Jeremaya 13 BM

Òwe Aṣọ Funfun

1 OLUWA sọ fún mi pé, “Lọ ra aṣọ funfun kan, kí o lọ́ ọ mọ́ ìdí, má sì tì í bọ omi rárá.”

2 Mo bá ra aṣọ funfun náà, bí OLUWA ti wí, mo lọ́ ọ mọ́ ìdí.

3 OLUWA tún sọ fún mi lẹẹkeji pé,

4 “Dìde, mú aṣọ funfun tí o rà, tí o lọ́ mọ́ ìdí, lọ sí odò Yufurate, kí o lọ fi pamọ́ sí ihò àpáta níbẹ̀.”

5 Mo bá lọ fi pamọ́ sí ẹ̀bá odò Yufurate bí OLUWA ti pa á láṣẹ fún mi.

6 Lẹ́yìn ọpọlọpọ ọjọ́, OLUWA sọ fún mi pé, “Dìde, lọ sí odò Yufurate kí o mú aṣọ tí mo ní kí o fi pamọ́ sibẹ wá.”

7 Mo bá lọ sí ẹ̀bá odò Yufurate; mo gbẹ́ ilẹ̀, mo yọ aṣọ funfun náà jáde kúrò ní ibi tí mo bò ó mọ́. Ó ti bàjẹ́; kò sì wúlò fún ohunkohun mọ́.

8 OLUWA sọ fún mi pé,

9 “Bẹ́ẹ̀ gan-an ni n óo ṣe sọ ògo Juda ati ti Jerusalẹmu di ìbàjẹ́.

10 Àwọn ẹni ibi wọnyi, tí wọ́n kọ̀, tí wọn kò gbọ́ tèmi, tí wọn ń fi oríkunkun tẹ̀lé ìfẹ́ ọkàn wọn, tí wọ́n sì ti sá tọ àwọn oriṣa lọ, tí wọn ń sìn wọ́n, tí wọn sì ń bọ wọ́n. Wọn yóo dàbí aṣọ yìí tí kò wúlò fún ohunkohun.

11 Bí aṣọ ìlọ́dìí tií lẹ̀ mọ́ ọkunrin lára, bẹ́ẹ̀ ni mo mú kí gbogbo ilé Israẹli ati gbogbo ilé Juda súnmọ́ mi, kí wọ́n lè jẹ́ eniyan mi, ati orúkọ mi, ìyìn mi, ati ògo mi. Ṣugbọn wọ́n kọ̀, wọn kò gbọ́.”

Ìkòkò Waini

12 OLUWA ní, “Sọ fún wọn pé, èmi OLUWA Ọlọrun Israẹli ní, ‘Gbogbo ìkòkò ni a óo rọ ọtí waini kún.’ Wọn yóo dá ọ lóhùn pé, ‘Ṣé a kò mọ̀ pé gbogbo ìkòkò ni a óo rọ ọtí waini kún ni?’

13 Ìwọ wá wí fún wọn pé, èmi OLUWA ní n óo rọ àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ yìí ní ọtí àrọyó, ati àwọn ọba tí wọn jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi, ati àwọn alufaa, àwọn wolii ati gbogbo àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu.

14 N óo máa sọ wọ́n lu ara wọn. Baba ati ọmọ yóo máa kọlu ara wọn. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. N kò ní ṣàánú wọn, n kò ní dá ẹnikẹ́ni sí, n kò sì ní yọ́nú sí wọn débi pé kí n má fẹ́ pa wọ́n run.”

Jeremaya ṣe Ìkìlọ̀ nípa Ìgbéraga

15 Ẹ tẹ́tí sílẹ̀ kí ẹ gbọ́,ẹ má gbéraga nítorí pé OLUWA ló sọ̀rọ̀.

16 Ẹ fi ògo fún OLUWA Ọlọrun yín kí ó tó mú òkùnkùn ṣú.Kí ẹ tó bẹ̀rẹ̀ sí fẹsẹ̀ kọ lórí òkè,níbi tí kò sí ìmọ́lẹ̀.Nígbà tí ẹ bá ń wá ìmọ́lẹ̀,yóo sọ ọ́ di ìṣúdudu,yóo sọ ọ́ di òkùnkùn biribiri.

17 Ṣugbọn bí ẹ kò bá ní gbọ́,ọkàn mi yóo sọkún níkọ̀kọ̀ nítorí ìgbéraga yín.N óo sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn,omi yóo sì máa dà lójú mi,nítorí a ti kó agbo OLUWA ní ìgbèkùn.

18 Wí fún ọba ati ìyá ọba pé,“Ẹ sọ̀kalẹ̀ lórí ìtẹ́ yín,nítorí adé yín tí ó lẹ́wà ti ṣí bọ́ sílẹ̀ lórí yín.”

19 Wọ́n ti sé ìlẹ̀kùn odi àwọn ìlú ilẹ̀ Nẹgẹbukò sì sí ẹni tí yóo ṣí wọn.A ti kó gbogbo Juda lọ sí ìgbèkùn,gbogbo wọn pátá ni a ti kó lọ.

20 Ẹ gbé ojú sókè,kí ẹ wo àwọn tí ń bọ̀ láti ìhà àríwá.Àwọn agbo ẹran tí a fun yín dà,àwọn ẹran ọ̀sìn yín tí ó lẹ́wà àwọn dà?

21 Kí ni ẹ óo máa wí nígbà tí OLUWA bá mú àwọn tí ẹ fi ṣe ọ̀rẹ́,tí ó fi wọ́n jọba le yín lórí?Ǹjẹ́ ìnira kò ní ba yín, bí ìrora obinrin tí ń rọbí?

22 Bí ẹ bá wí lọ́kàn yín pé,“Kí ló dé tí irú èyí fi dé bá wa?”Ẹ̀ṣẹ̀ yín ni ó pọ̀, ni a fi ká aṣọ ní ìdí yín,tí a sì jẹ yín níyà.

23 Ṣé ó ṣeéṣe kí ará Kuṣi yí àwọ̀ ara rẹ̀ pada?Àbí kí àmọ̀tẹ́kùn fọ tóótòòtóó ara rẹ̀ dànù?Bí ó bá ṣeéṣe, á jẹ́ wí pé ẹ̀yin náà lè hùwà rere;ẹ̀yin tí ibi ṣíṣe ti mọ́ lára.

24 N óo fọn yín ká bí ìyàngbòtí afẹ́fẹ́ láti inú aṣálẹ̀ ń fẹ́ kiri.

25 Èyí ni ìpín yín,ìpín tí mo ti yàn fun yín,nítorí pé ẹ ti gbàgbé èmi OLUWA, ẹ sì gbẹ́kẹ̀lé ọlọrun èké.

26 Èmi gan-an ni n óo ká aṣọ lára yín,n óo sì fi bò yín lójú, kí ayé lè rí ìhòòhò yín.

27 Mo ti rí ìwà ìbàjẹ́ yín,gbogbo ìwà àgbèrè yín, bí ẹ tí ń yan ká bí akọ ẹṣin,ati ìwà ìṣekúṣe yín ní orí àwọn òkè ninu pápá.Ẹ̀yin ará Jerusalẹmu, ẹ gbé!Yóo ti pẹ́ tó kí á tó wẹ̀ yín mọ́?