1 Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ tí OLUWA ń ba yín sọ, ẹ̀yin ọmọ Israẹli:
2 OLUWA ní,“Ẹ má kọ́ àṣà àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn,ẹ má sì páyà nítorí àwọn àmì ojú ọ̀run,bí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn tilẹ̀ ń páyà nítorí wọn,
3 nítorí pé irọ́ ló wà nídìí àwọn àṣà wọn.Wọn á gé igi ninu igbó,agbẹ́gilére á fi àáké gbẹ́ ẹ.
4 Wọn á fi fadaka ati wúrà ṣe é lọ́ṣọ̀ọ́,wọn á sì fi ìṣó kàn án mọ́lẹ̀,kí ó má baà wó lulẹ̀.
5 Ère wọn dàbí aṣọ́komásùn ninu oko ẹ̀gúsí,wọn kò lè sọ̀rọ̀,gbígbé ni wọ́n máa ń gbé wọnnítorí pé wọn kò lè dá rìn.Ẹ má bẹ̀rù wọnnítorí pé wọn kò lè ṣe ẹnikẹ́ni ní ibi kankan,bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì lè ṣe rere.”
6 OLUWA, kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ, o tóbi lọ́ba,agbára orúkọ rẹ sì pọ̀.
7 Ta ni kò ní bẹ̀rù rẹ, ìwọ ọba àwọn orílẹ̀-èdè?Nítorí ẹ̀tọ́ rẹ ni;kò sì sí ẹni tí ó gbọ́n tó ọláàrin àwọn ọlọ́gbọ́n tí wọ́n wà ní àwọn orílẹ̀-èdè,ati ni gbogbo ìjọba wọn.
8 Aláìmọ̀kan ati òmùgọ̀ ni gbogbo wọn,ère kò lè kọ́ eniyan lọ́gbọ́n,nítorí igi lásán ni.
9 Wọ́n kó fadaka pẹlẹbẹ wá láti ìlú Taṣiṣi,ati wúrà láti ìlú Ufasi.Iṣẹ́ ọwọ́ agbẹ́gilére ni wọ́n,ati ti àwọn alágbẹ̀dẹ wúrà.Aṣọ wọn jẹ́ aláwọ̀ pupaati ti elése àlùkò,iṣẹ́ ọwọ́ àwọn oníṣọ̀nà ni gbogbo wọn.
10 Ṣugbọn OLUWA ni Ọlọrun tòótọ́,òun ni Ọlọrun alààyè, Ọba ayérayé.Tí inú rẹ̀ bá bẹ̀rẹ̀ síí ru ayé á mì tìtì,àwọn orílẹ̀-èdè kò lè farada ibinu rẹ̀.
11 Wí fún wọn pé àwọn ọlọrun tí kì í ṣe àwọn ni wọ́n dá ọ̀run ati ayé yóo parun láyé ati lábẹ́ ọ̀run.
12 Òun ni ó fi agbára rẹ̀ dá ayé,tí ó fi ọgbọ́n fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀,tí ó sì fi òye rẹ̀ ta ojú ọ̀run bí aṣọ.
13 Bí ó bá fọhùn, omi á máa rọ́kẹ̀kẹ̀ lójú ọ̀run,ó mú kí ìkùukùu gbéra láti òpin ayé,òun ni ó dá mànàmáná fún òjò,tí ó sì mú afẹ́fẹ́ wá láti ilé ìṣúra rẹ̀.
14 Òmùgọ̀ ni gbogbo eniyan jẹ́, wọn kò sì ní ìmọ̀;gbogbo àwọn alágbẹ̀dẹ wúrà ni àwọn oriṣa wọn dójútì,nítorí pé irọ́ ló wà nídìí àwọn ère wọn;kò sí èémí ninu wọn.
15 Asán ni wọ́n, ohun ìṣìnà sì ni wọ́n;ní àkókò ìjẹníyà wọn, wọn yóo parun ni.
16 Ìpín Jakọbu kò rí bí àwọn wọnyi,nítorí òun ló dá ohun gbogbo,Israẹli sì ni ẹ̀yà tí ó yàn, gẹ́gẹ́ bí ìní rẹ̀;OLUWA àwọn ọmọ ogun ni orúkọ rẹ̀.
17 Ẹ gbé ẹrù yín nílẹ̀,ẹ̀yin tí ọ̀tá dótì wọnyi!
18 Nítorí OLUWA wí pé,“Mo ṣetán wàyí, tí n óo sọ àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ yìí nù bí òkò.N óo mú kí ìpọ́njú dé bá wọn,kí wọ́n lè mọ̀ pé nǹkan ṣe àwọn.”
19 Mo gbé, nítorí mo fara gbọgbẹ́!Ọgbẹ́ náà sì pọ̀.Ṣugbọn mo sọ fún ara mi pé,“Ìyà gan-an ni èyí jẹ́ fún mi,mo sì gbọdọ̀ fara dà á.”
20 Àgọ́ mi ti wó, gbogbo okùn rẹ̀ sì ti já.Àwọn ọmọ mi ti fi mí sílẹ̀, wọn kò sì sí mọ́.Kò sí ẹni tí yóo máa bá mi pa àgọ́ mọ́,bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí yóo máa bá mi ta aṣọ àgọ́ mi.
21 Nítorí pé òmùgọ̀ ni àwọn olùṣọ́-aguntan,wọn kò sì ṣe ìwádìí lọ́dọ̀ OLUWA,nítorí náà wọn kò ṣe àṣeyọrí,tí gbogbo agbo wọn sì fi túká.
22 Ẹ gbọ́ àhesọ ọ̀rọ̀ kan! Ó ń tàn kálẹ̀!Ìdàrúdàpọ̀ ńlá ń bọ̀ láti ilẹ̀ àríwá,tí yóo sọ àwọn ìlú Juda di ahoroyóo sì di ibùgbé àwọn ajáko.
23 OLUWA, mo mọ̀ pé ọ̀nà ẹ̀dá kò sí ní ọwọ́ ara rẹ̀.Kò sí ní ìkáwọ́ ẹni tí ń rìn láti tọ́ ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.
24 Tọ́ mi sọ́nà, OLUWA,ṣugbọn lọ́nà ẹ̀tọ́ ni kí o bá mi wí,kì í ṣe pẹlu ibinu rẹ,kí o má baà sọ mí di ẹni ilẹ̀.
25 Àwọn orílẹ̀-èdè tí wọn kò mọ̀ ọ́,ni kí o bínú sí kí ó pọ̀,ati àwọn tí wọn kì í jọ́sìn ní orúkọ rẹ;nítorí pé wọ́n ti jẹ Jakọbu run,wọ́n jẹ ẹ́ ní àjẹrun patapata,wọ́n sì sọ ibùgbé rẹ̀ di ahoro.