1 Lẹ́yìn tí Nebukadinesari, ọba Babiloni ti kó Jehoiakini ọba Juda, ọmọ Jehoiakimu kúrò ní ìlú Jerusalẹmu lọ sí Babiloni, pẹlu àwọn ìjòyè Juda, ati àwọn oníṣẹ́ ọnà, ati àwọn alágbẹ̀dẹ, OLUWA fi ìran yìí hàn mí. Mo rí apẹ̀rẹ̀ èso ọ̀pọ̀tọ́ meji níwájú ilé OLUWA.
2 Èso ọ̀pọ̀tọ́ tí ó wà ninu apẹ̀rẹ̀ kinni dára gbáà, ó dàbí èso ọ̀pọ̀tọ́ tí ó kọ́kọ́ pọ́n. Èso ọ̀pọ̀tọ́ tí ó wà ninu apẹ̀rẹ̀ keji ti rà patapata tóbẹ́ẹ̀ tí kò ṣe é jẹ. p
3 OLUWA bá bi mí pé, “Jeremaya, kí ni o rí?”Mo ní, “Èso ọ̀pọ̀tọ́ ni, àwọn tí ó dára, dára gan-an, àwọn tí kò sì dára bàjẹ́ tóbẹ́ẹ̀ tí wọn kò ṣe é jẹ.”
4 OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní,
5 “Ohun tí èmi OLUWA Ọlọrun Israẹli sọ nípa àwọn ará Juda tí wọ́n wà ní ìgbèkùn, àwọn tí mo ti mú kí á kó lẹ́rú láti ibí yìí lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Kalidea, ni pé, n óo kà wọ́n sí rere gẹ́gẹ́ bí àwọn èso ọ̀pọ̀tọ́ dáradára wọnyi.
6 N óo fi ojurere wò wọ́n, n óo kó wọn pada wá sí ilẹ̀ yìí. N óo fìdí wọn múlẹ̀, n kò sì ní pa wọ́n run. N óo gbé wọn ró, n kò ní fà wọ́n tu,
7 n óo sì fún wọn ní òye láti mọ̀ pé èmi ni OLUWA. Wọn yóo jẹ́ eniyan mi, èmi náà óo sì jẹ́ Ọlọrun wọn; nítorí tí wọn yóo fi tọkàntọkàn yipada sí mi.”
8 Ṣugbọn ohun tí OLUWA sọ nípa Sedekaya ọba Juda, ati àwọn ìjòyè rẹ̀, ati àwọn ará Jerusalẹmu tí wọ́n kù ní ilẹ̀ yìí, ati àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ Ijipti, ni pé òun óo ṣe wọ́n bí èso burúkú tí kò ṣe é jẹ.
9 Ó ní òun óo sọ wọ́n di ẹni àríbẹ̀rù fún gbogbo ìjọba ayé. Wọn óo di ẹni ẹ̀gàn, ẹni ẹ̀sín, ẹni yẹ̀yẹ́ ati ẹni tí a fi ń ṣẹ́ èpè ní gbogbo ibi tí òun óo tì wọ́n lọ.
10 Ó ní òun óo rán ogun, ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn sí wọn, títí wọn yóo fi kú tán, tí kò ní ku ẹyọ ẹnìkan lórí ilẹ̀ tí òun fún àwọn ati àwọn baba ńlá wọn.