1 Ẹni ọdún mọkanlelogun ni Sedekaya nígbà tí ó jọba, ọdún mọkanla ni ó sì fi wà lórí oyè ní Jerusalẹmu. Hamutali, ọmọ Jeremaya ará Libina ni ìyá rẹ̀.
2 Sedekaya ṣe nǹkan burúkú lójú OLUWA, bí Jehoiakimu ti ṣe.
3 Nǹkan tí ń ṣẹlẹ̀ ní Jerusalẹmu ati Juda burú débi pé inú fi bí OLUWA sí wọn tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi tì wọ́n jáde kúrò níwájú rẹ̀.Sedekaya ṣọ̀tẹ̀ sí ọba Babiloni.
4 Ní ọjọ́ kẹwaa oṣù kẹwaa, ní ọdún kẹsan-an tí Sedekaya gorí oyè, Nebukadinesari, ọba Babiloni, dé sí Jerusalẹmu pẹlu gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀. Wọ́n dó tì í, wọ́n sì mọ òkítì sí ara odi rẹ̀ yíká.
5 Wọ́n dóti ìlú náà títí di ọdún kọkanla ìjọba Sedekaya.
6 Ní ọjọ́ kẹsan-an oṣù kẹrin, ìyàn mú ní ààrin ìlú tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn ará ìlú kò fi rí oúnjẹ jẹ mọ́.
7 Wọ́n lu odi ìlú, àwọn ọmọ ogun sì gba ibẹ̀ sá jáde lóru. Wọ́n gba ẹnu ọ̀nà tí ó wà láàrin àwọn odi meji tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọgbà ọba, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ará Kalidea yí ìlú náà po, wọ́n bá dorí kọ apá ọ̀nà àfonífojì odò Jọdani.
8 Ṣugbọn àwọn ọmọ ogun Kalidea lépa ọba Sedekaya, wọ́n sì bá a ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jẹriko; gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ bá fọ́nká lẹ́yìn rẹ̀.
9 Ọwọ́ àwọn ọmọ ogun Kalidea tẹ Sedekaya ọba, wọ́n sì mú un lọ sọ́dọ̀ ọba Babiloni ní Ribila, ní ilẹ̀ Hamati, ọba Babiloni sì ṣe ìdájọ́ fún un.
10 Ọba Babiloni pa àwọn ọmọ Sedekaya lójú rẹ̀, ó sì pa àwọn ìjòyè Juda ní Ribila.
11 Ó yọ ojú Sedekaya mejeeji, ó fi ẹ̀wọ̀n dè é, ó mú un lọ sí Babiloni, ó sì jù ú sí ọgbà ẹ̀wọ̀n, títí tí ó fi kú.
12 Ní ọjọ́ kẹwaa oṣù karun-un, ní ọdún kọkandinlogun tí Nebukadinesari ọba Babiloni jọba, Nebusaradani, olórí àwọn tí ń ṣọ́ ọba Babiloni, wọ ìlú Jerusalẹmu.
13 Ó sun ilé OLUWA níná ati ilé ọba ati gbogbo ilé tí ó wà ní Jerusalẹmu; gbogbo àwọn ilé ńláńlá ní ó dáná sun.
14 Gbogbo àwọn ọmọ ogun Kalidea tí wọ́n wà pẹlu olórí àwọn tí ń ṣọ́ Nebukadinesari ọba wó gbogbo odi Jerusalẹmu lulẹ̀ patapata.
15 Nebusaradani, olórí àwọn olùṣọ́ ọba bá kó ninu àwọn talaka lẹ́rú pẹlu àwọn eniyan tí wọ́n kù ní ìlú, ati àwọn tí wọ́n ti sálọ sọ́dọ̀ ọba Babiloni, ati àwọn oníṣẹ́-ọwọ́.
16 Ṣugbọn ó ṣẹ́ àwọn díẹ̀ kù sílẹ̀ ninu àwọn talaka pé kí wọn máa ṣe ìtọ́jú ọgbà àjàrà kí wọn sì máa dá oko.
17 Àwọn ọmọ ogun Kalidea fọ́ àwọn òpó bàbà tí ó wà ninu ilé OLUWA ati agbada omi tí ó wà níbẹ̀ pẹlu ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀. Gbogbo rẹ̀ ni wọ́n fọ́ tí wọn rún wómúwómú; wọ́n sì kó gbogbo bàbà tí ó wà ninu ilé OLUWA lọ sí Babiloni.
18 Bákan náà ni wọ́n kó àwọn ìkòkò, ọkọ́, ati àwọn ọ̀pá tí wọn fi ń pa iná ẹnu àtùpà; àwọn àwokòtò, àwọn àwo turari, ati gbogbo àwọn ohun-èlò tí wọ́n fi bàbà ṣe, tí wọn ń lò fún ìsìn ninu ilé OLUWA.
19 Wọ́n sì kó àwọn abọ́ kéékèèké, àwọn àwo ìfọnná, ati àwọn àwokòtò; àwọn ìkòkò, àwọn ọ̀pá fìtílà, ati àwọn àwo turari, ati àwọn abọ́ tí wọ́n fi ń ta ohun mímu sílẹ̀. Gbogbo nǹkan èlò tí wọ́n fi wúrà ati fadaka ṣe ni Nebusaradani, olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ọba Babiloni kó lọ.
20 Bàbà tí Solomoni fi ṣe òpó mejeeji ati agbada omi, pẹlu àwọn mààlúù idẹ mejeejila tí wọ́n gbé agbada náà dúró, ati àwọn ìtẹ́lẹ̀ tí Solomoni ọba ṣe fún ilé OLUWA kọjá wíwọ̀n.
21 Ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn òpó náà ga ní igbọnwọ mejidinlogun, àyíká wọn jẹ́ igbọnwọ mejila, wọ́n nípọn, ní ìka mẹrin, wọ́n sì ní ihò ninu.
22 Ọpọ́n idẹ orí rẹ̀ ga ní igbọnwọ marun-un, wọ́n ṣe ẹ̀wọ̀n bí ẹ̀gbà ọrùn ati èso Pomegiranate yí ọpọ́n náà ká.
23 Òpó keji rí bákan náà pẹlu èso Pomegiranate. Mẹrindinlọgọrun-un ni àwọn èso Pomegiranate tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ kọ̀ọ̀kan; ọgọrun-un ni gbogbo èso Pomegiranate tí ó wà ní àyíká ẹ̀wọ̀n náà.
24 Olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ọba Babiloni mú Seraaya, olórí alufaa ati Sefanaya tí ó jẹ́ igbákejì rẹ̀ ati àwọn aṣọ́nà mẹtẹẹta.
25 Ó sì mú ọ̀gágun tí ń ṣe àkóso àwọn ọmọ ogun, ati meje ninu àwọn aṣojú ọba tí wọn rí láàrin ìlú ati akọ̀wé olórí ogun tí ń kọ orúkọ àwọn eniyan sílẹ̀ fún ogun jíjà. Wọ́n tún kó ọgọta eniyan ninu àwọn ará ìlú tí wọn rí láàrin ìgboro.
26 Nebusaradani olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ọba, kó wọn lọ sọ́dọ̀ ọba Babiloni ní Ribila.
27 Ọba Babiloni sì pa wọ́n ní Ribila ní ilẹ̀ Hamati.Bẹ́ẹ̀ ni a ṣe kó àwọn eniyan Juda ní ìgbèkùn kúrò ní ilẹ̀ wọn.
28 Iye àwọn eniyan tí Nebukadinesari kó lọ sí ìgbèkùn nìwọ̀nyí ní ọdún keje tí ó jọba, ó kó ẹgbẹẹdogun ó lé mẹtalelogun (3,023) lára àwọn Juu.
29 Ní ọdún kejidinlogun, ó kó àwọn ẹgbẹrin ó lé mejilelọgbọn (832) eniyan ní Jerusalẹmu.
30 Ní ọdún kẹtalelogun tí Nebukadinesari jọba, Nebusaradani, olórí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ọba, kó ojilelẹẹdẹgbẹrin ó lé marun-un (745) eniyan lára àwọn Juu. Gbogbo àwọn eniyan tí wọn kó lẹ́rú jẹ́ ẹgbaaji lé ẹgbẹta (4,600).
31 Ní ọdún kẹtadinlogoji lẹ́yìn tí a ti mú Jehoiakini, ọba Juda lọ sí ìgbèkùn, ní ọjọ́ kẹẹdọgbọn oṣù kejila ọdún náà Efilimerodaki, ọba Babiloni yẹ ọ̀rọ̀ Jehoiakini wò ní ọdún tí ó gorí oyè, ó sì pàṣẹ pé kí á tú u sílẹ̀ kúrò ní àtìmọ́lé.
32 Ó bá a sọ ọ̀rọ̀ rere, ó sì fi sí ipò tí ó ga jùlọ, àní ipò tí ó ga ju ti gbogbo àwọn ọba tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ ní Babiloni lọ.
33 Jehoiakini bọ́ aṣọ ẹ̀wọ̀n kúrò lọ́rùn, ó sì ń bá ọba jẹun lórí tabili ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.
34 Ọba Babiloni sì rí i pé òun ń pèsè gbogbo ohun tí ó nílò lojoojumọ fún un títí di ọjọ́ ikú rẹ̀.