1 OLUWA bá wolii Jeremaya sọ̀rọ̀ nípa Babiloni ní ilẹ̀ àwọn ará Kalidea pé:
2 “Kéde láàrin àwọn orílẹ̀-èdè,ta àsíá, kí o sì kéde.Má fi ohunkohun pamọ́; sọ pé,‘Ogun tí kó Babiloni,ojú ti oriṣa Bẹli,oriṣa Merodaki wà ninu ìdààmú.Ojú ti àwọn ère rẹ̀, ìdààmú sì bá wọn.’
3 “Nítorí pé orílẹ̀-èdè kan láti ìhà àríwá ti gbógun tì í,yóo sọ ilẹ̀ rẹ̀ di ahoro,kò sì ní sí ẹni tí yóo gbé inú rẹ̀ mọ́,ati eniyan ati ẹranko, wọn óo sá kúrò níbẹ̀.
4 “Nígbà tí àkókò bá tó, àwọn ọmọ Israẹli ati àwọn ọmọ Juda, yóo jọ wá pẹlu ẹkún, wọn yóo máa wá OLUWA Ọlọrun wọn.
5 Wọn yóo bèèrè ọ̀nà Sioni, wọn yóo kọjú sibẹ, wọn yóo sì wí pé: ‘Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á darapọ̀ mọ́ OLUWA, kí á sì bá a dá majẹmu ayérayé, tí a kò ní gbàgbé mọ́ títí ayé.’
6 “Àwọn eniyan mi dàbí aguntan tí ó sọnù, àwọn olùṣọ́ wọn ti ṣì wọ́n lọ́nà. Wọ́n ń lọ síhìn-ín, sọ́hùn-ún lórí òkè, wọ́n ń ti orí òkè kéékèèké bọ́ sí orí òkè ńláńlá; wọ́n ti gbàgbé ọ̀nà agbo wọn.
7 Gbogbo àwọn tí wọn rí wọn ń pa wọ́n jẹ, àwọn ọ̀tá wọn sì ń wí pé, ‘A kò ní ẹ̀bi kankan, nítorí pé wọ́n ti ṣẹ OLÚWA, tí ó jẹ́ ibùgbé òdodo wọn, ati ìrètí àwọn baba wọn.’
8 “Ẹ sá kúrò láàrin Babiloni, ẹ jáde kúrò ní ilẹ̀ àwọn ará Kalidea, bí òbúkọ tí ó ṣáájú agbo ẹran.
9 Nítorí n óo rú ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè sókè, láti ìhà àríwá, n óo sì kó wọn wá, wọn óo wá dóti Babiloni, wọn yóo gbógun tì í. Ibẹ̀ ni ọwọ́ wọn yóo ti tẹ̀ ẹ́, tí wọn óo sì fogun kó o. Ọfà wọn dàbí akọni ọmọ ogun, tí kì í pada sílé lọ́wọ́ òfo.
10 Ohun ìní àwọn ará Kalidea yóo di ìkógun; gbogbo àwọn tí wọn yóo kó wọn lẹ́rù ni yóo kó ẹrù ní àkótẹ́rùn, Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
11 OLUWA ní, “Ẹ̀yin ará Babiloni, tí ẹ kó àwọn eniyan mi,bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé inú yín dùn ẹ sì ń yọ̀,tí ẹ sì ń ṣe ojúkòkòrò, bí akọ mààlúù tí ń jẹko ninu pápá,tí ẹ sì ń yan bí akọ ẹṣin:
12 Ojú yóo ti olú-ìlú yín lọpọlọpọ,a óo dójú ti ilẹ̀ ìbí yín.Wò ó! Yóo di èrò ẹ̀yìn láàrin àwọn orílẹ̀-èdè,yóo di aṣálẹ̀ tí ó gbẹ.
13 Nítorí ibinu gbígbóná OLUWA,ẹnikẹ́ni kò ní gbé ibẹ̀ mọ́;yóo di ahoro patapata;ẹnu yóo ya gbogbo ẹni tí ó bá gba Babiloni kọjá,wọn yóo sì máa pòṣé nítorí ìyà tí a fi jẹ ẹ́.
14 “Ẹ gbógun ti Babiloni yíká, gbogbo ẹ̀yin tafàtafà. Ẹ máa ta á lọ́fà, ẹ má ṣẹ́ ọfà kankan kù, nítorí pé ó ti ṣẹ OLUWA.
15 Gbogbo ẹ̀yin tí ẹ yí i ká, ẹ hó bò ó, ó ti jọ̀wọ́ ara rẹ̀ sílẹ̀. Àwọn ibi ààbò rẹ̀ ti wó, àwọn odi rẹ̀ sì ti wó lulẹ̀. Nítorí ẹ̀san OLUWA ni, ẹ gbẹ̀san lára rẹ̀; ẹ ṣe sí i bí òun náà ti ṣe sí àwọn ẹlòmíràn.
16 Ẹ pa àwọn afunrugbin run ní Babiloni, ati àwọn tí ń lo dòjé ní ìgbà ìkórè. Olukuluku yóo pada sọ́dọ̀ àwọn eniyan rẹ̀, yóo sì sá pada sí ilẹ̀ rẹ̀, nítorí idà àwọn aninilára.”
17 OLUWA ní, “Israẹli dàbí aguntan tí àwọn kinniun ń lé kiri. Ọba Asiria ni ó kọ́kọ́ fi ṣe ẹran ìjẹ, ọba Babiloni sì ń wó àwọn egungun rẹ̀ tí ó kù.
18 Nítorí náà èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli, ni mo sọ pé n óo jẹ ọba Babiloni ati ilẹ̀ rẹ̀ níyà, bí mo ṣe jẹ ọba Asiria níyà.
19 N óo mú Israẹli pada sí ibùjẹ rẹ̀, yóo máa jẹ oúnjẹ tí ó bá hù lórí òkè Kamẹli ati ní agbègbè Baṣani, yóo sì tẹ́ ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ lọ́rùn lórí òkè Efuraimu ati òkè Gileadi.
20 OLUWA ní, Nígbà tí ó bá yá, tí àkókò bá tó, a óo wá ẹ̀ṣẹ̀ tì ní Israẹli ati Juda; nítorí pé n óo dáríjì àwọn tí mo bá ṣẹ́kù.”
21 OLUWA ní,“Ẹ gbógun ti ilẹ̀ Merataimu, ati àwọn ará Pekodi.Ẹ pa wọ́n, kí ẹ sì run wọ́n patapata.Gbogbo nǹkan tí mo pàṣẹ fun yín ni kí ẹ ṣe.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
22 A gbọ́ ariwo ogun ati ìparun ńlá, ní ilẹ̀ náà.
23 Ẹ wo bí a ti gé òòlù tó ti ń lu gbogbo ayé lulẹ̀,tí a sì fọ́ ọ!Ẹ wo bí Babiloni ti di ohun àríbẹ̀rù, láàrin àwọn orílẹ̀-èdè.
24 Mo dẹ tàkúté sílẹ̀ fun yín, ẹ̀yin ará Babiloni:Tàkúté náà mu yín, ẹ kò sì mọ̀.Wọ́n ri yín, ọwọ́ sì tẹ̀ yín,nítorí pé ẹ yájú sí èmi OLUWA.
25 Mo ti ṣí ìlẹ̀kùn ilé ìṣúra àwọn nǹkan ìjà yín,mo sì kó àwọn ohun ìjà ibinu yín jáde,nítorí èmi OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ní iṣẹ́ kan láti ṣe ní ilẹ̀ àwọn ará Kalidea.
26 Ẹ gbógun tì í ní gbogbo ọ̀nà,ẹ ṣí àká rẹ̀ sílẹ̀,ẹ kó o jọ bí òkítì ọkà,kí ẹ sì pa á run patapata,ẹ má dá ohunkohun sí ninu rẹ̀.
27 Ẹ pa gbogbo akọ mààlúù rẹ̀,ẹ fà wọ́n lọ sí ibi tí wọ́n ti ń pa ẹran.Àwọn ará Babiloni gbé, nítorí ọjọ́ wọn ti pé,àní ọjọ́ ìjìyà wọn.”
28 (Ẹ gbọ́ ariwo bí àwọn eniyan tí ń sá àsálà kúrò ní ilẹ̀ Babiloni, wá sí Sioni, láti wá ròyìn ìgbẹ̀san Ọlọrun wa, ẹ̀san tẹmpili rẹ̀ tí wọ́n wó lulẹ̀.)
29 “Ẹ pe àwọn tafàtafà jọ, kí wọn dojú kọ Babiloni; kí gbogbo àwọn tí wọn ń tafà pàgọ́ yí i ká, kí wọn má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni sá àsálà. Ẹ san án fún un gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, ẹ ṣe sí i bí ó ti ṣe sí àwọn ẹlòmíràn; nítorí pé ó ṣe àfojúdi sí OLUWA, Ẹni Mímọ́ Israẹli.
30 Nítorí náà àwọn ọdọmọkunrin rẹ̀, yóo kú ní gbàgede rẹ̀. Gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ ní a óo parun ní ọjọ́ náà. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
31 “Wò ó! Mo dojú kọ ọ́,ìwọ onigbeeraga yìí,nítorí pé ọjọ́ ti pé tí n óo jẹ ọ́ níyà.Èmi OLUWA, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
32 Agbéraga, o óo fẹsẹ̀ kọ, o óo sì ṣubú,kò ní sí ẹni tí yóo gbé ọ dìde.N óo dá iná kan ninu àwọn ìlú rẹ,iná náà yóo sì jó gbogbo àyíká rẹ.”
33 OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “À ń ni àwọn ọmọ Israẹli lára, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ọmọ Juda; gbogbo àwọn tí wọ́n kó wọn ní ìgbèkùn ni wọ́n wo ọwọ́ mọ́ wọn, wọn kò jẹ́ kí wọn lọ.
34 Ṣugbọn alágbára ni Olùràpadà wọn, OLUWA àwọn ọmọ ogun ni orúkọ rẹ̀. Dájúdájú, yóo jà fún wọn, kí ó lè fún ayé ní ìsinmi, ṣugbọn kí ìdààmú lè bá àwọn ará Babiloni.”
35 OLUWA ní,“Idà ni yóo pa àwọn ará Kalidea,idà ni yóo pa àwọn ará Babiloni,ati àwọn ìjòyè wọn,ati àwọn amòye wọn!
36 Idà ni yóo pa àwọn awoṣẹ́ wọn,kí wọ́n lè di òpè!Idà ni yóo pa àwọn ọmọ ogun wọn,kí wọ́n lè parẹ́!
37 Idà ni yóo pa àwọn ẹṣin wọn,ati àwọn kẹ̀kẹ́ ogun wọn,idà ni yóo pa gbogbo àwọn àjèjì ọmọ ogun tí wọ́n wà láàrin wọn,Kí wọ́n lè di obinrin!Idà ni yóo fọ́ àwọn ilé ìṣúra wọn,kí wọ́n lè di ìkógun!
38 Ọ̀dá yóo dá ní ilẹ̀ wọn,kí àwọn odò wọn lè gbẹ!Nítorí pé ilẹ̀ tí ó kún fún ère ni,wọ́n sì kúndùn ìbọ̀rìṣà.
39 “Nítorí náà àwọn ẹranko ìgbẹ́ ati ìkookò ni yóo máa gbé inú Babiloni, ẹyẹ ògòǹgò yóo máa gbé inú rẹ̀. Kò ní sí eniyan níbẹ̀, ẹnikẹ́ni kò ní gbé inú rẹ̀ mọ́ títí lae.
40 Yóo dàbí ìgbà tí Ọlọrun pa Sodomu ati Gomora run, pẹlu àwọn ìlú tí ó yí wọn ká; nítorí náà ẹnikẹ́ni kò ní gbé ibẹ̀ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni eniyan kò ní máa dé sibẹ.
41 “Wò ó! Àwọn kan ń bọ̀ láti ìhà àríwá, orílẹ̀-èdè ńlá, ati ọpọlọpọ ọba,wọ́n ń gbára wọn jọ láti máa bọ̀ láti òkèèrè.
42 Wọ́n kó ọrun ati ọ̀kọ̀ lọ́wọ́,ìkà ni wọ́n, wọn kò ní ojú àánú.Ìró wọn dàbí ìró rírú omi òkun;wọ́n gun ẹṣin,wọ́n tò bí àwọn ọmọ ogun.Wọ́n ń bọ̀ wá dojú kọ ọ́, ìwọ Babiloni!
43 Nígbà tí ọba Babiloni gbọ́ ìró wọn,ọwọ́ rẹ̀ rọ,ìrora sì mú un bíi ti obinrin tí ń rọbí.
44 “Wò ó! Bí kinniun tíí yọ ní aginjù odò Jọdani tíí kọlu agbo aguntan, bẹ́ẹ̀ ni n óo yọ sí àwọn ará Babiloni, n óo mú kí wọn sá kúrò lórí ilẹ̀ wọn lójijì; n óo sì yan ẹnikẹ́ni tí ó bá wù mí láti máa ṣe àkóso ibẹ̀. Nítorí ta ló dàbí mi? Ta ló lè yẹ̀ mí lọ́wọ́ wò? Olùṣọ́-aguntan wo ló lè dúró dè mí?
45 Nítorí náà, ẹ gbọ́ ète tí èmi OLUWA pa lórí Babiloni, ati èrò mi lórí àwọn ará Kalidea: A óo kó agbo ẹran wọn lọ tọmọtọmọ; ibùjẹ ẹran wọn yóo sì parun nítorí tiwọn.
46 Ariwo wíwó odi Babiloni yóo mi ilẹ̀ tìtì, a óo sì gbọ́ ìró rẹ̀ káàkiri àwọn orílẹ̀-èdè.”