1 OLUWA bá Jeremaya wolii sọ̀rọ̀ nípa Filistini kí Farao tó ṣẹgun Gasa,
2 Ó ní,“Wò ó, omi kan ń ru bọ̀ láti ìhà àríwá,yóo di àgbàrá tí ó lágbára;yóo ya bo ilẹ̀ yìí ati gbogbo ohun tí ó wà lórí rẹ̀,yóo ya bo ìlú yìí pẹlu, ati àwọn tí wọn ń gbé inú rẹ̀.Àwọn eniyan yóo kígbe: gbogbo àwọn ará ìlú yóo sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn.
3 Nígbà tí pátákò ẹsẹ̀ ẹṣin bá ń dún,tí àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ bá ń sáré,tí ẹsẹ̀ àwọn kẹ̀kẹ́ ogun sì ń pariwo,Àwọn baba kò ní lè wo àwọn ọmọ wọn lẹ́yìn pé kí àwọn fà wọ́n,nítorí pé ọwọ́ wọn yóo rọ;
4 nítorí ọjọ́ tí ń bọ̀, tí yóo jẹ́ ọjọ́ ìparun gbogbo àwọn ará Filistia,ọjọ́ tí a óo run gbogbo àwọn olùrànlọ́wọ́ tí ó kù fún Tire ati Sidoni.Nítorí pé OLUWA yóo pa àwọn ará Filistia run,àwọn tí wọ́n kù ní etí òkun ní Kafitori.
5 Ìbànújẹ́ ti dé bá Gasa, Aṣikeloni ti parun.Ẹ̀yin tí ẹ kù lára àwọn ọmọ Anakimu, ẹ óo ti fi ìbànújẹ́ ṣá ara yín lọ́gbẹ́ pẹ́ tó?
6 Ẹ̀yin ń bèèrè pé, ‘Ìwọ idà OLUWA,yóo ti pẹ́ tó kí o tó sinmi?Pada sinu àkọ̀ rẹ, máa sinmi kí o sì dúró jẹ́ẹ́.’
7 Ṣugbọn idà OLUWA ṣe lè dákẹ́ jẹ́ẹ́, nígbà tí Oluwa fún un ní iṣẹ́ láti ṣe?OLUWA ti pàṣẹ fún un láti kọlu Aṣikeloni, ati àwọn ìlú etí òkun.”