Aisaya 63 BM

Ìṣẹ́gun OLUWA lórí Àwọn Orílẹ̀-Èdè

1 “Ta ni ń ti Edomu bọ̀ yìí,tí ó wọ aṣọ àlàárì, tí ń bọ̀ láti Bosira,tí ó yọ bí ọjọ́ ninu aṣọ tí ó wọ̀,tí ń yan bọ̀ ninu agbára ńlá rẹ̀.”“Èmi ni, èmi tí mò ń kéde ẹ̀san,tí mo sì lágbára láti gbani là.”

2 “Kí ló dé tí aṣọ rẹ fi pupa,tí ó dàbí ti ẹni tí ń fún ọtí waini?”

3 OLUWA dáhùn, ó ní, “Èmi nìkan ni mo tí ń fún ọtí waini,ẹnikẹ́ni kò bá mi fún un ninu àwọn eniyan mi.Mo fi ibinu tẹ̀ wọ́n bí èso àjàrà,mo fi ìrúnú tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀.Ẹ̀jẹ̀ wọn bá dà sí mi láṣọ:ó ti di àbààwọ́n sára gbogbo aṣọ mi.

4 Nítorí ọjọ́ ẹ̀san ló wà lọ́kàn mi,ọdún ìràpadà mi sì ti dé.

5 Mo wò yíká, ṣugbọn kò sí olùrànlọ́wọ́,ẹnu yà mí pé, n kò rí ẹnìkan tí yóo gbé mi ró;nítorí náà, agbára mi ni mo fi ṣẹgun,ibinu mi ni ó sì gbé mi ró.

6 Mo fi ibinu tẹ àwọn orílẹ̀-èdè mọ́lẹ̀,mo fi ìrúnú rọ wọ́n yó,mo sì tú ẹ̀jẹ̀ wọn dà sílẹ̀.”

Oore OLUWA sí Israẹli

7 N óo máa sọ nípa ìfẹ́ ńlá OLUWA lemọ́lemọ́,n óo máa kọrin ìyìn rẹ̀;nítorí gbogbo ohun tí OLUWA ti fún wa,ati oore ńlá tí ó ṣe fún ilé Israẹli,tí ó ṣe fún wọn nítorí àánú rẹ̀,ati gẹ́gẹ́ bí ọpọlọpọ ìfẹ́ rẹ̀ tí kìí yẹ̀.

8 OLUWA ní, “Dájúdájú eniyan mi mà ni wọ́n,àwọn ọmọ tí kò ní hùwà àgàbàgebè.”Ó sì di Olùgbàlà wọn.

9 Ninu gbogbo ìyà tí wọ́n jẹ, òun pẹlu wọn ni,angẹli iwájú rẹ̀ sì gbà wọ́n là.Nítorí ìfẹ́ ati àánú rẹ̀, ó rà wọ́n pada.Ó fà wọ́n sókè, ó sì gbé wọn ní gbogbo ìgbà àtijọ́.

10 Ṣugbọn wọ́n hùwà ọlọ̀tẹ̀:wọ́n sì mú Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀ bínú.Nítorí náà ó di ọ̀tá wọn,ó sì dojú ìjà kọ wọ́n.

11 Ṣugbọn ó ranti ìgbà àtijọ́,ní àkókò Mose, iranṣẹ rẹ̀.Wọ́n bèèrè pé,ẹni tí ó kó wọn la òkun já dà?Olùṣọ́-aguntan agbo rẹ̀,tí ó fi Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀ sáàrin wọn?

12 Ẹni tí ó gbé agbára rẹ̀ tí ó lógo wọ Mose,tí ó pín òkun níyà níwájú wọn,kí orúkọ rẹ̀ lè lókìkí títí lae.

13 Ó mú wọn la ibú omi kọjá, bí ẹṣin ninu aṣálẹ̀;wọ́n rìn, wọn kò fẹsẹ̀ kọ.

14 Wọ́n rìn wọnú àfonífojì bíi mààlúù,Ẹ̀mí OLUWA sì fún wọn ní ìsinmi.Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe darí àwọn eniyan rẹ̀,kí ó lè gba ògo fún orúkọ rẹ̀.

Adura fún Àánú ati Ìrànlọ́wọ́

15 Bojúwo ilẹ̀ láti ọ̀run,láti ibùgbé rẹ mímọ́ tí ó lógo.Ìtara rẹ dà? Agbára rẹ dà?O ti dáwọ́ ìfẹ́ ati àánú rẹ dúró lára wa ni?

16 Ìwọ ni baba wa.Bí Abrahamu kò tilẹ̀ mọ̀ wá,tí Israẹli kò sì dá wa mọ̀.Ìwọ OLUWA ni baba wa,Olùràpadà wa láti ìgbà àtijọ́, ni orúkọ rẹ.

17 OLUWA kí ló dé tí o fi jẹ́ kí á ṣìnà, kúrò lọ́dọ̀ rẹ;tí o sé ọkàn wa lé, tí a kò fi bẹ̀rù rẹ?Pada sọ́dọ̀ wa nítorí àwọn iranṣẹ rẹ,nítorí àwọn ẹ̀yà Israẹli tíí ṣe ìní rẹ.

18 Fún ìgbà díẹ̀, ilé mímọ́ rẹ jẹ́ ti àwa eniyan mímọ́ rẹ;ṣugbọn àwọn ọ̀tá wa ti wó o lulẹ̀.

19 A wá dàbí àwọn tí o kò jọba lórí wọn rí,àní, bí àwọn tí a kò fi orúkọ rẹ pè.