Jeremaya 40 BM

Jeremaya Ń Gbé Ọ̀dọ̀ Gedalaya

1 OLUWA bá Jeremaya sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tí Nebusaradani, olórí àwọn tí ń ṣọ́ ọba Babiloni, tú u sílẹ̀ ní Rama. Nebusaradani rí Jeremaya tí wọ́n fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ dè é, wọ́n sì kó o pọ̀ mọ́ àwọn tí wọn kó kúrò ní ìlú Jerusalẹmu ati ní ilẹ̀ Juda tí wọn ń kó lọ sí Babiloni.

2 Nebusaradani, olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ ọba Babiloni, sọ fún Jeremaya pé, “OLUWA Ọlọrun rẹ ti pinnu láti ṣe ilẹ̀ yìí ní ibi;

3 Ó sì ti ṣe bí ó ti pinnu nítorí pé ẹ dẹ́ṣẹ̀ sí i, ẹ kò sì fetí sí ohùn rẹ̀, nítorí náà ni ibi ṣe dé ba yín.

4 Nisinsinyii, wò ó, mo tú ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ ọwọ́ rẹ sílẹ̀, bí o bá fẹ́ bá mi lọ sí Babiloni, máa bá mi kálọ, n óo tọ́jú rẹ dáradára; bí o kò bá sì fẹ́ lọ, dúró. Wò ó, gbogbo ilẹ̀ nìyí níwájú rẹ yìí, ibi tí o bá fẹ́ tí ó dára lójú rẹ ni kí o lọ.

5 Bí o bá fẹ́ pada, pada lọ bá Gedalaya ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani, ẹni tí ọba Babiloni fi ṣe gomina àwọn ìlú Juda, kí o máa bá a gbé láàrin àwọn eniyan náà. Bí o kò bá sì fẹ́ bẹ́ẹ̀, ibi tí ó bá wù ọ́ láti lọ ni kí o lọ.” Olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ ọba bá fún un ní owó, oúnjẹ, ati ẹ̀bùn, ó ní kí ó máa lọ.

6 Jeremaya bá pada sọ́dọ̀ Gedalaya, ọmọ Ahikamu ní Misipa, ó sì ń gbé pẹlu rẹ̀ láàrin àwọn eniyan tí wọn kù ní ilẹ̀ náà.

Gedalaya, Gomina Juda

7 Nígbà tí gbogbo àwọn olórí ogun tí wọ́n wà ní ìgbèríko pẹlu àwọn ọmọ ogun wọn gbọ́ pé ọba Babiloni ti fi Gedalaya ọmọ Ahikamu jẹ gomina ní ilẹ̀ Juda, ati pé ó ti fi ṣe olùtọ́jú àwọn ọkunrin, ati àwọn obinrin, ati àwọn ọmọde ati díẹ̀ ninu àwọn talaka ilẹ̀ Juda, tí wọn kò kó lọ sí Babiloni,

8 wọ́n lọ bá Gedalaya ní Misipa. Àwọn tí wọ́n lọ nìwọ̀nyí: Iṣimaeli, ọmọ Netanaya, Johanani, ọmọ Karea, Seraaya, ọmọ Tanhumeti, àwọn ọmọ Efai, ará Netofa, Jesanaya, ọmọ ará Maakati, àwọn àtàwọn eniyan wọn.

9 Gedalaya bá búra fún àwọn ati àwọn eniyan wọn pé, “Ẹ má bẹ̀rù ati sin àwọn ará Kalidea. Ẹ máa gbé ilẹ̀ yìí, kí ẹ máa sin ọba Babiloni, yóo sì dára fun yín.

10 Ní tèmi, Misipa ni n óo máa gbé kí n lè máa rí ààyè bá àwọn ará Kalidea tí wọn wá dótì wá sọ̀rọ̀. Ẹ̀yin ẹ máa kó ọtí, èso, ati òróró jọ sinu ìkòkò yín, kí ẹ sì máa gbé àwọn ìlú tí ẹ ti gbà.”

11 Bákan náà, nígbà tí gbogbo àwọn ará Juda tí wọn wà ní ilẹ̀ Moabu, ati àwọn tí wọn wà ní ilẹ̀ àwọn ará Amoni ati ti Edomu ati àwọn tí wọ́n wà ní gbogbo ilẹ̀ káàkiri gbọ́ pé ọba Babiloni dá àwọn eniyan díẹ̀ sí ní Juda, àtipé ó fi Gedalaya, ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani, ṣe gomina wọn,

12 gbogbo àwọn ará Juda pada láti gbogbo ibi tí wọn sá lọ, wọ́n wá sí ilẹ̀ Juda, wọ́n lọ sí ọ̀dọ̀ Gedalaya ní Misipa, wọ́n sì kó ọtí ati èso jọ lọpọlọpọ.

Wọ́n Pa Gedalaya

13 Johanani ọmọ Karea ati gbogbo àwọn olórí ogun tí wọ́n wà ní ìgbèríko wá sọ́dọ̀ Gedalaya ní Misipa.

14 Wọ́n sọ fún un pé, “Ǹjẹ́ o mọ̀ pé Baalisi, ọba àwọn ọmọ Amoni ti rán Iṣimaeli, ọmọ Netanaya pé kí ó wá pa ọ́?” Ṣugbọn Gedalaya kò gbà wọ́n gbọ́.

15 Johanani bá sọ fún Gedalaya ní ìkọ̀kọ̀ ní Misipa pé, “Jẹ́ kí n lọ pa Iṣimaeli ọmọ Netanaya, ẹnikẹ́ni kò sì ní mọ̀. Kí ló dé tí o óo jẹ́ kí ó pa ọ́, tí gbogbo Juda tí wọn kóra jọ sí ọ̀dọ̀ rẹ yóo sì túká; tí àwọn tí wọn ṣẹ́kù ninu àwọn eniyan Juda yóo sì ṣègbé?”

16 Ṣugbọn Gedalaya sọ fún Johanani, ọmọ Karea pé, “Má ṣe bẹ́ẹ̀, irọ́ ni ò ń pamọ́ Iṣimaeli.”