Jeremaya 22 BM

Iṣẹ́ tí Jeremaya Jẹ́ fún Ìdílé Ọba Juda

1 OLUWA sọ fún mi pé, kí n lọ sí ilé ọba Juda kí n sọ fún un níbẹ̀ pé,

2 “Gbọ́ ohun tí OLUWA sọ, ìwọ ọba Juda, tí o jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi, ìwọ ati àwọn ìjòyè rẹ ati àwọn eniyan rẹ, tí wọn ń gba àwọn ẹnubodè wọnyi wọlé:

3 Ẹ máa ṣe ẹ̀tọ́ ati òdodo, kí ẹ máa gba ẹni tí wọn ń jà lólè lọ́wọ́ àwọn aninilára. Ẹ má hùwà burúkú sí àwọn àlejò, tabi àwọn aláìníbaba, ati àwọn opó. Ẹ má ṣe wọ́n níbi, ẹ má sì ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ ní ibi mímọ́ yìí.

4 Nítorí pé bí ẹ bá fi tọkàntọkàn fetí sí ọ̀rọ̀ mi, àwọn ọba yóo máa wọlé, wọn yóo sì máa jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi. Wọn yóo máa gun ẹṣin ati kẹ̀kẹ́ ogun àtàwọn, ati àwọn ìjòyè wọn, ati àwọn eniyan.

5 Ṣugbọn bí ẹ kò bá gba ohun tí mo wí, mo ti fi ara mi búra pé ilẹ̀ yìí yóo di ahoro. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

6 OLUWA sọ nípa ìdílé ọba Juda pé,“Bíi Gileadi ni o dára lójú mi,ati bí orí òkè Lẹbanoni.Ṣugbọn sibẹ, dájúdájú, n óo sọ ọ́ di aṣálẹ̀;o óo sì di ìlú tí ẹnikẹ́ni kò ní gbé.

7 N óo kó àwọn apanirun tí yóo pa ọ́ run wá,olukuluku yóo wá pẹlu ohun ìjà rẹ̀.Wọn óo gé àwọn tí wọn dára jùlọ ninu àwọn igi Kedari yín,wọn óo sì sun wọ́n níná.

8 “Ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè ni yóo máa gba ìlú yìí kọjá; wọn yóo sì máa bi ara wọn pé, ‘Kí ló dé tí OLUWA fi ṣe báyìí sí ìlú ńlá yìí?’

9 Àwọn eniyan yóo sì máa dáhùn pé, ‘Nítorí pé wọ́n kọ majẹmu OLUWA Ọlọrun wọn sílẹ̀ ni, wọ́n ń bọ oriṣa, wọ́n sì ń sìn wọ́n.’ ”

Iṣẹ́ tí Jeremaya Jẹ́ Nípa Joahasi

10 Ẹ̀yin ará Juda,ẹ má sọkún nítorí ọba tí ó kú,ẹ má sì dárò rẹ̀.Ọba tí ń lọ sí ìgbèkùn ni kí ẹ sọkún fún,nítorí pé yóo lọ, kò sì ní pada wá mọ́láti fojú kan ilẹ̀ tí a bí i sí.

11 Nítorí pé OLUWA sọ nípa Joahasi, ọba Juda, ọmọ Josaya, tí ó jọba dípò Josaya baba rẹ̀, tí ó sì jáde kúrò ní ibí yìí pé, “Kò ní pada sibẹ mọ́.

12 Ibi tí wọn mú un ní ìgbèkùn lọ ni yóo kú sí; kò ní fi ojú rí ilẹ̀ yìí mọ́.”

Iṣẹ́ Tí Jeremaya Jẹ́ nípa Jehoiakimu

13 Ẹni tí ó ń fi aiṣododo kọ́ ilé rẹ̀ gbé,tí ó ń fi ọ̀nà èrú kọ́ òrùlé rẹ̀.Tí ó mú ọmọ ẹnìkejì rẹ̀ sìn lọ́fẹ̀ẹ́,láìsan owó iṣẹ́ rẹ̀ fún un.

14 Ègbé ni fún ẹni tí ó wí pé,“N óo kọ́ ilé ńlá fún ara mi,ilé tí ó ní yàrá ńláńlá lókè rẹ̀.”Ó bá yọ àwọn fèrèsé sí i lẹ́gbẹ̀ẹ́.Ó fi igi kedari bo ara ògiri rẹ̀,ó wá fi ọ̀dà pupa kùn ún.

15 Ṣé ilé kedari tí o kọ́ ni ó sọ ọ́ di ọba?Wo baba rẹ, ṣé kò rí jẹ ni,tabi kò rí mu?Ṣebí ó ṣe ẹ̀tọ́ ati òdodo,ṣebí ó sì dára fún un.

16 Ẹjọ́ ẹ̀tọ́ níí dá fún talaka ati aláìní,ohun gbogbo sì ń lọ dáradára.Ṣebí èyí ni à ń pè ní kí eniyan mọ OLUWA?OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.

17 Ṣugbọn níbi èrè aiṣododo nìkan ni ojú ati ọkàn yín ń wà,níbi kí ẹ máa pa aláìṣẹ̀, kí ẹ máa ni eniyan lára,kí ẹ sì máa hùwà ìkà.

18 Nítorí náà, OLUWA sọ nípa Jehoiakimu, ọba Juda, ọmọ Josaya pé,wọn kò ní dárò rẹ̀, pé,“Ó ṣe, arakunrin mi!”Tabi pé, “Ó ṣe, arabinrin mi!”Wọn kò ní ké pé,“Ó ṣe, oluwa mi!” Tabi pé, “Ó ṣe! Áà! Kabiyesi!”

19 Bí ẹni ń ṣe òkú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni wọ́n óo ṣe òkú rẹ̀;ẹ̀yìn odi Jerusalẹmu ni wọn yóo wọ́ ọ jù sí.Ẹ̀yin ará Jerusalẹmu,

Iṣẹ́ Tí Jeremaya Jẹ́ nípa Ohun Tí Yóo Ṣẹlẹ̀ sí Jerusalẹmu

20 ẹ gun orí òkè Lẹbanoni lọ, kí ẹ kígbe.Ẹ dúró lórí òkè Baṣani, kí ẹ pariwo gidigidi,ẹ kígbe láti orí òkè Abarimu,nítorí pé a ti pa gbogbo àwọn alájọṣe yín run.

21 OLUWA bá yín sọ̀rọ̀ nígbà tí nǹkan ń dára fun yín,ṣugbọn ẹ sọ pé ẹ kò ní gbọ́.Bẹ́ẹ̀ ni ẹ tí ń ṣe láti kékeré yín,ẹ kì í gbọ́rọ̀ sí OLUWA lẹ́nu.

22 Afẹ́fẹ́ yóo fẹ́ gbogbo àwọn olórí yín lọ,àwọn olólùfẹ́ yín yóo lọ sí ìgbèkùn.Ojú yóo wá tì yín,ẹ óo sì di ẹni ẹ̀tẹ́,nítorí gbogbo ibi tí ẹ̀ ń ṣe.

23 Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé Lẹbanoni,tí ẹ kọ́ ilé yín sí ààrin igi kedari.Ẹ óo kérora nígbà tí ara bá ń ni yín,tí ara ń ni yín bíi ti obinrin tí ń rọbí ọmọ!

Ìdájọ́ Ọlọrun lórí Jehoiakini

24 OLUWA sọ fún Jehoiakini ọba, ọmọ Jehoiakimu, ọba Juda, pé, “Mo fi ara mi búra, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Bí ó bá tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ ni òrùka èdìdì ọwọ́ ọ̀tún mi,

25 n óo bọ́ ọ kúrò, n óo sì fi ọ́ lé Nebukadinesari ọba Babiloni, ati àwọn ará Kalidea lọ́wọ́, àwọn tí wọn ń wá ẹ̀mí rẹ, tí ẹ̀rù wọn sì ń bà ọ́.

26 N óo wọ́ ìwọ ati ìyá tí ó bí ọ jù sí ilẹ̀ àjèjì, tí kì í ṣe ibi tí wọ́n bí ọ sí, ibẹ̀ ni ẹ óo kú sí.

27 Ṣugbọn ilẹ̀ tí ọkàn yín fẹ́ pada sí, ẹ kò ní pada sibẹ mọ́.”

28 Ṣé àfọ́kù ìkòkò tí ẹnikẹ́ni kò kà kún ni Jehoiakini?Àbí o ti di ohun èlò àlòpatì?Kí ló dé tí òun ati àwọn ọmọ rẹ̀fi di ẹni tí a kó lẹ́rú lọ sí ilẹ̀ tí wọn kò mọ̀ rí?

29 Ilẹ̀! Ilẹ̀!Gbọ́ ohun tí OLUWA sọ!

30 Ó ní, “Ẹ kọ orúkọ ọkunrin yìí sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aláìlọ́mọ,ẹni tí kò ní ṣe rere kan ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀;nítorí pé kò sí ọ̀kankan ninu àwọn ọmọ rẹ̀tí yóo rọ́pò rẹ̀ lórí ìtẹ́ Dafidi,Ìdílé rẹ̀ kò sì ní jọba mọ ní Juda.”