1 Ẹ súnmọ́ ibí, kí ẹ wá gbọ́, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè,ẹ tẹ́tí sílẹ̀, gbogbo ẹ̀yin eniyan.Kí ilẹ̀ gbọ́ ati gbogbo ohun tí ó wà lórí rẹ̀,kí ayé tẹ́tí sílẹ̀ pẹlu gbogbo nǹkan tí ń ti inú rẹ̀ jáde.
2 Nítorí OLUWA ń bínú sí gbogbo orílẹ̀-èdè,inú rẹ̀ sì ń ru sí àwọn eniyan ibẹ̀.Ó ti fi wọ́n sílẹ̀ fún ìparun, ó sì ti fà wọ́n kalẹ̀ fún pípa.
3 A óo wọ́ òkú wọn jùnù,òkú wọn yóo máa rùn;ẹ̀jẹ̀ wọn yóo sì máa ṣàn lórí àwọn òkè.
4 Oòrùn, òṣùpá, ati àwọn ìràwọ̀ yóo gbọ̀n dànùa óo ká awọsanma bí ẹni ká ìwé.Oòrùn, òṣùpá, ati àwọn ìràwọ̀ yóo jábọ́bí ewé tií rẹ̀ sílẹ̀ lára ìtàkùn àjàrà,àní, bí ewé tií wọ́ dànù lórí igi ọ̀pọ̀tọ́.
5 Nítorí mo ti rẹkẹ idà mi lókè ọ̀run,yóo sọ̀kalẹ̀ láti ṣe ìdájọ́ àwọn ará Edomu;yóo sọ̀kalẹ̀ sórí àwọn tí mo fẹ́ parun.
6 OLUWA ní idà kan tí a tì bọ inú ẹ̀jẹ̀,a rì í sinu ọ̀rá,pẹlu ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́ aguntan ati ti ewúrẹ́,ati ọ̀rá ara kíndìnrín àgbò.Nítorí pé OLUWA yóo rú ẹbọ ní Bosira,yóo sì pa ọpọlọpọ eniyan ní ilẹ̀ Edomu.
7 Àwọn mààlúù igbó yóo kú pẹlu wọn,bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù ati àwọn akọ mààlúù ńlá.Ilẹ̀ wọn yóo kún fún ẹ̀jẹ̀,ọ̀rá eniyan yóo sì mú kí ilẹ̀ wọn lẹ́tù lójú.
8 Nítorí OLUWA ti ya ọjọ́ kan sọ́tọ̀ fún ẹ̀san,ó ti ya ọdún kan sọ́tọ̀ tí yóo gbèjà Sioni.
9 Àwọn odò ilẹ̀ Edomu yóo di ọ̀dà,erùpẹ̀ rẹ̀ yóo di imí ọjọ́;ilẹ̀ Edomu yóo di ọ̀dà tí ń jó bùlàbùlà.
10 Yóo máa jó tọ̀sán-tòru, kò ní kú,yóo máa rú èéfín sókè títí lae.Yóo di aṣálẹ̀ láti ìrandíran,ẹnikẹ́ni kò ní gbabẹ̀ kọjá mọ́ títí lae.
11 Àṣá ati òòrẹ̀ ni yóo fi ibẹ̀ ṣe ilé,òwìwí ati ẹyẹ kannakánná ni yóo máa gbé ibẹ̀.OLUWA yóo ta okùn ìdàrúdàpọ̀ lé e lórí,yóo sì na ọ̀pá ìdàrúdàpọ̀ lé àwọn ìjòyè rẹ̀ lórí.
12 “Kò sí Ilẹ̀ Ọba Mọ́” ni a óo máa pè é.Gbogbo àwọn ìjòyè rẹ̀ yóo parẹ́.
13 Ẹ̀gún yóo hù ninu ààfin rẹ̀,ẹ̀gún òṣùṣú ati ẹ̀gún ọ̀gàn yóo hù ninu àwọn ìlú olódi rẹ̀.Wọn yóo di ibùgbé fún àwọn ọ̀fàfà ati ẹyẹ ògòǹgò,
14 àwọn ẹranko ìgbẹ́ ati ìkookò yóo jọ máa gbé ibẹ̀,àwọn ewúrẹ́ igbó yóo máa ké pe ara wọn.Iwin yóo rí ibi máa gbé,yóo sì rí ààyè máa sinmi níbẹ̀.
15 Òwìwí yóo pa ìtẹ́ sibẹ, tí yóo máa yé sí.Yóo pamọ, yóo ràdọ̀ bo àwọn ọmọ rẹ̀,yóo sì máa tọ́jú wọn níbẹ̀.Àwọn àṣá yóo péjọ sibẹ,olukuluku wọn, pẹlu ekeji rẹ̀.
16 Ẹ lọ wá inú ìwé OLUWA,kí ẹ ka ohun tí ó wà níbẹ̀.Kò sí ọ̀kan ninu àwọn wọnyi tí kò ní sí níbẹ̀,kò sí èyí tí kò ní ní ẹnìkejì.Nítorí OLUWA ni ó pàṣẹ bẹ́ẹ̀,ẹ̀mí rẹ̀ ni ó sì kó wọn jọ.
17 Ó ti ṣẹ́ gègé fún wọn,ó ti fi okùn wọ̀n ọ́n kalẹ̀ fún wọn.Àwọn ni wọn óo ni ín títí lae,wọn óo sì máa gbé ibẹ̀ láti ìrandíran.