1 OLUWA rán Jeremaya níṣẹ́, ó ní
2 kí Jeremaya dúró sí ẹnu ọ̀nà ilé OLUWA, kí ó sì kéde pé: “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA, gbogbo ẹ̀yin ará Juda tí ń gba ẹnu ọ̀nà wọnyi wọlé láti sin OLUWA.
3 OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní: ‘Ẹ tún ìrìn ẹsẹ̀ yín ati iṣẹ́ ọwọ́ yín ṣe, kí n lè jẹ́ kí ẹ máa gbé ìhín.
4 Ẹ má ṣe gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn yìí pé: “Tẹmpili OLUWA nìyí, kò séwu, tẹmpili OLUWA nìyí.”
5 “ ‘Bí ẹ bá tún ìrìn ẹsẹ̀ yín ati iṣẹ́ ọwọ́ yín ṣe nítòótọ́, tí ẹ bá ń dá ẹjọ́ òtítọ́,
6 tí ẹ kò bá fi ìyà jẹ àwọn àlejò, ati àwọn aláìníbaba, tabi àwọn opó, tabi kí ẹ máa ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ ní ibí yìí, tí ẹ kò sì máa bọ oriṣa káàkiri, kí ẹ fi kó bá ara yín,
7 n óo jẹ́ kí ẹ máa gbé ibí yìí títí lae, lórí ilẹ̀ tí mo fún àwọn baba ńlá yín láti ìgbà laelae.
8 “ ‘Ẹ wò ó! Ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn tí kò lè mú èrè wá ni ẹ gbójú lé.
9 Ṣé ẹ fẹ́ máa jalè, kí ẹ máa pa eniyan, kí ẹ máa ṣe àgbèrè, kí ẹ máa búra èké, kí ẹ máa sun turari sí oriṣa Baali, kí ẹ máa bọ àwọn oriṣa tí ẹ kò mọ̀ káàkiri;
10 kí ẹ sì tún máa wá jọ́sìn níwájú mi ninu ilé yìí, ilé tí à ń fi orúkọ mi pè; kí ẹ máa wí pé, “OLUWA ti gbà wá là;” kí ẹ sì tún pada lọ máa ṣe gbogbo àwọn nǹkan ìríra tí ẹ tí ń ṣe?
11 Ṣé lójú tiyín, ilé yìí, tí à ń fi orúkọ mi pè, ó ti wá di ibi ìsápamọ́ sí fún àwọn olè? Mo ti ri yín; èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
12 Nisinsinyii, ẹ lọ sí ilé mi ní Ṣilo, níbi ìjọ́sìn mi àkọ́kọ́, kí ẹ sì wo ohun tí mo ṣe sí i, nítorí ìwà burúkú Israẹli, àwọn eniyan mi.
13 Nisinsinyii, nítorí gbogbo ohun tí ẹ̀ ń ṣe wọnyi, tí mo sì ń ba yín sọ̀rọ̀ lemọ́lemọ́, tí ẹ kò gbọ́, tí mo pè yín, tí ẹ kò dáhùn,
14 bí mo ti ṣe sí Ṣilo ni n óo ṣe ilé tí à ń fi orúkọ mi pè, tí ẹ gbójú lé; ati ilẹ̀ tí mo fún ẹ̀yin ati àwọn baba ńlá yín. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
15 N óo le yín kúrò níwájú mi, bí mo ti lé àwọn ọmọ Efuraimu, tí wọ́n jẹ́ arakunrin yín dànù.’ ”
16 OLUWA ní, “Ìwọ Jeremaya ní tìrẹ, má bẹ̀bẹ̀ fún àwọn eniyan wọnyi, má sọkún nítorí wọn, tabi kí o gbadura fún wọn. Má sì bẹ̀ mí nítorí wọn, nítorí n kò ní gbọ́.
17 Ṣé o kò rí àwọn ohun tí wọn ń ṣe ninu àwọn ìlú Juda ati ní ìgboro Jerusalẹmu ni?
18 Àwọn ọmọ ń kó igi jọ, àwọn baba wọn ń dá iná, àwọn obinrin ń po ìyẹ̀fun láti fi ṣe àkàrà fún Ayaba Ọ̀run. Wọ́n sì ń ta ọtí sílẹ̀ fún àwọn oriṣa láti mú mi bínú.
19 Ṣé èmi ni wọ́n ń mú bínú? Kì í ṣe pé ara wọn ni wọ́n ń ṣe, tí wọ́n sì ń dójú ti ara wọn?
20 Nítorí náà, èmi OLUWA Ọlọrun óo tú ibinu gbígbóná mi sórí ibí yìí, n óo bínú sí eniyan ati ẹranko, ati igi oko ati èso ilẹ̀. Ibinu mi óo jó wọn run bí iná, kò sì ní ṣe é pa.
21 “Ẹ da ẹbọ sísun yín pọ̀ mọ́ ẹran tí ẹ fi rúbọ, kí ẹ lè rí ẹran jẹ; Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
22 Nítorí ní ọjọ́ tí mo kó àwọn baba yín jáde ní ilẹ̀ Ijipti, n kò bá wọn sọ̀rọ̀ ẹbọ sísun tabi ẹbọ rírú, bẹ́ẹ̀ ni n kò pàṣẹ rẹ̀ fún wọn.
23 Àṣẹ tí mo pa fún wọn ni pé kí wọn gbọ́ràn sí mi lẹ́nu. Mo ní n óo máa jẹ́ Ọlọrun wọn, àwọn náà óo sì máa jẹ́ eniyan mi; mo ní kí wọn máa tọ ọ̀nà tí mo bá pa láṣẹ fún wọn, kí ó lè dára fún wọn.
24 Ṣugbọn wọn kò gbọ́ràn, wọn kò sì tẹ́tí sí mi. Wọ́n ń tẹ̀lé ìmọ̀ ara wọn, wọ́n ń ṣe oríkunkun, dípò kí wọ́n máa lọ siwaju, ẹ̀yìn ni wọ́n ń pada sí.
25 Láti ọjọ́ tí àwọn baba ńlá yín ti jáde ní ilẹ̀ Ijipti títí di òní, lojoojumọ ni mò ń rán àwọn wolii iranṣẹ mi sí wọn léraléra.
26 Sibẹ wọn kò gbọ́ tèmi, wọn kò tẹ́tí sí mi. Kàkà bẹ́ẹ̀, oríkunkun ni wọ́n ń ṣe. Iṣẹ́ burúkú wọn ju ti àwọn baba ńlá wọn lọ.
27 “Gbogbo ọ̀rọ̀ wọnyi ni o óo sọ fún wọn, ṣugbọn wọn kò ní gbọ́. O óo pè wọ́n, ṣugbọn wọn kò ní dá ọ lóhùn.
28 O óo sọ fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin ni orílẹ̀-èdè tí kò gbọ́ ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ̀, tí kò sì gbọ́ ìbáwí. Òtítọ́ kò sí mọ́ ninu ìṣe yín, bẹ́ẹ̀ ni, kò sì sí ninu ọ̀rọ̀ ẹnu yín.’
29 “Ẹ gé irun orí yín dànù,ẹ lọ sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn lórí òkè,nítorí OLUWA ti kọ ìran yín sílẹ̀,ó ti fi ibinu ta ìran yín nù.
30 “Àwọn ọmọ Juda ti ṣe nǹkan burúkú. Wọ́n gbé ère wọn kalẹ̀ ninu ilé tí à ń fi orúkọ mi pè, wọ́n sì ti sọ ọ́ di aláìmọ́.
31 Wọ́n kọ́ pẹpẹ Tofeti ní àfonífojì Hinomu, wọ́n ń sun àwọn ọmọkunrin ati àwọn ọmọbinrin wọn níná níbẹ̀. N kò pa irú àṣẹ bẹ́ẹ̀ fún wọn; irú nǹkan bẹ́ẹ̀ kò tilẹ̀ fi ìgbà kan sí lọ́kàn mi.
32 Nítorí náà nígbà tó bá yá, a kò ní pè é ní Tofeti tabi àfonífojì ọmọ Hinomu mọ́, àfonífojì ìpànìyàn ni a óo sì máa pè é. Tofeti ni wọn yóo sì máa sin òkú sí nígbà tí kò bá sí ààyè ní ibòmíràn mọ́.
33 Òkú àwọn eniyan yìí yóo di oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ati fún àwọn ẹranko, kò sì ní sí ẹni tí yóo lé wọn.
34 N óo fi òpin sí ẹ̀rín ati ìró ayọ̀ ní Jerusalẹmu, a kò sì ní gbọ́ ohùn ọkọ iyawo ati ohùn iyawo àṣẹ̀ṣẹ̀gbé níbẹ̀ mọ́; nítorí pé n óo sọ ilẹ̀ náà di ahoro.