Jeremaya 11 BM

Jeremaya ati Majẹmu

1 OLUWA bá èmi Jeremaya sọ̀rọ̀,

2 ó ní, “Gbọ́ ọ̀rọ̀ majẹmu yìí, kí o sì sọ ọ́ fún àwọn ọmọ Juda, ati àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu.

3 Sọ fún wọn pé OLUWA Ọlọrun Israẹli ní, ‘Ẹnikẹ́ni tí kò bá gba ọ̀rọ̀ majẹmu

4 tí mo pa láṣẹ fún àwọn baba ńlá yín, gbé! Majẹmu tí mo bá wọn dá ní ọjọ́ tí mo kó wọn kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, ilẹ̀ tí ó gbóná bí iná tí alágbẹ̀dẹ fi ń yọ́ irin.’ Mo sọ fún wọn nígbà náà, mo ní, ‘Ẹ máa fetí sí ohùn mi, kí ẹ sì máa ṣe gbogbo nǹkan tí mo pa láṣẹ fun yín. Òun ni ẹ óo fi jẹ́ eniyan mi, tí èmi náà óo sì fi jẹ́ Ọlọrun yín.

5 Bí ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, n óo mú ẹ̀jẹ́ tí mo jẹ́ fún àwọn baba ńlá yín ṣẹ, pé n óo fún wọn ní ilẹ̀ tí ó kún fún wàrà ati oyin,’ bí ó ti rí ní òní.”Mo bá dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, OLUWA.”

6 OLUWA tún sọ fún mi pé, “Kéde gbogbo ọ̀rọ̀ yìí ní àwọn ìlú Juda ati ní àwọn òpópó Jerusalẹmu, pé kí wọn fetí sí ọ̀rọ̀ majẹmu yìí, kí wọ́n sì ṣe bí ó ti wí.

7 Mo kìlọ̀ fún àwọn baba ńlá yín ní ọjọ́ tí mo kó wọn kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, títí tí ó sì fi di òní, n kò yé kìlọ̀ fún wọn pé kí wọ́n fetí sí ohùn èmi OLUWA.

8 Sibẹsibẹ wọn kò gbọ́; wọn kò sì fetí sí ọ̀rọ̀ mi. Kàkà bẹ́ẹ̀, olukuluku ń ṣe ohun tí ó wà ní ọkàn burúkú rẹ̀. Nítorí náà ni mo ṣe mú kí gbogbo ọ̀rọ̀ majẹmu yìí ṣẹ mọ́ wọn lára, bí mo ti pa á láṣẹ fún wọn pé kí wọn ṣe, ṣugbọn tí wọn kò ṣe.”

9 OLUWA tún wí fún mi pé, “Àwọn ọmọ Juda ati àwọn tí wọn ń gbé Jerusalẹmu ń dìtẹ̀.

10 Wọ́n ti pada sí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba ńlá wọn, tí wọ́n kọ̀, tí wọn kò gbọ́ ọ̀rọ̀ mi. Wọ́n ti bá àwọn ọlọrun mìíràn lọ, wọ́n sì ń sìn wọ́n. Àwọn ọmọ Israẹli ati àwọn ọmọ Juda ti da majẹmu tí mo bá àwọn baba ńlá wọn dá.

11 Nítorí náà, OLUWA ní, òun óo mú kí ibi ó dé bá wọn, ibi tí wọn kò ní lè bọ́ ninu rẹ̀. Ó ní bí wọ́n tilẹ̀ ké pe òun, òun kò ní fetí sí tiwọn.

12 Ó ní àwọn ìlú Juda ati àwọn tí wọn ń gbé Jerusalẹmu yóo ké pe àwọn oriṣa tí wọn ń sun turari sí, ṣugbọn àwọn oriṣa kò ní lè gbà wọ́n lọ́jọ́ ìṣòro.

13 Bí àwọn ìlú ti pọ̀ tó ní ilẹ̀ Juda bẹ́ẹ̀ ni àwọn oriṣa ibẹ̀ pọ̀ tó. Bákan náà, Jerusalẹmu, bí òpópó ṣe pọ̀ tó ní Jerusalẹmu, bẹ́ẹ̀ náà ni pẹpẹ tí wọ́n fi ń sun turari sí Baali, tí ó jẹ́ ohun ìtìjú, ṣe pọ̀ tó ninu rẹ̀.

14 “Nítorí náà, má ṣe gbadura fún àwọn eniyan wọnyi. Má sọkún nítorí wọn, má sì bẹ̀bẹ̀ fún wọn, nítorí n kò ní gbọ́, nígbà tí wọn bá ké pè mí nígbà ìṣòro wọn.

15 “Ẹ̀tọ́ wo ni olólùfẹ́ mi níláti wà ninu ilé mi lẹ́yìn tí ó ti ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ inú rẹ̀? Ṣé ọpọlọpọ ẹ̀jẹ́ ati ẹran tí a fi rúbọ lè mú kí ibi rékọjá rẹ̀? Ṣé ó lè máa yọ̀ nígbà náà?

16 Nígbà kan rí, OLUWA pè ọ́ ní igi olifi eléwé tútù, tí èso rẹ̀ dára; ṣugbọn pẹlu ìró ìjì ńlá, yóo dáná sun ún, gbogbo ẹ̀ka rẹ̀ yóo sì jóná.

17 OLUWA àwọn ọmọ ogun tí ó gbìn ọ́, ti ṣe ìdájọ́ ibi fún ọ, nítorí iṣẹ́ ibi tí ẹ ṣe, ẹ̀yin ilé Israẹli ati ilé Juda; ẹ mú mi bínú nítorí pé ẹ sun turari sí oriṣa Baali.”

Ète láti Pa Jeremaya

18 OLUWA fi iṣẹ́ ibi wọn hàn mí, ó sì yé mi.

19 Ṣugbọn mo dàbí ọ̀dọ́ aguntan tí wọn ń fà lọ sọ́dọ̀ alápatà. N kò mọ̀ pé nítorí mi ni wọ́n ṣe ń gbèrò ibi, tí wọn ń wí pé, “Ẹ jẹ́ kí á gé igi náà lulẹ̀ pẹlu èso rẹ̀, kí á gé e kúrò ní ilẹ̀ alààyè, kí á má sì ranti orúkọ rẹ̀ mọ́.”

20 Ṣugbọn onídàájọ́ òdodo ni ọ́, OLUWA àwọn ọmọ ogun, ẹni tí ó ń dán ọkàn ati èrò eniyan wò, jẹ́ kí n rí i bí o óo ṣe máa gbẹ̀san lára wọn; nítorí pé ìwọ ni mo fi ọ̀rọ̀ mi lé lọ́wọ́.

21 Nítorí náà, OLUWA sọ nípa àwọn ará Anatoti, tí wọn ń wá ẹ̀mí Jeremaya, tí wọn sì ń sọ fún un pé, “O kò gbọdọ̀ sọ àsọtẹ́lẹ̀ mọ́ ní orúkọ OLUWA. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, àwa ni a óo pa ọ́.”

22 Nítorí náà, OLUWA àwọn ọmọ ogun ní òun óo jẹ wọ́n níyà; àwọn ọdọmọkunrin wọn yóo kú lójú ogun, ìyàn ni yóo sì pa àwọn ọmọkunrin ati ọmọbinrin wọn.

23 Kò ní sí ẹni tí yóo ṣẹ́kù nítorí pé òun óo mú kí ibi dé bá àwọn ará Anatoti, nígbà tí àkókò bá tó tí òun óo jẹ wọ́n níyà.