Aisaya 27 BM

1 Ní ọjọ́ náà,OLUWA yóo fi idà rẹ̀ tí ó mú, tí ó tóbi, tí ó sì lágbára,pa Lefiatani, ejò tí ó ń fò,Lefiatani, ejò tí ń lọ́ wérékéké,yóo sì pa ejò ńlá tí ń bẹ ninu òkun.

2 Ní ọjọ́ náà,OLUWA yóo kọrin nípa ọgbà àjàrà dáradára kan pé,

3 “Èmi OLUWA ni olùṣọ́ rẹ̀,lásìkò, lásìkò ni mò ń bomi rin ín;tọ̀sán-tòru ni mò ń ṣọ́ ọkí ẹnìkan má baà bà á jẹ́.

4 Inú kò bí mi,ǹ bá rí ẹ̀gún ati pàǹtí ninu rẹ̀,ǹ bá gbógun tì wọ́n,ǹ bá jó gbogbo wọn níná papọ̀.

5 Ṣugbọn bí wọn bá fi mí ṣe ààbò,kí wọn wá kí á parí ìjà láàrin ara wa;kí wọn wá kí á parí ìjà láàrin ara wa.”

6 Ní ọjọ́ iwájúJakọbu yóo ta gbòǹgbò,Israẹli yóo tanná, yóo rúwé,yóo so, èso rẹ̀ yóo sì kún gbogbo ayé.

7 Ṣé OLUWA ti jẹ wọ́n níyà bí ó ti fìyà jẹ àwọn tí ó jẹ wọ́n níyà?Ṣé ó ti pa wọ́n bí ó ti pa àwọn tí ó pa wọ́n?

8 OLUWA fìyà jẹ àwọn eniyan rẹ̀,ó kó wọn lọ sí ìgbèkùn;ó lé wọn jáde ní ìlú,bí ìgbà tí ẹ̀fúùfù líle bá ń fẹ́ láti ìlà oòrùn.

9 Ọ̀nà tí a fi lè pa ẹ̀ṣẹ̀ Jakọbu rẹ́,tí a fi lè mú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ kúrò ni pé:Kí ó fọ́ gbogbo òkúta àwọn pẹpẹ oriṣa rẹ̀ túútúú,bí ẹfun tí a lọ̀ kúnná;kí ó má ku ère oriṣa Aṣera tabi pẹpẹ turari kan lóòró.

10 Nítorí ìlú olódi ti di ahoro,ó di ibùgbé tí a kọ̀ sílẹ̀, tí a sì patì bí aginjù;ibẹ̀ ni àwọn ọmọ mààlúù yóo ti máa jẹko,wọn óo dùbúlẹ̀ níbẹ̀, wọn óo sì máa jẹ àwọn ẹ̀ka igi rẹ̀.

11 Àwọn ẹ̀ka igi náà yóo dánígbà tí wọ́n bá gbẹ,àwọn obinrin yóo sì fi wọ́n dáná.Nítorí òye kò yé àwọn eniyan wọnyi rárá;nítorí náà, ẹni tí ó dá wọn kò ní ṣàánú wọn,Ẹni tí ó mọ wọ́n kò ní yọ́nú sí wọn.

12 Ní ọjọ́ náà,OLUWA yóo pa ẹ̀yin eniyan Israẹli bí ẹni pa ọkà,láti odò Yufurate títí dé odò Ijipti,yóo sì ko yín jọ lọ́kọ̀ọ̀kan.

13 Ní ọjọ́ náà,a óo fun fèrè ogun ńlá,àwọn tí ó ti sọnù sí ilẹ̀ Asiriaati àwọn tí a lé lọ sí ilẹ̀ Ijiptiyóo wá sin OLUWA lórí òkè mímọ́ ní Jerusalẹmu.