1 Ní ọdún kẹrin ìjọba Jehoiakimu ọmọ Josaya ọba Juda, OLUWA sọ fún Jeremaya pé,
2 “Mú ìwé kíká kí o sì kọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo sọ fún ọ nípa Israẹli ati Juda ati gbogbo orílẹ̀-èdè sinu rẹ̀. Gbogbo ohun tí mo sọ láti ọjọ́ tí mo ti ń bá ọ sọ̀rọ̀ ní ìgbà ayé Josaya títí di òní, ni kí o kọ.
3 Bóyá bí àwọn ará Juda bá gbọ́ nípa ibi tí mò ń gbèrò láti ṣe sí wọn, olukuluku lè yipada kúrò ninu ọ̀nà ibi rẹ̀, kí n lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ ati àìdára wọn jì wọ́n.”
4 Jeremaya bá pe Baruku ọmọ Neraya, ó sọ àwọn ọ̀rọ̀ tí OLUWA bá a sọ fún un, Baruku bá kọ wọ́n sinu ìwé kíká kan.
5 Jeremaya pàṣẹ fún Baruku pé, “Wọn kò gbà mí láàyè láti lọ sí inú ilé OLUWA;
6 nítorí náà, ìwọ ni óo lọ sibẹ ní ọjọ́ ààwẹ̀ láti ka ọ̀rọ̀ tí o gbọ́ ní ẹnu mi; tí o sì kọ sí inú ìwé kíká, sí etí gbogbo àwọn ará Juda tí wọ́n wá láti ìlú wọn.
7 Ó ṣeéṣe kí wọn mú ẹ̀bẹ̀ wọn wá siwaju OLUWA, kí olukuluku sì yipada kúrò lọ́nà ibi rẹ̀ tí ó ń rìn, nítorí pé ibinu OLUWA pọ̀ lórí wọn.”
8 Baruku bá ṣe gbogbo ohun tí Jeremaya wolii pa láṣẹ fún un lati kà lati inú ìwé ilé Oluwa.
9 Ní oṣù kẹsan-an, ọdún karun-un tí Jehoiakimu ọmọ Josaya jọba ní Juda, gbogbo àwọn tí wọn ń gbé Jerusalẹmu ati àwọn eniyan tí wọ́n ti àwọn ìlú Juda wá sí Jerusalẹmu, kéde ọjọ́ ààwẹ̀ níwájú OLUWA.
10 Baruku bá ka ọ̀rọ̀ Jeremaya tí ó kọ sinu ìwé, sí etígbọ̀ọ́ gbogbo eniyan ní yàrá Gemaraya, ọmọ Ṣafani, akọ̀wé, tí ó wà ní gbọ̀ngàn òkè ní Ẹnu Ọ̀nà Titun ilé OLUWA.
11 Nígbà tí Mikaaya ọmọ Gemaraya, ọmọ Ṣafani gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ OLUWA tí ó wà ninu ìwé náà;
12 Ó lọ sí yàrá akọ̀wé ní ààfin ọba, ó bá gbogbo àwọn ìjòyè tí wọn jókòó níbẹ̀: Eliṣama akọ̀wé ati Delaaya ọmọ Ṣemaaya, ati Elinatani ọmọ Akibori, ati Gemaraya ọmọ Ṣafani, ati Sedekaya ọmọ Hananaya ati gbogbo àwọn ìjòyè.
13 Mikaaya sọ gbogbo ohun tí ó gbọ́, nígbà tí Baruku ka ohun tí ó kọ sinu ìwé fún wọn.
14 Gbogbo àwọn ìjòyè bá rán Jehudi ọmọ Netanaya, ọmọ Ṣelemaya ọmọ Kuṣi pé kí ó lọ sọ fún Baruku kí ó máa bọ̀ kí ó sì mú ìwé tí ó kà sí etígbọ̀ọ́ gbogbo eniyan lọ́wọ́. Baruku, ọmọ Neraya, sì wá sọ́dọ̀ wọn tòun ti ìwé náà lọ́wọ́ rẹ̀.
15 Wọ́n ní kí ó jókòó, kí ó kà á fún àwọn, Baruku bá kà á fún wọn.
16 Nígbà tí wọ́n gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ náà, ẹ̀rù bà wọ́n, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wo ara wọn lójú. Wọ́n bá sọ fún Baruku pé, “A gbọdọ̀ sọ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí fún ọba.”
17 Wọ́n bi Baruku pé, “Sọ fún wa, báwo ni o ṣe kọ gbogbo ọ̀rọ̀ wọnyi sílẹ̀? Ṣé Jeremaya ni ó sọ ọ́, tí ìwọ fi ń kọ ọ́ ni, àbí báwo?”
18 Baruku bá dá wọn lóhùn pé, Jeremaya ni ó sọ gbogbo ọ̀rọ̀ náà fún òun ni òun fi kọ ọ́ sinu ìwé.
19 Àwọn ìjòyè bá sọ fún Baruku pé kí òun ati Jeremaya lọ sápamọ́, kí wọn má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni mọ ibi tí wọ́n wà.
20 Àwọn ìjòyè bá fi ìwé náà pamọ́ sinu yàrá Eliṣama akọ̀wé, lẹ́yìn náà wọ́n lọ sí ọ̀dọ̀ ọba ní gbọ̀ngàn, wọ́n sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ náà fún un.
21 Ọba bá rán Jehudi pé kí ó lọ mú ìwé náà wá, ó sì mú un wá láti inú yàrá Eliṣama, akọ̀wé. Jehudi bá kà á fún ọba ati gbogbo àwọn ìjòyè tí wọn dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀.
22 Ninu oṣù kẹsan-an ni ọ̀rọ̀ yìí ṣẹlẹ̀, ọba sì wà ní ilé tíí máa gbé ní àkókò òtútù, iná kan sì wà níwájú rẹ̀ tí ń jó ninu agbada.
23 Bí Jehudi bá ti ka òpó mẹta tabi mẹrin ninu ìwé náà, ọba yóo fi ọ̀bẹ gé e kúrò, yóo sì jù ú sinu iná tí ń jó níwájú rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe títí ó fi fi ìwé náà jóná tán.
24 Sibẹ ẹ̀rù kò ba ọba tabi àwọn iranṣẹ rẹ̀ tí wọ́n gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí, wọn kò sì fa aṣọ wọn ya.
25 Elinatani, Dilaaya ati Gemaraya tilẹ̀ bẹ ọba pé kí ó má fi ìwé náà jóná, ṣugbọn kò gbà.
26 Ọba bá pàṣẹ fún Jerameeli ọmọ rẹ̀, ati Seraaya ọmọ Asirieli, ati Ṣelemaya ọmọ Abideeli, pé kí wọn lọ mú Baruku akọ̀wé, ati Jeremaya wolii wá, ṣugbọn OLUWA fi wọ́n pamọ́.
27 Lẹ́yìn tí ọba ti fi ìwé náà jóná, ati gbogbo ohun tí Jeremaya ní kí Baruku kọ sinu rẹ̀, OLUWA sọ fún Jeremaya pé,
28 “Mú ìwé mìíràn kí o tún kọ gbogbo ohun tí ó wà ninu ìwé ti àkọ́kọ́, tí Jehoiakimu, ọba Juda fi jóná sinu rẹ̀.
29 Ohun tí o óo kọ nípa Jehoiakimu ọba Juda, nìyí: sọ pé èmi OLUWA ní, ṣé ó fi ìwé ti àkọ́kọ́ jóná ni, ó ní, kí ló dé tí a fi kọ sinu rẹ̀ pé dájúdájú, ọba Babiloni ń bọ̀ wá pa ilẹ̀ yìí run ati pé, yóo pa ati eniyan ati ẹranko tí ó wà ninu rẹ̀ run?
30 Nítorí náà, ohun tí èmi OLUWA níí sọ nípa rẹ̀ ni pé, ẹyọ ọmọ rẹ̀ kan kò ní jọba lórí ìtẹ́ Dafidi. Ìta ni a óo gbé òkú rẹ̀ jù sí, oòrùn yóo máa pa á lọ́sàn-án, ìrì yóo sì máa sẹ̀ sí i lórí lóru.
31 N óo jẹ òun, ati àwọn ọmọ rẹ̀, ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ níyà, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. N óo mú kí gbogbo ibi tí mo pinnu lórí wọn ṣẹ sí wọn lára ati sí ara àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu ati àwọn ará Juda, nítorí pé wọn kò gbọ́ràn.”
32 Jeremaya bá fún Baruku akọ̀wé, ọmọ Neraya, ní ìwé mìíràn, Baruku sì kọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí Jeremaya sọ fún un sinu rẹ̀. Ó kọ ohun tí ó wà ninu ìwé àkọ́kọ́ tí Jehoiakimu ọba Juda fi jóná, ó sì fi àwọn nǹkan mìíràn kún un pẹlu.