Jeremaya 2 BM

Ìtọ́jú Ọlọrun lórí Israẹli

1 OLUWA sọ fún mi pé,

2 “Lọ kéde sí etígbọ̀ọ́ àwọn ará Jerusalẹmu, pé èmi OLUWA ní, mo ranti bí o ti fi ara rẹ jì mí nígbà èwe rẹ, ìfẹ́ rẹ dàbí ìfẹ́ iyawo àṣẹ̀ṣẹ̀gbé; mo ranti bí o ṣe ń tẹ̀lé mi ninu aṣálẹ̀, ní ilẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò gbin nǹkankan sí.

3 Israẹli jẹ́ mímọ́ fún OLUWAÒun ni àkọ́so èso rẹ̀.Gbogbo àwọn tí wọ́n jẹ ninu àkọ́so èso yìí di ẹlẹ́bi;ibi sì dé bá wọn.Èmi OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.”

Ẹ̀ṣẹ̀ Àwọn Baba Ńlá Israẹli

4 Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA, ẹ̀yin ilé Jakọbu, ati gbogbo ìdílé Israẹli.

5 OLUWA ní: “Nǹkan burúkú wo ni àwọn baba ńlá yín ní mo fi ṣe àwọn, tí wọ́n jìnnà sí mi; tí wọ́n fi bẹ̀rẹ̀ síí bọ oriṣa lásánlàsàn, tí àwọn pàápàá sì fi di eniyan lásán?

6 Wọn kò bèèrè pé, Níbo ni OLUWA wà,ẹni tí ó kó wa jáde láti ilẹ̀ Ijipti,tí ó sìn wá la aṣálẹ̀ já,ilẹ̀ aṣálẹ̀ tí ó kún fún ọ̀gbun,ilẹ̀ ọ̀dá ati òkùnkùn biribiri,ilẹ̀ tí eniyan kìí là kọjá,tí ẹnikẹ́ni kì í gbé?

7 Mo mu yín wá sí ilẹ̀ tí ó lọ́ràá,pé kí ẹ máa gbádùn èso rẹ̀ ati àwọn nǹkan dáradára tí wọ́n wà ninu rẹ̀,ṣugbọn nígbà tí ẹ dé inú rẹ̀, ẹ sọ ilẹ̀ mi di aláìmọ́,ẹ sì sọ ogún mi di ohun ìríra.

8 Àwọn alufaa kò bèèrè pé, ‘OLUWA dà?’Àwọn tí wọn ń ṣe àmójútó òfin kò mọ̀ mí,àwọn olórí ń dìtẹ̀ sí mi,àwọn wolii ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní orúkọ oriṣa Baali,wọ́n sì ń tẹ̀lé àwọn oriṣa lásánlàsàn.

OLUWA fi Ẹ̀sùn Kan Àwọn Eniyan Rẹ̀

9 “Nítorí náà, mò ń ba yín rojọ́,n óo sì tún bá arọmọdọmọ yín rojọ́ pẹlu.”OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.

10 Ó ní, “Ẹ kọjá sí èbúté àwọn ará Kipru kí ẹ wò yíká,tabi kí ẹ ranṣẹ sí Kedari kí ẹ sì ṣe ìwádìí fínnífínní,bóyá irú rẹ̀ ṣẹlẹ̀ rí.

11 Ǹjẹ́ orílẹ̀-èdè kankan tíì pààrọ̀ ọlọrun rẹ̀ rí,bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kì í ṣe ọlọrun tòótọ́?Ṣugbọn àwọn eniyan mi ti pààrọ̀ ògo wọn,wọ́n ti fi ohun tí kò ní èrè pààrọ̀ rẹ̀.

12 Nítorí náà kí ẹ̀rù kí ó bà ọ́, ìwọ ọ̀run,kí o wárìrì, kí gbogbo nǹkan dàrú mọ́ ọ lójú.”

13 OLUWA wí pé, “Nítorí pé àwọn eniyan mi ṣe nǹkan burúkú meji:wọ́n ti kọ èmi orísun omi ìyè sílẹ̀,wọ́n ṣe kànga fún ara wọn;kànga tí ó ti là, tí kò lè gba omi dúró.

Èrè Aiṣododo Israẹli

14 “Ṣé ẹrú ni Israẹli ni,àbí ọmọ ẹrú tí ẹrú bí sinu ilé?Báwo ló ṣe wá di ìjẹ fún àwọn ọ̀tá rẹ̀.

15 Àwọn kinniun ti bú mọ́ ọn,wọ́n bú ramúramù.Wọ́n sọ ilẹ̀ rẹ̀ di ahoro.Àwọn ìlú rẹ̀ sì ti tú, wọ́n ti wó palẹ̀,láìsí eniyan tí ń gbé inú wọn.

16 Bákan náà, àwọn ará Memfisi ati Tapanhesi ti fọ́ adé orí rẹ̀.

17 Ṣebí ọwọ́ ara yín ni ẹ fi fà á sí orí ara yín,nígbà tí ẹ̀yin kọ Ọlọrun yín sílẹ̀,nígbà tí ó ń tọ yín sọ́nà?

18 Kí ni èrè tí ẹ rí nígbà tí ẹ lọ sí Ijipti,tí ẹ lọ mu omi odò Naili,àbí kí ni èrè tí ẹ gbà bọ̀ nígbà tí ẹ lọ sí Asiria,tí ẹ lọ mu omi odò Yufurate.

19 Ìwà burúkú yín yóo fìyà jẹ yín,ìpadà sẹ́yìn yín yóo sì kọ yín lọ́gbọ́n.Kí ó da yín lójú pé,nǹkan burúkú ni, ìgbẹ̀yìn rẹ̀ kò sì ní dùn,pé ẹ fi èmi OLUWA Ọlọrun yín sílẹ̀;ìbẹ̀rù mi kò sí ninu yín.Èmi, OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Israẹli Kọ̀ láti Sin OLUWA

20 OLUWA wí pé,“Nítorí pé ó ti pẹ́ tí ẹ ti bọ́ àjàgà yín,tí ẹ sì ti tú ìdè yín;tí ẹ sọ pé, ẹ kò ní sìn mí.Ẹ̀ ń lọ káàkiri lórí gbogbo òkè,ati lábẹ́ gbogbo igi tútù;ẹ̀ ń foríbalẹ̀, ẹ̀ ń ṣe bíi panṣaga.

21 Sibẹ mo gbìn yín gẹ́gẹ́ bí àjàrà tí mo fẹ́,tí èso rẹ̀ dára.Báwo ni ẹ ṣe wá yipada patapata,tí ẹ di àjàrà igbó tí kò wúlò?

22 Bí ẹ tilẹ̀ fi eérú fọ ara yín,tí ẹ sì fi ọpọlọpọ ọṣẹ wẹ̀,sibẹ, àbààwọ́n ẹ̀bi yín wà níwájú mi.

23 Báwo ní ẹ ṣe lè wí pé ẹ kì í ṣe aláìmọ́;ati pé ẹ kò tẹ̀lé àwọn oriṣa Baali?Ẹ wo irú ìwà tí ẹ hù ninu àfonífojì,kí ẹ ranti gbogbo ibi tí ẹ ṣebí ọmọ ràkúnmí tí ń lọ, tí ń bọ̀;tí ń tọ ipa ọ̀nà ara rẹ̀.

24 Ẹ dàbíi Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ìgbẹ́, tí aṣálẹ̀ ti mọ́ lára,tí ń ṣí imú kiri,nígbà tí ó ń wa akọ tí yóo gùn ún.Ta ló lè dá a dúró?Kí akọ tí ó bá ń wá amá wulẹ̀ ṣe ara rẹ̀ ní wahala,nítorí yóo yọjú nígbà tí àkókò gígùn rẹ̀ bá tó.

25 Má rìn láìwọ bàtà, Israẹli,má sì jẹ́ kí òùngbẹ gbẹ ọ́.Ṣugbọn o sọ pé, ‘Kò sí ìrètí,nítorí àjèjì oriṣa ni mo fẹ́,n óo sì wá wọn kiri.’ ”

Ó Tọ́ kí Israẹli Jìyà

26 OLUWA ní, “Bí ojú tíí ti olè nígbà tí ọwọ́ bá tẹ̀ ẹ́,bẹ́ẹ̀ ni ojú yóo tì yín, ẹ̀yin ọmọ Israẹli.Àtẹ̀yin ati àwọn ọba yín, ati àwọn ìjòyè yín,ati àwọn alufaa yín, ati àwọn wolii yín;

27 ẹ̀yin tí ẹ̀ ń wí fún igi pé igi ni baba yín,tí ẹ sì ń sọ fún òkúta pé òkúta ni ó bi yín;nítorí pé dípò kí ẹ kọjú sí ọ̀dọ̀ mi,ẹ̀yìn ni ẹ kọ sí mi.Ṣugbọn nígbà tí ìṣòro dé ba yín,ẹ bẹ̀rẹ̀ sí kígbe pè mí pé kí n dìde, kí n gbà yín là.

28 “Ṣugbọn níbo ni àwọn oriṣa yín tí ẹ dá fún ara yín wà?Kí wọn dìde, tí wọ́n bá lè gbà yín ní àkókò ìṣòro yín!Ṣebí bí ìlú yín ti pọ̀ tó, bẹ́ẹ̀ ni àwọn oriṣa yín náà pọ̀ tó, ẹ̀yin ará Juda.

29 Ẹjọ́ kí ni ẹ wá ń bá mi rò?Ṣebí gbogbo yín ni ẹ̀ ń bá mi ṣọ̀tẹ̀!

30 Mo na àwọn ọmọ yín lásán ni,wọn kò gba ẹ̀kọ́.Ẹ̀yin gan-an ni ẹ fi idà pa àwọn wolii yín ní àparun,bíi kinniun tí ń pa ẹran kiri.

31 Ẹ̀yin ìran yìí, ẹ gbọ́ ohun tí èmi, OLUWA ń sọ.Ṣé aṣálẹ̀ ni mo jẹ́ fún Israẹli;tabi mo ti di ilẹ̀ òkùnkùn biribiri?Kí ló dé tí ẹ̀yin eniyan mi fí ń sọ pé,‘A ti di òmìnira, a lè máa káàkiri;a kò ní wá sí ọ̀dọ̀ rẹ mọ́?’

32 Ṣé ọmọbinrin lè gbàgbé ohun ọ̀ṣọ́ rẹ̀?Tabi iyawo àṣẹ̀ṣẹ̀gbé lè gbàgbé àwọn aṣọ rẹ̀?Sibẹ ẹ ti gbàgbé mi tipẹ́.

33 “Ẹ mọ oríṣìíríṣìí ọ̀nà tí eniyan fi í wá olólùfẹ́ kiri,tóbẹ́ẹ̀ tí ẹ ti fi ìrìnkurìn yínkọ́ àwọn obinrin oníwà burúkú.

34 Ẹ̀jẹ̀ àwọn talaka tí kò ṣẹ̀, wà létí aṣọ yín;bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò bá wọn níbi tí wọ́n ti ń fọ́lé.Gbogbo èyí wà bẹ́ẹ̀,

35 sibẹ ẹ̀ ń sọ pé, ‘Ọwọ́ wa mọ́;dájúdájú, OLUWA ti dá ọwọ́ ibinu rẹ̀ dúró lára wa.’Ẹ wò ó! N óo dá yín lẹ́jọ́,nítorí ẹ̀ ń sọ pé ẹ kò dẹ́ṣẹ̀.

36 Ẹ̀ ń fi ara yín wọ́lẹ̀ káàkiri;ẹ̀ ń yà síhìn-ín sọ́hùn-ún!Bí Asiria ti dójú tì yín,bẹ́ẹ̀ ni Ijipti náà yóo dójú tì yín.

37 Ẹ óo ká ọwọ́ lérí ninígbà tí ẹ óo bá jáde níbẹ̀.Nítorí OLUWA ti kọ àwọn tí ẹ gbójúlé,wọn kò sì ní ṣe yín níre.”