1 OLUWA ní, “Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, bí ẹ bá fẹ́ yipada, ọ̀dọ̀ mi ni kí ẹ pada sí. Mo kórìíra ìbọ̀rìṣà; nítorí náà bí ẹ bá jáwọ́ ninu rẹ̀, tí ẹ kò bá ṣìnà kiri mọ́,
2 tí ẹ bá ń búra pẹlu òtítọ́ pé, ‘Bí OLUWA ti wà láàyè,’ lórí ẹ̀tọ́ ati òdodo, àwọn orílẹ̀-èdè yòókù yóo máa fi orúkọ mi súre fún ara wọn, wọn yóo sì máa ṣògo ninu mi.”
3 Nítorí pé OLUWA sọ fún àwọn ará Juda ati àwọn tí wọn ń gbé Jerusalẹmu pé, “Ẹ tún oko yín tí ẹ ti patì tẹ́lẹ̀ kọ, ẹ má sì gbin èso sáàrin ẹ̀gún.
4 Ẹ kọ ara yín ní ilà abẹ́ fún OLUWA, kí ẹ sì kọ ara yín ní ilà ọkàn, ẹ̀yin ará Juda ati ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé Jerusalẹmu; kí ibinu mi má baà dé, bí iná tí ó ń jó tí kò sí ẹni tí ó lè pa á, nítorí iṣẹ́ ibi yín.”
5 Ẹ sọ ọ́ ní Juda,ẹ sì kéde rẹ̀ láàrin Jerusalẹmu pé,“Ẹ fọn fèrè káàkiri ilẹ̀ náà,kí ẹ sì kígbe sókè pé,‘Ẹ kó ara yín jọ kí á lọ sí àwọn ìlú olódi.’
6 Ẹ gbé àsíá sókè sí Sioni,pé kí wọn sá àsálà, kí wọn má ṣe dúró,nítorí mò ń mú ibi ati ìparun ńlá bọ̀ láti ìhà àríwá.
7 Kinniun kan ti jáde lọ láti inú igbó tí ó wà;ọ̀kan ninu àwọn tí wọ́n máa ń run àwọn orílẹ̀-èdè ti gbéra;ó ti jáde kúrò ní ipò rẹ̀,láti sọ ilẹ̀ yín di ahoro.Yóo pa àwọn ìlú yín run,kò sì ní sí eniyan ninu wọn mọ́.
8 Nítorí èyí, ẹ fi aṣọ ọ̀fọ̀ bora,ẹ sọkún kí ẹ máa ké tẹ̀dùntẹ̀dùn,nítorí ìrúnú gbígbóná OLUWAkò tíì yipada kúrò lọ́dọ̀ wa.”
9 OLUWA ní, “Tó bá di ìgbà náà, ojora yóo mú ọba ati àwọn ìjòyè, àwọn alufaa yóo dààmú, ẹnu yóo ya àwọn wolii.”
10 Mo bá dáhùn pé, “Háà, OLUWA Ọlọrun, àṣé ò ń tan àwọn eniyan wọnyi, ati àwọn ará Jerusalẹmu ni, nígbà tí o sọ fún wọn pé, yóo dára fún wọn; àṣé idà ti dé ọrùn wọn!”
11 A óo wí fún àwọn eniyan yìí, ati àwọn ará Jerusalẹmu ní ìgbà náà pé afẹ́fẹ́ gbígbóná kan ń fẹ́ bọ̀ láti orí àwọn òkè, ninu pápá, ó ń fẹ́ bọ̀ sọ́dọ̀ àwọn eniyan mi; kì í ṣe afẹ́fẹ́ lásán tíí fẹ́ pàǹtí ati ìdọ̀tí dànù.
12 Ìjì tí yóo ti ọ̀dọ̀ mi wá yóo le jù bẹ́ẹ̀ lọ. Nisinsinyii èmi ni mò ń fi ọ̀rọ̀ mi dá wọn lẹ́jọ́.
13 Ẹ wò ó! Ó ń bọ̀ bí ìkùukùu,kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ dàbí ìjì.Àwọn ẹṣin rẹ̀ yára ju àṣá lọ.A gbé, nítorí ìparun dé bá wa.
14 Ìwọ Jerusalẹmu, fọ ibi dànù kúrò lọ́kàn rẹ,kí á lè gbà ọ́ là.Yóo ti pẹ́ tó tí èrò burúkú yóo fi máa wà lọ́kàn rẹ?
15 Nítorí a gbọ́ ohùn kan láti ilẹ̀ Dani,tí ń kéde ibi láti òkè Efuraimu.
16 Ẹ kìlọ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè pé ó ń bọ̀,kéde fún Jerusalẹmu pé,àwọn ológun tí ń dó ti ìlú ń bọ̀, láti ilẹ̀ òkèèrè.Wọ́n ń kọ lálá sí àwọn ìlú Juda.
17 Wọ́n yí i ká bí àwọn tí ó ń ṣọ́ oko,nítorí pé ó ti ṣọ̀tẹ̀ sí OLUWA.OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.
18 Ìrìn ẹsẹ̀ rẹ ati ìwà rẹni ó mú kí àwọn nǹkan wọnyi dé bá ọ.Ìjìyà rẹ nìyí, ó sì korò;ó ti dé oókan àyà rẹ.
19 Oró ò! Oró ò!Mò ń jẹ̀rora!Àyà mi ò!Àyà mi ń lù kìkìkì,n kò sì lè dákẹ́;nítorí mo gbọ́ ìró fèrè ogun, ati ariwo ogun.
20 Àjálù ń ṣubú lu àjálù,gbogbo ilẹ̀ ti parun.Lójijì àgọ́ mi wó lulẹ̀,aṣọ títa mi sì fàya ní ìṣẹ́jú kan.
21 Yóo ti pẹ́ tó tí n óo máa wo àsíá ogun,tí n óo sì máa gbọ́ fèrè ogun?
22 OLUWA ní, “Nítorí pé àwọn eniyan mi gọ̀,wọn kò mọ̀ mí.Òmùgọ̀ ọmọ ni wọ́n;wọn kò ní òye.Ọgbọ́n àtiṣe ibi kún inú wọn:ṣugbọn wọn kò mọ rere ṣe.”
23 Mo bojú wo ilé ayé, ilé ayé ṣófo,ó rí júujùu;mo ṣíjú wo ojú ọ̀run,kò sí ìmọ́lẹ̀ níbẹ̀.
24 Mo wo àwọn òkè ńlá, wọ́n ń mì tìtì,gbogbo òkè kéékèèké ń sún lọ síhìn-ín sọ́hùn-ún.
25 Mo wò yíká, n kò rí ẹnìkan,gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run ti fò sálọ.
26 Mo wò yíká, mo rí i pé gbogbo ilẹ̀ ọlọ́ràá ti di aṣálẹ̀,gbogbo ìlú sì ti di òkítì àlàpà níwájú OLUWA,nítorí ibinu ńlá rẹ̀.
27 Nítorí OLUWA ti sọ pé,gbogbo ilẹ̀ náà yóo di ahoro;sibẹ òpin kò ní tíì dé.
28 Nítorí èyí, ilẹ̀ yóo ṣọ̀fọ̀,ojú ọ̀run yóo sì ṣókùnkùn.Nítorí pé ó ti sọ bẹ́ẹ̀,ó ti rò ó dáradára, kò tíì jáwọ́ ninu rẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni kò ní yipada.
29 Nígbà tí wọ́n gbọ́ ariwo àwọn ẹlẹ́ṣin ati ti àwọn tafàtafà,gbogbo ìlú sá jáde fún ààbò.Wọ́n sá wọ inú igbó lọ,wọ́n gun orí òkè lọ sinu pàlàpálá òkúta;gbogbo ìlú sì di ahoro.
30 Ìwọ tí o ti di ahoro,kí ni èrò rẹ tí o fi wọ aṣọ elése àlùkò?Tí o wa nǹkan ọ̀ṣọ́ wúrà sára?Tí o tọ́ ojú?Tí o tọ́ ètè?Asán ni gbogbo ọ̀ṣọ́ tí o ṣe,àwọn olólùfẹ́ rẹ kò kà ọ́ sí,ọ̀nà ati gba ẹ̀mí rẹ ni wọ́n ń wá.
31 Nítorí mo gbọ́ igbe kan, tí ó dàbí igbe obinrin tí ó ń rọbí,ó ń kérora bí aboyún tí ó ń rọbí alákọ̀ọ́bí.Mo gbọ́ igbe Jerusalẹmu tí ń pọ̀ọ̀kà ikú,tí ó na ọwọ́ rẹ̀ síta, tí ń ké pé,“Mo gbé! Mò ń kú lọ, lọ́wọ́ àwọn apànìyàn!”