Aisaya 15 BM

OLUWA yóo Pa Moabu Run

1 Ọ̀rọ̀ tí OLUWA sọ nípa ilẹ̀ Moabu nìyí:Nítorí tí a wó ìlú Ari ati Kiri lulẹ̀ ní òru ọjọ́ kan ṣoṣo,ó parí fún Moabu.

2 Àwọn ọmọbinrin Diboni ti gun àwọn ibi pẹpẹ tí wọ́n ti ń bọ̀rìṣà lọ, wọ́n lọ sọkún.Moabu ń pohùnréré ẹkún nítorí Nebo ati Medeba.Gbogbo orí wọn pá, wọ́n sì ti fá gbogbo irùngbọ̀n wọn.

3 Wọ́n da aṣọ ọ̀fọ̀ bora ní ìta gbangba.Gbogbo wọn dúró lórí òrùlé ilé wọn,ati ní gbogbo gbàgede, wọ́n ń pohùnréré ẹkún,omijé sì ń dà lójú wọn.

4 Heṣiboni ati Eleale ń kígbe lóhùn rara,àwọn ará Jahasi gbọ́ ariwo wọn;nítorí náà àwọn ọmọ ogun Moabu sọkún,ọkàn rẹ̀ sì wárìrì.

5 Ọkàn mi sọkún fún Moabu;àwọn ìsáǹsá rẹ̀ sá lọ sí Soari ati Egilati Ṣeliṣiya.Ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Luhiti, wọ́n ń sọkún bí wọ́n ti ń gòkè lọ,wọ́n sì ń kígbe arò bí wọ́n tí ń lọ sí Horonaimu.

6 Àwọn odò Nimrimu di aṣálẹ̀,koríko ibẹ̀ gbẹ;àwọn ohun ọ̀gbìn tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń yọ jóná mọ́lẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni ewé kò rú mọ́.

7 Nítorí náà àwọn ohun tí wọ́n ní lọpọlọpọati ohun ìní tí wọn ti kó jọ,ni wọ́n kó lọ sí ìkọjá odò Wilo.

8 Nítorí ariwo kan ti gba gbogbo ilẹ̀ Moabu kan,ẹkún náà dé Egilaimu,ìpohùnréré náà sì dé Beerelimu.

9 Nítorí odò Diboni kún fún ẹ̀jẹ̀,sibẹsibẹ n óo jẹ́ kí ohun tí ó jù bẹ́ẹ̀ lọ dé bá a.Kinniun ni yóo pa àwọn ará Moabu tí ó bá ń sá lọati àwọn eniyan tí ó bá kù ní ilẹ̀ náà.