̀ṣẹ̀gbé ati ti ọkọ iyawo. Yóo ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀ níṣojú yín, ní ìgbà ayé yín.’

10 “Bí o bá sọ ọ̀rọ̀ yìí fún àwọn eniyan náà tán, bí wọn bá bi ọ́ pé, ‘Kí ló dé tí OLUWA fi sọ gbogbo ọ̀rọ̀ burúkú yìí nípa wa? Kí ni a ṣe? Ẹ̀ṣẹ̀ wo ni a ṣẹ OLUWA Ọlọrun wa?’

11 Kí o dá wọn lóhùn pé, nítorí pé àwọn baba wọn ti kọ̀ mí sílẹ̀, wọ́n ń tẹ̀lé àwọn ọlọrun mìíràn, wọ́n ń sìn wọ́n, wọ́n sì ń bọ wọ́n.

12 Wọ́n ti kọ̀ mí sílẹ̀, wọn kò sì pa òfin mi mọ́. Ẹ̀yin gan-an ti ṣe ohun tí ó burú ju ti àwọn baba yín lọ, ẹ wò bí olukuluku yín tí ń tẹ̀lé agídí ọkàn rẹ̀, tí ẹ kọ̀, tí ẹ kò sì gbọ́ tèmi.

13 Nítorí náà, n óo gba yín dànù kúrò ní ilẹ̀ yìí; n óo fọn yín dànù bí òkò, sí ilẹ̀ tí ẹ̀yin ati àwọn baba yín kò mọ̀ rí. Níbẹ̀ ni ẹ óo ti máa sin oriṣa, tí ẹ óo máa bọ wọ́n tọ̀sán-tòru, nítorí pé n kò ní ṣàánú yín.”

Ìpadàbọ̀ láti Ìgbèkùn

14 Nítorí náà, OLUWA ní, “Àkókò ń bọ̀, tí wọn kò ní máa búra mọ́ pé, ‘Bí OLUWA, tí ó kó àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti tí ń bẹ,’

15 ṣugbọn wọn yóo máa búra pé, ‘Bí OLUWA tí ń bẹ, ẹni tí ó kó àwọn ọmọ Israẹli jáde láti ilẹ̀ àríwá ati láti gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó lé wọn lọ.’ N óo mú wọn pada sórí ilẹ̀ wọn, ilẹ̀ tí mo fún àwọn baba wọn.”

Ìjìyà Tí ń Bọ̀

16 Ó ní, “Wò ó, n óo ranṣẹ pe ọpọlọpọ apẹja, wọn yóo sì wá kó àwọn eniyan wọnyi. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn náà, n óo ranṣẹ sí ọpọlọpọ ọdẹ, wọn yóo sì wá dọdẹ wọn ní orí gbogbo òkè gíga ati àwọn òkè kéékèèké, ati ninu pàlàpálá àpáta.

17 Nítorí pé mò ń wo gbogbo ohun tí wọn ń ṣe, kò sí èyí tí n kò rí, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀ṣẹ̀ wọn kò sápamọ́ fún mi.

18 N óo gbẹ̀san àìdára wọn, ati ẹ̀ṣẹ̀ wọn ní ìlọ́po meji, nítorí wọ́n ti fi ohun ìríra wọn sọ ilẹ̀ mi di eléèérí. Wọ́n sì ti kó oriṣa ìríra wọn kún ilẹ̀ mi.”

Adura Igbẹkẹle Jeremaya ninu OLUWA

19 OLUWA, ìwọ ni agbára mi, ati ibi ààbò mi,ìwọ ni ibi ìsápamọ́sí mi, ní ìgbà ìpọ́njú.Àwọn orílẹ̀-èdè yóo wá sọ́dọ̀ rẹ,láti gbogbo òpin ayé,wọn yóo máa wí pé:“Irọ́ patapata ni àwọn baba wa jogún,ère lásánlàsàn tí kò ní èrè kankan.

20 Ṣé eniyan lè fi ọwọ́ ara rẹ̀ ṣẹ̀dá ọlọrun?Irú ọlọrun bẹ́ẹ̀ kì í ṣe ọlọrun rárá.”

21 OLUWA ní, “Nítorí náà, wò ó, n óo jẹ́ kí wọn mọ̀;àní sẹ́, n óo jẹ́ kí wọ́n mọ agbára ati ipá mi;wọn yóo sì mọ̀ pé orúkọ mi ni OLUWA.”