1 OLUWA Ọlọrun Israẹli bá Jeremaya sọ̀rọ̀:
2 Ó ní, “Kọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ fún ọ sinu ìwé,
3 nítorí pé àkókò ń bọ̀ tí n óo dá ire àwọn eniyan mi, Israẹli ati Juda pada. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. N óo mú wọn pada wá sí ilẹ̀ tí mo fún àwọn baba ńlá wọn, yóo sì di ohun ìní wọn.”
4 Ọ̀rọ̀ tí OLUWA sọ nípa Israẹli ati Juda nìyí:
5 “A ti gbọ́ igbe ìdágìrì ati ti ẹ̀rù,kò sì sí alaafia.
6 Ẹ bèèrè, kí ẹ sì ṣe ìwádìí;ǹjẹ́ ọkunrin lè lóyún kí ó sì bímọ?Kí ló wá dé tí mo rí gbogbo ọkunrin,tí wọn ń dáwọ́ tẹ ìbàdí bí obinrin tí ń rọbí?Kí ló dé tí gbogbo yín fajúro?
7 Ọjọ́ ńlá lọjọ́ náà yóo jẹ́,kò sí ọjọ́ tí yóo dàbí rẹ̀,àkókò ìpọ́njú ni yóo jẹ́ fún ilé Jakọbu;ṣugbọn wọn yóo bọ́ ninu rẹ̀.”
8 OLUWA ní, “Nígbà tí ó bá yá,n óo já àjàgà kúrò lọ́rùn wọn.N óo já ẹ̀wọ̀n tí wọ́n fi so wọ́n,wọn kò sì ní ṣe iranṣẹ fún àjèjì mọ́.
9 Ṣugbọn wọn yóo máa sin Ọlọrun wọn,ati ti Dafidi, ọba wọn, tí n óo gbé dìde fún wọn.
10 “Ẹ má bẹ̀rù, ẹ̀yin eniyan Jakọbu, iranṣẹ mi,ẹ má sì jẹ́ kí àyà fò yín, ẹ̀yin ọmọ Israẹli.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.N óo ti òkèèrè wá gbà yín là,N óo gba àwọn ọmọ yín tí wọ́n wà ní ìgbèkùn là pẹlu.Àwọn ọmọ Jakọbu yóo pada ní ìfọ̀kànbalẹ̀ ati ìrọ̀rùn,ẹnikẹ́ni kò sì ní dẹ́rù bà wọ́n mọ́.
11 Nítorí pé mo wà pẹlu yín, n óo gbà yín là.Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n óo pa gbogbo orílẹ̀-èdè run,gbogbo orílẹ̀-èdè tí mo fọn yín ká sí ni n óo parun patapata,ṣugbọn n kò ní pa ẹ̀yin run.N óo jẹ yín níyà,ṣugbọn n kò ní fi ìyà tí kò tọ́ jẹ yín.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
12 “Egbò yín kò lè san mọ́,ọgbẹ́ yín sì jinlẹ̀.
13 Kò sí ẹni tí yóo gba ẹjọ́ yín rò,kò ní sí òògùn fún ọgbẹ́ yín,kò ní sí ìwòsàn fun yín.
14 Gbogbo àwọn olólùfẹ́ yín ti gbàgbé yín;wọn kò bìkítà nípa yín mọ́,nítorí mo ti nà yín bí ọ̀tá mi,mo sì fi ìyà jẹ yín bí ọ̀tá tí kò láàánú,nítorí àṣìṣe yín pọ̀,nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín pọ̀ rékọjá ààlà.
15 Kí ló dé tí ẹ̀ ń sunkún,nítorí ìnira yín tí kò lóògùn?Nítorí pé ẹ̀ṣẹ̀ yín pọ̀ rékọjá ààlàni mo ṣe jẹ́ kí àwọn nǹkan wọnyi dé ba yín.
16 Ṣugbọn, gbogbo àwọn tí wọ́n bá jẹ yín run, ni a óo pada jẹ run.Gbogbo àwọn ọ̀tá yín patapata, ni yóo lọ sí ìgbèkùn.Gbogbo àwọn tí wọ́n fogun kó yín ni ogun yóo kó.N óo fi ẹrù àwọn tí wọn ń jà yín lólè fún àwọn akónilẹ́rù.
17 N óo fun yín ní ìlera,n óo sì wo àwọn ọgbẹ́ yín sàn,èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.Nítorí wọ́n ti pè yín ní ‘Ẹni ìtanù,Sioni tí ẹnikẹ́ni kò bìkítà fún.’ ”
18 OLUWA ní,“Mo ṣetán láti dá ire ilé Jakọbu pada,n óo fi ojurere wo ibùgbé rẹ̀.A óo tún ìlú náà kọ́ sórí òkítì rẹ̀,a óo sì tún kọ́ ààfin rẹ̀ sí ààyè rẹ̀ tẹ́lẹ̀.
19 Orin ọpẹ́ yóo máa ti ibẹ̀ jáde wá,a óo sì máa gbọ́ ohùn àwọn tí ń ṣe àríyá pẹlu.N óo bukun wọn, wọn óo di pupọ,n óo sọ wọ́n di ẹni iyì, wọn kò sì ní jẹ́ eniyan yẹpẹrẹ.
20 Àwọn ọmọ wọn yóo rí bí wọn ti rí ní àtijọ́,àwọn ìjọ wọn yóo fi ìdí múlẹ̀ níwájú mi.N óo sì fi ìyà jẹ gbogbo àwọn tí wọn ń ni wọ́n lára.
21 Ọ̀kan ninu wọn ni yóo jọba lórí wọn,ààrin wọn ni a óo sì ti yan olórí wọn;n óo fà á mọ́ra, yóo sì súnmọ́ mi,nítorí pé kò sí ẹni tí ó lè fúnra rẹ̀ súnmọ́ mi.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
22 Ẹ óo jẹ́ eniyan mi, n óo sì jẹ́ Ọlọrun yín.”
23 Ẹ wo ìjì OLUWA!Ibinu rẹ̀ ń bọ̀ bí ìjì líle.Ó ń bọ̀ sórí àwọn oníṣẹ́ ibi.
24 Ibinu gbígbóná OLUWA kò ní yipada,títí yóo fi mú èrò ọkàn rẹ̀ ṣẹ.Òye nǹkan wọnyi yóo ye yín ní ọjọ́ ìkẹyìn.