Aisaya 50 BM

1 OLUWA ní:OLUWA ní:“Ìwé ìkọ̀sílẹ̀ tí mo fi kọ àwọn eniyan mi sílẹ̀ dà?Ta ni mo tà yín fún,tí mo jẹ lówó?Ẹ wò ó! Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín ni a ṣe tà yín,nítorí àìdára yín ni mo ṣe kọ̀ yín sílẹ̀.

2 “Kí ló dé tí mo wá àwọn eniyan mi tí n kò rí ẹnìkan;mo pè, ẹnikẹ́ni kò dá mi lóhùn?Ṣé n kò lágbára tó láti rà wọ́n pada ni;àbí n kò lágbára láti gba ni là?Wò ó! Ìbáwí lásán ni mo fi gbẹ́ omi òkun,tí mo sì fi sọ odò tí ń ṣàn di aṣálẹ̀,omi wọn gbẹ,òùngbẹ gbẹ àwọn ẹja inú wọn pa,wọ́n kú, wọ́n sì ń rùn.

3 Mo da òkùnkùn bo ojú ọ̀run bí aṣọ,mo ṣe aṣọ ọ̀fọ̀ ní ìbora fún wọn.”

Ìgbọràn Iranṣẹ OLUWA

4 OLUWA Ọlọrun ti fi ọ̀rọ̀ ìmọ̀ sí mi lẹ́nu.Kí n lè mọ bí a tií gba àwọn tí ọkàn wọn rẹ̀wẹ̀sì níyànjú.Ojoojumọ ni ó ń ṣí mi létí láràárọ̀,kí n lè máa gbọ́rọ̀ bí àwọn akẹ́kọ̀ọ́.

5 OLUWA Ọlọrun ti ṣí mi létí,n kò sì ṣe oríkunkun,tabi kí n pada sẹ́yìn.

6 Mo tẹ́ ẹ̀yìn sílẹ̀ fún àwọn tí ń nani lẹ́gba;mo sì kọ ẹ̀rẹ̀kẹ́ sí àwọn tí ń fa eniyan ní irùngbọ̀n tu.N kò fojú pamọ́ nítorí ẹ̀gàn,bẹ́ẹ̀ ni n kò gbójú sá fún itọ́ títu síni lójú.

7 OLUWA Ọlọrun ń ràn mí lọ́wọ́,nítorí náà ojú kò tì mí;nítorí náà mo múra gírí,mo jẹ́ kí ojú mi le koko,mo sì mọ̀ pé ojú kò ní tì mí.

8 Ẹni tí yóo dá mi láre wà nítòsí,ta ló fẹ́ bá mi jà?Ta ló fẹ́ fi ẹ̀sùn kàn mí?Kí olúwarẹ̀ súnmọ́ tòsí mi,kí á jọ kojú ara wa?

9 Wò ó! OLUWA Ọlọrun ń ràn mí lọ́wọ́,ta ni yóo dá mi lẹ́bi?Gbogbo wọn ni yóo gbọ̀n dànù bí aṣọ,kòkòrò yóo sì jẹ wọ́n.

10 Ta ló bẹ̀rù OLUWA ninu yín,tí ń gbọ́ràn sí iranṣẹ rẹ̀ lẹ́nu,tí ń rìn ninu òkùnkùn,tí kò ní ìmọ́lẹ̀,ṣugbọn sibẹ, tí ó gbẹ́kẹ̀lé OLUWA,tí ó fẹ̀yìn ti Ọlọrun rẹ̀.

11 Gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń dáná,tí ẹ tan iná yí ara yín ká,ẹ máa rìn lọ ninu iná tí ẹ dá;ẹ máa la iná tí ẹ fi yí ara yín ká kọjá.Bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe fun yín.Ẹ óo wà ninu ìrora.