12 Ojú rẹ̀ dàbí àwọn àdàbà etí odò,tí a fi wàrà wẹ̀, tí wọ́n tò sí bèbè odò.
13 Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀ dàbí ebè òdòdó olóòórùn dídùn,tí ń tú òórùn dídùn jáde.Ètè rẹ̀ dàbí òdòdó lílì,tí òróró òjíá ń kán níbẹ̀.
14 Ọwọ́ rẹ̀ dàbí ọ̀pá wúrà,tí a to ohun ọ̀ṣọ́ sí lára.Ara rẹ̀ dàbí eyín erin tí ń dántí a fi òkúta safire bò.
15 Ẹsẹ̀ rẹ̀ dàbí òpó alabasitatí a gbé ka orí ìtẹ́lẹ̀ wúrà.Ìrísí rẹ̀ dàbí òkè Lẹbanoni, ó rí gbọ̀ngbọ̀nràn bí igi Kedari.