Jeremaya 49 BM

Ìdájọ́ OLUWA Lórí Amoni

1 Ohun tí OLUWA sọ nípa àwọn ará Amoni nìyí: Ó ní,“Ṣé Israẹli kò lọ́mọ ni?Tabi kò ní àrólé?Kí ló dé tí àwọn tí ń bọ Milikomu ṣe gba ilẹ̀ ẹ̀yà Gadi,tí wọ́n sì fi àwọn ìlú Gadi ṣe ibùjókòó?

2 Nítorí náà, wò ó, àkókò ń bọ̀ tí n óo jẹ́ kí ariwo ogun sọ, ní Raba ìlú àwọn ọmọ Amoni;Raba yóo di òkítì àlàpà,a óo sì dáná sun àwọn ìgbèríko rẹ̀;Israẹli yóo wá pada fi ogun kó àwọn tí wọ́n kó o lẹ́rú.

3 Sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, ìwọ Heṣiboni,nítorí pé ìlú Ai ti parun!Ẹ sọkún, ẹ̀yin ọmọbinrin Raba!Ẹ ró aṣọ ọ̀fọ̀,ẹ máa sọkún, kí ẹ sì máa sá sókè sódò láàrin ọgbà!Nítorí pé oriṣa Moleki yóo lọ sí ìgbèkùn,pẹlu àwọn babalóòṣà rẹ̀ ati àwọn ìjòyè ní ibi ìsìn rẹ̀.

4 Kí ló dé tí ò ń fọ́nnu nípa agbára rẹ,ipá rẹ ti pin, ìwọ olóríkunkun ọmọbinrinìwọ tí o gbójú lé ọrọ̀ rẹ,tí ò ń wí pé, ‘Ta ló lè dojú kọ mí?’

5 Wò ó! N óo kó ìpayà bá ọ,láti ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn tí wọ́n yí ọ ká;èmi OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.Gbogbo yín ni yóo fọ́nká,tí olukuluku yóo sì yà sí ọ̀nà tirẹ̀,kò sì ní sí ẹni tí yóo kó àwọn tí ń sá fún ogun jọ.

6 “Ṣugbọn lẹ́yìn náà, n óo dá ire àwọn ará Amoni pada.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Ìdájọ́ OLUWA lórí Edomu

7 Ohun tí OLUWA àwọn ọmọ ogun sọ nípa Edomu nìyí: Ó ní,“Ṣé kò sí ọgbọ́n ní Temani mọ́ ni?Àbí àwọn amòye kò ní ìmọ̀ràn lẹ́nu mọ́?Ṣé ọgbọ́n ti rá mọ́ wọn ninu ni?

8 Ẹ̀yin ará Dedani, ẹ pada kíá, ẹ máa sálọ.Ẹ wọ inú ihò lọ, kí ẹ lọ máa gbébẹ̀!Nítorí pé ní ìgbà tí mo bá jẹ ìran Esau níyà, n óo mú kí ibi dé bá wọn.

9 Bí àwọn tí ń kórè èso àjàrà bá bẹ̀rẹ̀ sí kórè,ṣebí wọn a máa fi èso díẹ̀ díẹ̀ sílẹ̀?Bí àwọn olè bá wọlé lóru,ṣebí ìba ohun tí ó bá wù wọ́n ni wọn yóo kó?

10 Ṣugbọn mo ti tú àwọn ọmọ Esau sí ìhòòhò,Mo ti sọ ibi tí wọn ń sápamọ́ sí di gbangba,wọn kò sì rí ibi sápamọ́ sí mọ́.Àwọn ọmọ wọn ti parun,pẹlu àwọn arakunrin wọn ati àwọn aládùúgbò wọn;àwọn pàápàá sì ti di àwátì.

11 Fi àwọn ọmọ rẹ, aláìníbaba sílẹ̀,n óo pa wọ́n mọ́ láàyè,sì jẹ́ kí àwọn opó rẹ gbẹ́kẹ̀lé mi.

12 “Bí àwọn tí kò yẹ kí wọ́n jìyà bá jìyà, ṣé ìwọ wá lè lọ láìjìyà? O kò ní lọ láìjìyà, dájúdájú ìyà óo jẹ ọ́.

13 Nítorí pé mo ti fi ara mi búra, èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀, pé Bosira yóo di àríbẹ̀rù ati ohun ẹ̀gàn, ahoro ati ohun àmúgégùn-ún; àwọn ìlú rẹ̀ yóo sì di ahoro títí lae.”

14 Mo ti gbọ́ ìròyìn láti ọ̀dọ̀ OLUWA,wọ́n ti rán ikọ̀ kan sí àwọn orílẹ̀-èdè,wọ́n ní kí wọn kéde pé,“OLUWA ní, ‘Ẹ kó ara yín jọ, kí ẹ kọlu Edomu,ẹ dìde, kí ẹ gbógun tì í!

15 Nítorí pé n óo sọ ọ́ di kékeréláàrin àwọn orílẹ̀-èdè,o óo sì di yẹpẹrẹ,láàrin àwọn ọmọ eniyan.

16 Ẹ̀rù tí ó wà lára rẹ, ati ìgbéraga ọkàn rẹ ti tàn ọ́ jẹ,ìwọ tí ò ń gbé pàlàpálá àpáta,tí o fi góńgó orí òkè ṣe ibùgbé.Bí o tilẹ̀ kọ́ ìtẹ́ rẹ sí ibi gíga, bíi ti ẹyẹ idì,n óo fà ọ́ lulẹ̀ láti ibẹ̀.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.’ ”

17 OLUWA ní, “Edomu yóo sì di ibi àríbẹ̀rù, ẹ̀rù yóo máa ba gbogbo àwọn tí wọ́n bá gba ibẹ̀ kọjá, wọn yóo máa pòṣé nítorí ibi tí ó dé bá a.

18 Yóo rí fún un bí ó ti rí fún Sodomu ati Gomora ati àwọn ìlú agbègbè wọn tí ó parun. Ẹnikẹ́ni kò ní gbé ibẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò ní dé sibẹ. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

19 Wò ó, bí kinniun tií yọ ní aginjù odò Jọdani láti kọlu agbo aguntan, bẹ́ẹ̀ ni n óo yọ sí Edomu n óo sì mú kí ó sá kúrò lórí ilẹ̀ rẹ̀ lójijì. N óo sì yan ẹnikẹ́ni tí ó bá wù mí láti máa ṣe àkóso ibẹ̀; nítorí ta ló dàbí mi? Ta ló lè yẹ̀ mí lọ́wọ́ wò? Olùṣọ́-aguntan wo ló lè dúró dè mí?

20 Nítorí náà, ẹ gbọ́ ète tí OLUWA pa lórí Edomu, ati èrò rẹ̀ lórí àwọn tí wọn ń gbé Temani. A óo kó agbo ẹran wọn lọ tọmọtọmọ, ibùjẹ àwọn ẹran wọn yóo parun nítorí tiwọn.

21 Ariwo wíwó odi Edomu wọn yóo mi ilẹ̀ tìtì, a óo sì gbọ́ ìró rẹ̀ títí dé etí òkun pupa.

22 Wò ó! Ẹnìkan yóo fò bí ẹyẹ idì, yóo na ìyẹ́ rẹ̀ sórí Bosira, ní ọjọ́ náà ọkàn àwọn ọmọ ogun Edomu yóo dàbí ọkàn obinrin tí ń rọbí.”

Ìdájọ́ OLUWA lórí Damasku

23 Ohun tí OLUWA sọ nípa Damasku nìyí, Ó ní,“Ìdààmú dé bá Hamati ati Aripadi,nítorí pé wọ́n gbọ́ ìròyìn burúkú:Jìnnìjìnnì dà bò wọ́n, ọkàn wọn sì dàrú,bí omi òkun tí kò lè dákẹ́ jẹ́ẹ́.

24 Àárẹ̀ mú Damasku,ó pẹ̀yìndà pé kí ó máa sálọ,ṣugbọn ìpayà mú un,ìrora ati ìbànújẹ́ sì dé bá a, bí obinrin tí ń rọbí.

25 Ẹ wò ó bí ìlú olókìkí tí ó kún fún ayọ̀, ṣe di ibi ìkọ̀sílẹ̀!

26 Àwọn ọdọmọkunrin Damasku yóo ṣubú ní gbàgede rẹ̀ ní ọjọ́ náà,gbogbo àwọn ọmọ ogun ibẹ̀ yóo sì parun ni;Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

27 N óo dáná sun odi Damasku,yóo sì jó ibi ààbò Benhadadi.”

Ìdájọ́ OLUWA lórí Ẹ̀yà Kedari ati ìlú Hasori

28 OLUWA sọ nípa Kedari ati àwọn ìjọba Hasori tí Nebukadinesari ọba Babiloni ṣẹgun pé,“Ẹ dìde kí ẹ gbógun ti Kedari!Ẹ pa àwọn ará ìlà oòrùn run!

29 Ogun yóo kó àgọ́ wọn ati àwọn ẹran ọ̀sìn wọn lọ,ati àwọn aṣọ àgọ́, ati ohun ìní wọn;Ọ̀tá yóo kó ràkúnmí wọn lọ,àwọn eniyan yóo máa kígbe sí wọn pé,‘Ìpayà wà ní gbogbo àyíká.’

30 “Ẹ̀yin ará Hasori, ẹ sá,ẹ lọ jìnnà réré, kí ẹ sì máa gbé inú ọ̀gbun.Nítorí pé Nebukadinesari, ọba Babiloni ń pète ibi si yín,ó ti pinnu ibi si yín.

31 Ó ní, ‘Ẹ dìde kí ẹ gbógun ti orílẹ̀-èdè tí ó wà ní alaafia, ati láìléwu,ìlú tí ó dá dúró tí kò sì ní ìlẹ̀kùn tabi ọ̀pá ìdábùú ìlẹ̀kùn fún ààbò.’

32 “Àwọn ràkúnmí ati agbo ẹran wọn yóo di ìkógun.N óo fọ́n àwọn tí wọn ń gé ẹsẹ̀ irun wọn ká sí igun mẹrẹẹrin ayé,n óo sì mú kí ibi bá wọn láti gbogbo àyíká wọn.

33 Hasori yóo di ibùgbé ajáko,yóo di ahoro títí laelae.Ẹnìkan kò ní gbé ibẹ̀ mọ́,bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kò ní dé sibẹ mọ́.”

Ìdájọ́ OLUWA lórí Elamu

34 OLUWA àwọn ọmọ ogun bá Jeremaya wolii sọ nípa Elamu ní ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba Sedekaya, ọba Juda.

35 Ó ní, “Wò ó! N óo pa àwọn tafàtafà Elamu, tí wọn jẹ́ orísun agbára wọn,

36 n óo mú kí ẹ̀fúùfù mẹrin láti igun mẹrẹẹrin ojú ọ̀run kọlu Elamu; n óo sì fọ́n wọn ká sinu ẹ̀fúùfù náà, kò sì ní sí orílẹ̀-èdè kan tí àwọn ará Elamu kò ní fọ́n ká dé.

37 N óo dẹ́rùbà wọ́n; níwájú àwọn ọ̀tá wọn, ati níwájú àwọn tí ń wá ọ̀nà ati pa wọ́n. N óo bínú sí wọn gan-an, n óo sì mú kí ibi dé bá wọn. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. N óo rán ogun tẹ̀lé wọn, títí n óo fi pa wọ́n tán.

38 N óo tẹ́ ìtẹ́ mi kalẹ̀ ní Elamu, n óo sì pa ọba ati àwọn ìjòyè wọn.

39 Ṣugbọn nígbẹ̀yìn, n óo dá ire Elamu pada. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”