1 OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli sọ nípa Moabu pé,“Nebo gbé nítorí yóo di ahoro!Ojú yóo ti Kiriataimu nítorí ogun óo kó o;ìtìjú yóo bá ibi ààbò rẹ̀, wọn óo wó o lulẹ̀;
2 ògo Moabu ti dópin!Wọ́n ń pète ibi sí i ní Heṣiboni,wọ́n ní, ‘Ẹ jẹ́ kí á lọ pa á run, kí ó má jẹ́ orílẹ̀-èdè mọ́!’Ẹ̀yin ará Madimeni pàápàá, kẹ́kẹ́ yóo pa mọ yín lẹ́nu;ogun yóo máa le yín kiri.
3 Gbọ́ igbe kan ní Horonaimu,igbe ìsọdahoro ati ìparun ńlá!
4 “Moabu ti parun; a gbọ́ igbe àwọn ọmọ rẹ̀.
5 Bí wọn tí ń gun òkè Luhiti, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń sọkún,nítorí pé nígbà tí wọn tí ń lọ níbi ẹsẹ̀ òkè Horonaimu,ni wọ́n tí ń gbọ́ igbe ìparun; pé,
6 ‘Ẹ sá! Ẹ sá àsálà fún ẹ̀mí yín!Ẹ sáré bíi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ aṣálẹ̀!’
7 “Ọwọ́ yóo tẹ ìwọ náà, Moabu, nítorí pé o gbójú lé ibi ààbò ati ọrọ̀ rẹ.Oriṣa Kemoṣi yóo lọ sí ìgbèkùn, pẹlu àwọn babalóòṣà ati àwọn ìjòyè rẹ̀.
8 Apanirun yóo wọ gbogbo ìlú,ìlú kankan kò sì ní bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀;àwọn àfonífojì yóo pòórá, a óo sì pa àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ run. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
9 Ẹ bá Moabu wá ìyẹ́, nítorí yóo fò bí ẹyẹ;àwọn ìlú rẹ̀ yóo di ahoro, kò ní ku ẹnikẹ́ni ninu wọn.”
10 (Ègún ń bẹ lórí ẹni tí ó bá ń fi ìmẹ́lẹ́ ṣe iṣẹ́ OLUWA;ègún sì ń bẹ lórí ẹni tí ó bá sì kọ̀, tí kò máa fi idà rẹ̀ pa eniyan.)
11 OLUWA ní,“Láti ìgbà èwe Moabu ni ó ti ń gbé pẹlu ìrọ̀rùn,kò tíì lọ sí ìgbèkùn rí.Nítorí náà ó silẹ̀ bí gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ ọtí.A kò máa dà á kiri láti inú ìgò kan sí òmíràn.Adùn rẹ̀ ṣì wà lára rẹ̀, òórùn rẹ̀ kò sì tíì yipada.
12 “Nítorí náà, àkókò ń bọ̀,tí n óo jẹ́ kí wọn da Moabu nù, bí ẹni da ọtí nù.Àwọn tí wọn ń da ọtí nù ni n óo rán, tí wọn óo wá tẹ̀ ẹ́ bí ìgò ọtíwọn óo dà á nù patapata, wọn óo sì fọ́ ìgò rẹ̀.
13 Kemoṣi yóo di ohun ìtìjú fún Moabu,gẹ́gẹ́ bí Bẹtẹli, tí Israẹli gbójú lé, ṣe di ohun ìtìjú fún Israẹli.
14 Ẹ ṣe lè wí pé alágbára ni yín, ati pé ẹ jẹ́ akikanju lójú ogun?
15 Ẹni tí yóo pa ilẹ̀ Moabu ati àwọn ìlú rẹ̀ run ti dé,àwọn àṣàyàn ọmọkunrin rẹ̀ sì ti lọ sí ibi tí wọn ó ti pa wọ́n.Èmi ọba, tí orúkọ mi ń jẹ́ OLUWA àwọn ọmọ ogun, ni ó sọ bẹ́ẹ̀.
16 Ọjọ́ ìdààmú Moabu fẹ́rẹ̀ dé, ìpọ́njú rẹ̀ sì ń bọ̀ kánkán.
17 “Gbogbo ẹ̀yin tí ẹ yí i ká, ẹ dárò rẹ̀,kí gbogbo ẹ̀yin tí ẹ mọ orúkọ rẹ̀ sì wí pé,‘Ọ̀pá àṣẹ tí ó lágbára ti kán,ọ̀pá àṣẹ tí ó lógo ti ṣẹ́.’
18 Sọ̀kalẹ̀ kúrò ninu ògo rẹ, kí o jókòó lórí ìyàngbẹ ilẹ̀, ìwọ tí ò ń gbé Diboni!Nítorí pé ẹni tí óo pa Moabu run ti dojú kọ ọ́,ó sì ti wó àwọn ibi ààbò rẹ̀.
19 Dúró lẹ́bàá ọ̀nà kí o máa ṣọ́nà, ìwọ tí ò ń gbé Aroeri!Bèèrè lọ́wọ́ àwọn tí wọ́n sálọ; bi àwọn tí ń sá àsálà pé, ‘Kí ló ṣẹlẹ̀?’
20 Ìtìjú ti bá Moabu, nítorí pé ó ti wó lulẹ̀; ẹ kígbe, ẹ máa sọkún.Ẹ kéde rẹ̀ ní ipadò Anoni, pé,‘Moabu ti parẹ́, ó ti di òkítì àlàpà.’
21 “Ìdájọ́ ti dé sórí àwọn ìlú tí ó wà ní ilẹ̀ tí ó tẹ́jú: Holoni, Jahisai, ati Mefaati;
22 Diboni, Nebo, ati Beti Dibilataimu,
23 Kiriataimu, Betigamuli, ati Betimeoni,
24 Kerioti, Bosira, ati gbogbo àwọn ìlú ilẹ̀ Moabu, ati àwọn tí wọ́n wà nítòsí, ati àwọn tí wọ́n wà lókèèrè.
25 Ipá Moabu ti pin, a sì ti ṣẹ́ ẹ lápá. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
26 OLUWA ní,“Ẹ rọ Moabu lọ́tí yó,nítorí pé ó gbéraga sí OLUWA;kí ó lè máa yíràá ninu èébì rẹ̀,a óo sì fi òun náà ṣẹ̀sín.
27 Moabu, ṣebí ò ń fi Israẹli ṣe yẹ̀yẹ́?Ṣé o bá a láàrin àwọn ọlọ́ṣà ni,tí ó fi jẹ́ pé nígbàkúùgbà tí o bá ń sọ̀rọ̀ rẹ̀, ń ṣe ni o máa ń mi orí rẹ?
28 “Ẹ fi ààrin ìlú sílẹ̀, kí ẹ lọ máa gbé inú àpáta, ẹ̀yin ará Moabu!Ẹ ṣe bí àdàbà, tí ó kọ́lé rẹ̀ sí ẹ̀gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ ẹnu ihò àpáta.
29 A ti gbọ́ nípa ìgbéraga Moabu,ó ní ìgbéraga lọpọlọpọ,a ti gbọ́ nípa èrò gíga rẹ̀, ati ìgbéraga rẹ̀,nípa àfojúdi rẹ̀, ati nípa ìwà ìjọra-ẹni-lójú rẹ̀.
30 Mo mọ̀ pé aláfojúdi ni.Ó ń fọ́nnu lásán ni, kò lè ṣe nǹkankan tó yanjú.
31 Nítorí náà, ni mo ṣe ń sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn, tí mò ń kígbe sókè nítorí Moabutí mo sì ń ṣọ̀fọ̀ nítorí àwọn ará Kiri Heresi.
32 Ìwọ ọgbà àjàrà Sibima,ọ̀rọ̀ rẹ pa mí lẹ́kún, ju ti Jaseri lọ!Àwọn ẹ̀ka rẹ tàn dé òkun, wọ́n tàn títí dé Jaseri,apanirun sì ti kọlu àwọn èso ẹ̀ẹ̀rùn rẹ, ati èso àjàrà rẹ.
33 Wọ́n ti mú ayọ̀ ati ìdùnnú kúrò ní ilẹ̀ ọlọ́ràá Moabu;mo ti mú kí ọtí waini tán níbi tí wọ́n ti ń ṣe é,kò sí ẹni tí ó ń ṣe ọtí waini pẹlu ariwo ayọ̀ mọ́, ariwo tí wọn ń pa kì í ṣe ti ayọ̀.
34 “Heṣiboni ati Eleale kígbe sókè, igbe wọn sì dé Jahasi láti Soari, ó dé Horonaimu ati Egilati Ṣeliṣiya. Àwọn odò Nimrimu pàápàá ti gbẹ.
35 N óo pa àwọn tí ń rú ẹbọ níbi pẹpẹ ìrúbọ run, ati àwọn tí ń sun turari sí oriṣa ní ilẹ̀ Moabu.
36 “Nítorí náà ni mo ṣe ń dárò Moabu ati àwọn ará Kiri Heresi bí ẹni fi fèrè kọ orin arò nítorí pé gbogbo ọrọ̀ tí wọ́n kó jọ ti ṣègbé.
37 Gbogbo wọn ti fá irun orí ati irùngbọ̀n wọn; wọ́n ti fi abẹ ya gbogbo ọwọ́ wọn, wọ́n sì lọ́ aṣọ ọ̀fọ̀ mọ́ ìbàdí.
38 Gbogbo eniyan ń sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn ní gbogbo orí ilé Moabu, ati àwọn ìta gbangba rẹ̀. Nítorí pé mo ti fọ́ Moabu, bíi ohun èlò tí ẹnikẹ́ni kò bìkítà fún. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
39 A ti fọ́ Moabu túútúú! Ẹ̀ ń sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn! Moabu pẹ̀yìndà pẹlu ìtìjú! Moabu wá di ẹni yẹ̀yẹ́ ati ẹni àríbẹ̀rù fún gbogbo àwọn tí wọ́n yí i ká.”
40 OLUWA ní,“Wò ó, ẹnìkan yóo fò wá bí ẹyẹ idì,yóo sì na ìyẹ́ apá rẹ̀ lé Moabu lórí.
41 Ogun yóo kó àwọn ìlú Moabu,wọn óo sì gba àwọn ibi ààbò rẹ̀.Ní ọjọ́ náà, ọkàn àwọn ọmọ ogun Moabu yóo dàbí ọkàn obinrin tí ó ń rọbí,
42 Moabu yóo parun, kò ní jẹ́ orílẹ̀-èdè mọ́,nítorí pé ó ṣe ìgbéraga sí OLÚWA.
43 Ẹ̀yin ará Moabu,ìpayà, ọ̀gbun ati tàkúté ń bẹ níwájú yín!
44 Ẹni tí ó ń sálọ nítorí ìpayà,yóo jìn sinu ọ̀gbun,ẹni tí ó bá sì jáde ninu ọ̀gbunyóo kó sinu tàkúté.N óo mú kí àwọn nǹkan wọnyi dé bá Moabunígbà tí àkókò ìjìyà rẹ̀ bá tó.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
45 Àwọn tí wọn ń sá fún ogun dúró ní ibi ààbò Heṣiboni,wọn kò lágbára mọ́,nítorí iná ṣẹ́ jáde láti Heṣiboniahọ́n iná sì yọ láàrin ilé Sihoni ọba;iná ti jó Moabu tíí ṣe adé àwọn ọmọ onídàrúdàpọ̀ ní àjórun,
46 Ẹ̀yin ará Moabu, ẹ gbé!Ó ti parí fun yín, ẹ̀yin ọmọ Kemoṣi,nítorí a ti kó àwọn ọmọkunrin yín lẹ́rú,a ti kó àwọn ọmọbinrin yín lọ sí ìgbèkùn.
47 “Sibẹsibẹ n óo dá ire Moabu pada lẹ́yìn ọ̀la,èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.Bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún Moabu.”