Jeremaya 17 BM

Ẹ̀ṣẹ̀ ati Ìjìyà Juda

1 OLUWA ní, “Gègé irin ni a fi kọ ẹ̀ṣẹ̀ Juda sílẹ̀ gègé òkúta dayamọndi ni a sì fi kọ ọ́ sí ọkàn yín, ati sí ara ìwo ara pẹpẹ wọn,

2 níwọ̀n ìgbà tí àwọn ọmọ yín bá ń ranti àwọn pẹpẹ yín, ati àwọn oriṣa Aṣera yín, tí ẹ rì mọ́ ẹ̀gbẹ́ gbogbo igi tútù, ati lórí àwọn òkè gíga;

3 ati lórí àwọn òkè ninu pápá. N óo sọ gbogbo ọrọ̀ yín ati gbogbo ohun ìṣúra yín di ìkógun fún àwọn ọ̀tá yín; n óo fi gbẹ̀san ẹ̀ṣẹ̀ yín ní gbogbo ilẹ̀ yín.

4 Ìwà yín yóo mú kí ilẹ̀ tí mo fun yín bọ́ lọ́wọ́ yín; n óo sí sọ yín di ẹrú àwọn ọ̀tá yín ní ilẹ̀ tí ẹ kò mọ̀rí. Ẹ ti mú kí ibinu mi máa jó bí iná, kò sì ní kú títí lae.”

Oríṣìíríṣìí Ọ̀rọ̀

5 OLUWA ní,“Ègún ni fún ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé eniyan,tí ó fi ẹlẹ́ran ara ṣe agbára rẹ̀;tí ọkàn rẹ̀ yipada kúrò lọ́dọ̀ èmi OLUWA.

6 Ó dàbí igbó ṣúúrú ninu aṣálẹ̀,nǹkan rere kan kò lè ṣẹlẹ̀ sí i.Ninu ilẹ̀ gbígbẹ, ninu aṣálẹ̀ ni ó wà,ninu ilẹ̀ iyọ̀ tí ẹnikẹ́ni kò lè gbé.

7 “Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé OLUWA,tí ó fi OLUWA ṣe àgbẹ́kẹ̀lé rẹ̀.

8 Yóo dàbí igi tí a gbìn sí ipa odò,tí ó ta gbòǹgbò kan ẹ̀bá odò.Ẹ̀rù kò ní bà á nígbà tí ẹ̀ẹ̀rùn bá dé,nítorí pé ewé rẹ̀ yóo máa tutù minimini.Kò ní páyà lákòókò ọ̀gbẹlẹ̀,nígbà gbogbo ni yóo sì máa so.

9 “Ọkàn eniyan kún fún ẹ̀tàn ju ohun gbogbo lọ,ìwà ìbàjẹ́ sì kún inú rẹ̀;ta ni ó lè mọ èrò ọkàn eniyan?

10 Èmi OLUWA ni èmi máa ń wádìí èrò eniyan,tí èmi sì máa ń yẹ ọkàn eniyan wò,láti san án fún olukuluku gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀,ati gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

11 Bí àparò tíí pa ẹyin ẹlẹ́yinbẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó fi èrú kó ọrọ̀ jọ.Ọrọ̀ yóo lọ mọ́ ọn lọ́wọ́ lọ́sàn-án gangan,nígbẹ̀yìn yóo di òmùgọ̀.

12 Ìtẹ́ ògo tí a tẹ́ sí ibi gíga láti ìbẹ̀rẹ̀ ni ibi mímọ́ wa.

13 OLUWA, ìwọ ni Israẹli gbójú lé,ojú yóo ti gbogbo àwọn tí wọ́n kọ̀ ọ́ sílẹ̀.A óo kọ orúkọ àwọn tí wọ́n kọ̀ ọ́ sílẹ̀ sórí ilẹ̀,yóo sì parẹ́,nítorí pé wọ́n ti kọ OLUWA, orísun omi ìyè, sílẹ̀.

Jeremaya Bèèrè fún Ìrànlọ́wọ́ OLUWA

14 Wò mí sàn, OLUWA, ara mi yóo sì dá,gbà mí, n óo sì bọ́ ninu ewu.Nítorí pé ìwọ ni mò ń yìn.

15 Wò ó! Wọ́n ń bi mí pé,“Níbo ni gbogbo ìhàlẹ̀ OLUWA já sí?Jẹ́ kí ó ṣẹ, kí á rí i!”

16 N kò bẹ̀bẹ̀ pé kí o rán ibi sí wọn,bẹ́ẹ̀ ni n kò fẹ́ ọjọ́ ibi fún wọn.OLUWA, o mọ̀ bẹ́ẹ̀.Ọ̀rọ̀ tí ó ti ẹnu mi jáde kò tún lè ṣàjèjì sí ọ.

17 Má di ohun ẹ̀rù fún mi,nítorí ìwọ ni ibi ààbò mi ní ọjọ́ ibi.

18 Jẹ́ kí ojú ó ti àwọn tí wọn ń ṣe inúnibíni mi,ṣugbọn kí ojú má tì mí.Jẹ́ kí ìpayà bá wọn,ṣugbọn má jẹ́ kí èmi páyà.Mú ọjọ́ ibi dé bá wọn; pa wọ́n run ní àpatúnpa.

Pípa Ọjọ́ Ìsinmi Mọ́

19 OLUWA sọ fún mi pé, “Lọ dúró ní ẹnubodè Bẹnjamini níbí, tí àwọn ọba Juda máa ń gbà wọlé, tí wọn sìí gbà jáde; ati ní gbogbo ẹnubodè Jerusalẹmu,

20 kí o wí pé, ‘Ẹ gbọ́ bí OLUWA ti wí, ẹ̀yin ọba Juda, ati gbogbo ẹ̀yin ará Juda ati gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé Jerusalẹmu, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gba ẹnu ọ̀nà wọnyi wọlé.

21 OLUWA ní kí ẹ ṣọ́ra fún ẹ̀mí yín, ẹ má máa ru ẹrù ní ọjọ́ ìsinmi, ẹ má gbé ẹrù wọ ẹnubodè Jerusalẹmu ní ọjọ́ ìsinmi mọ́.

22 Ẹ kò gbọdọ̀ ru ẹrù jáde ní ilé yín ní ọjọ́ ìsinmi. Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan, ẹ níláti ya ọjọ́ ìsinmi sí mímọ́, bí mo ti pa á láṣẹ fún àwọn baba ńlá yín.

23 Sibẹ àwọn baba yín kò gbọ́; wọn kò sì fetí sílẹ̀, wọ́n ṣe oríkunkun, kí wọn má baà gbọ́, kí wọn má baà gba ìtọ́ni.

24 Ṣugbọn bí ẹ̀yin bá fetí sí ọ̀rọ̀ mi, tí ẹ kò gbé ẹrù wọ inú ìlú yìí lọ́jọ́ ìsinmi, tí ẹ ya ọjọ́ ìsinmi sí mímọ́ láìṣe iṣẹ́ kankan lọ́jọ́ náà,

25 àwọn ọba tí yóo máa gúnwà lórí ìtẹ́ Dafidi, yóo máa gba ẹnubodè ìlú yìí wọlé. Àwọn ati àwọn ìjòyè wọn, ati àwọn ará Juda ati ará ìlú Jerusalẹmu yóo máa gun ẹṣin ati kẹ̀kẹ́ ogun wọlé. Àwọn eniyan yóo sì máa gbé ìlú yìí títí ayé.

26 Àwọn eniyan yóo máa wá láti gbogbo ìlú Juda ati àwọn agbègbè Jerusalẹmu, láti ilẹ̀ Bẹnjamini ati pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ṣefela, láti àwọn agbègbè olókè ati ilẹ̀ Nẹgẹbu, wọn yóo máa mú ẹbọ sísun ati ẹbọ ọrẹ wá, pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ ati turari; wọn yóo máa mú ẹbọ ọpẹ́ wá sí ilé OLUWA.

27 Ṣugbọn bí ẹ kò bá fetí sí ọ̀rọ̀ mi, tí ẹ kò ya ọjọ́ ìsinmi sí mímọ́, tí ẹ̀ ń ru ẹrù wọ inú Jerusalẹmu lọ́jọ́ ìsinmi, n óo ṣá iná sí ẹnubodè Jerusalẹmu, yóo jó àwọn ààfin rẹ̀, kò sì ní ṣe é pa.’ ”