Jeremaya 43 BM

Wọ́n Mú Jeremaya Lọ sí Ijipti

1 Nígbà tí Jeremaya parí gbogbo ọ̀rọ̀ tí OLUWA Ọlọrun wọn rán an sí gbogbo àwọn ará ìlú,

2 Asaraya, ọmọ Hoṣaaya, ati Johanani, ọmọ Karea, ati gbogbo àwọn ọkunrin aláfojúdi kan wí fún Jeremaya pé, “Irọ́ ni ò ń pa. OLUWA Ọlọrun wa kò rán ọ láti sọ fún wa pé kí á má lọ ṣe àtìpó ní Ijipti.

3 Baruku, ọmọ Neraya, ni ó fẹ́ mú wa kọlù ọ́, kí o lè fà wá lé àwọn ará Kalidea lọ́wọ́, kí wọ́n lè pa wá; tabi kí wọ́n kó wa lọ sí ìgbèkùn ní Babiloni.”

4 Nítorí náà Johanani, ọmọ Karea, ati gbogbo àwọn olórí ogun ati gbogbo àwọn ará ìlú kò gba ohun tí OLUWA sọ, pé kí wọ́n dúró ní ilẹ̀ Juda.

5 Kàkà bẹ́ẹ̀, Johanani, ọmọ Karea, ati gbogbo àwọn olórí ogun kó gbogbo àwọn ará Juda tí wọ́n ṣẹ́kù, tí wọ́n pada wá sí ilẹ̀ Juda láti oríṣìíríṣìí orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti sálọ:

6 àwọn ọkunrin ati àwọn obinrin, àwọn ọmọde, àwọn ìjòyè, ati gbogbo àwọn tí Nebusaradani, olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ ọba Babiloni, fi sábẹ́ àkóso Gedalaya ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani, ati Jeremaya wolii ati Baruku ọmọ Neraya.

7 Wọ́n kó wọn lọ sí ilẹ̀ Ijipti, nítorí wọn kò fetí sí ọ̀rọ̀ OLUWA Ọlọrun wọn. Wọ́n lọ títí tí wọ́n fi dé Tapanhesi.

8 OLUWA bá Jeremaya sọ̀rọ̀ ní Tapanhesi:

9 Ó ní, “Gbé òkúta ńláńlá lọ́wọ́, kí o bò wọ́n mọ́lẹ̀, níbi pèpéle tí ó wà lẹ́nu ọ̀nà ààfin Farao ní Tapanhesi, lójú àwọn ará Juda,

10 kí o sì wí fún wọn pé OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní òun óo lọ mú Nebukadinesari ọba Babiloni, iranṣẹ òun wá, yóo sì gbé ìtẹ́ rẹ̀ ka orí àwọn òkúta tí òun rì mọ́lẹ̀ yìí, Nebukadinesari yóo sì tẹ́ ìtẹ́ ọlá rẹ̀ sórí wọn.

11 Yóo wá kọlu ilẹ̀ Ijipti, yóo jẹ́ kí àjàkálẹ̀ àrùn pa àwọn tí yóo kú ikú àjàkálẹ̀ àrùn, yóo kó àwọn tí yóo lọ sí ìgbèkùn lọ sí ìgbèkùn, yóo sì fi idà pa àwọn tí yóo kú ikú idà.

12 Yóo dáná sun àwọn ilé àwọn oriṣa ilẹ̀ Ijipti; yóo jó wọn níná; yóo sì kó àwọn ará ìlú lọ sí ìgbèkùn; yóo fọ ilẹ̀ Ijipti mọ́ bí darandaran tíí ṣa eégbọn kúrò lára aṣọ rẹ̀, yóo sì jáde kúrò níbẹ̀ ní alaafia.

13 Yóo fọ́ àwọn òpó ilé oriṣa Heliopolisi tí ó wà ní ilẹ̀ Ijipti, yóo sì dáná sun àwọn ilé àwọn oriṣa ilẹ̀ Ijipti.”