Jeremaya 41 BM

1 Ní oṣù keje ni Iṣimaeli, ọmọ Netanaya ọmọ Eliṣama dé, ìdílé ọba ni ó ti wá, ó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìjòyè ọba. Òun pẹlu àwọn ọkunrin mẹ́wàá bá lọ sọ́dọ̀ Gedalaya ọmọ Ahikamu ní Misipa. Bí wọ́n ṣe ń jẹun lọ́wọ́ ní Misipa,

2 Iṣimaeli, ọmọ Netanaya ati àwọn mẹ́wàá tí wọ́n bá a wá dìde, wọ́n bá fi idà pa Gedalaya tí ọba Babiloni fi ṣe gomina ilẹ̀ náà.

3 Iṣimaeli pa gbogbo àwọn Juu tí wọ́n wà pẹlu Gedalaya ní Misipa, ati gbogbo àwọn ọmọ ogun Kalidea tí wọ́n wà níbẹ̀.

4 Ọjọ́ keji tí wọ́n pa Gedalaya tán, kí ẹnikẹ́ni tó gbọ́ nípa rẹ̀,

5 àwọn ọgọrin eniyan kan wá láti Ṣekemu, Ṣilo ati láti Samaria pẹlu irùngbọ̀n wọn ní fífá, wọ́n fa agbádá wọn ya, wọ́n sì ṣá ara wọn lọ́gbẹ́. Wọ́n mú ọrẹ ẹbọ ati turari lọ́wọ́ wá sí Tẹmpili OLUWA.

6 Iṣimaeli, ọmọ Netanaya sọkún pàdé wọn láti Misipa. Bí ó ti pàdé wọn ó wí pé, “Ẹ máa kálọ sí ọ̀dọ̀ Gedalaya ọmọ Ahikamu.”

7 Nígbà tí wọ́n wọ ààrin ìlú, Iṣimaeli ọmọ Netanaya ati àwọn tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ pa wọ́n, wọ́n sì kó òkú wọn dà sí inú kòtò.

8 Ṣugbọn àwọn mẹ́wàá kan ninu wọn sọ fún Iṣimaeli pé, “Má pa wá, nítorí a ní ọkà wíítì, ọkà baali, ati òróró ati oyin ní ìpamọ́ ninu oko.” Nítorí náà, ó fi wọ́n sílẹ̀ kò sì pa wọ́n bí ó ti pa àwọn yòókù wọn.

9 Kòtò tí Iṣimaeli ju òkú àwọn eniyan tí ó pa sí ni kòtò tí ọba Asa gbẹ́ tí ó fi dí ọ̀nà mọ́ Baaṣa ọba Israẹli; ṣugbọn Iṣimaeli, ọmọ Netanaya fi òkú eniyan tí ó pa kún kòtò náà.

10 Iṣimaeli bá kó gbogbo àwọn tí wọ́n kù ní Misipa lẹ́rú, àwọn ọmọ ọba lobinrin ati gbogbo àwọn tí wọ́n kù ní Misipa, àwọn tí Nebusaradani olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ọba fi sí abẹ́ ìṣọ́ Gedalaya. Iṣimaeli kó wọn lẹ́rú ó sì fẹ́ kó wọn kọjá sí ọ̀dọ̀ àwọn ará Amoni.

11 Nígbà tí Johanani, ọmọ Karea ati gbogbo àwọn olórí ogun tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ gbọ́ gbogbo iṣẹ́ ibi tí Iṣimaeli, ọmọ Netanaya ṣe,

12 wọ́n kó gbogbo àwọn ọmọ ogun wọn lọ gbógun ti Iṣimaeli, wọ́n bá a létí odò ńlá tí ó wà ní Gibeoni.

13 Nígbà tí gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà lọ́dọ̀ Iṣimaeli rí Johanani, ọmọ Karea ati gbogbo àwọn olórí ogun tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀, inú wọn dùn.

14 Ni gbogbo àwọn tí Iṣimaeli kó lẹ́rú ní Misipa bá yipada kúrò lẹ́yìn rẹ̀, wọ́n lọ bá Johanani ọmọ Karea.

15 Ṣugbọn Iṣimaeli, ọmọ Netanaya, pẹlu àwọn mẹjọ sá àsálà lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Amoni.

16 Lẹ́yìn náà Johanani ọmọ Karea, ati gbogbo àwọn olórí ogun tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀, kó gbogbo àwọn tí Iṣimaeli ọmọ Netanaya kó lẹ́rú ní Misipa, lẹ́yìn tí ó pa Gedalaya ọmọ Ahikamu tán, ó bá kó ati àwọn ọmọ ogun, ati àwọn obinrin, ati àwọn ọmọde, ati àwọn ìwẹ̀fà, pada wá láti Gibeoni.

17 Wọ́n lọ ń gbé Geruti Kimhamu, tí ó wà lẹ́bàá Bẹtilẹhẹmu. Wọ́n pinnu láti kó lọ sí ilẹ̀ Ijipti nítorí ẹ̀rù àwọn ará Kalidea ń bà wọ́n;

18 nítorí pé Iṣimaeli ọmọ Netanaya ti pa Gedalaya, ọmọ Ahikamu, tí ọba Babiloni fi ṣe gomina ilẹ̀ náà.