2 Mo sùn ṣugbọn ọkàn mi kò sùn.Ẹ gbọ́! Olùfẹ́ mi ń kan ìlẹ̀kùn.Ṣílẹ̀kùn fún mi,arabinrin mi, olùfẹ́ mi,àdàbà mi, olùfẹ́ mi tí ó péye,nítorí pé, ìrì ti mú kí orí mi tutù,gbogbo irun mi ti rẹ, fún ìrì alẹ́.
3 Mo ti bọ́ra sílẹ̀,báwo ni mo ṣe lè tún múra?Mo ti fọ ẹsẹ̀ mi,báwo ni mo ṣe lè tún dọ̀tí rẹ̀?
4 Olùfẹ́ mi gbọ́wọ́ lé ìlẹ̀kùn,ọkàn mi sì kún fún ayọ̀.
5 Mo dìde, mo ṣílẹ̀kùn fún olùfẹ́ mi,gbogbo ọwọ́ mi kún fún òjíá,òróró òjíá sì ń kán ní ìka misára kọ́kọ́rọ́ ìlẹ̀kùn.
6 Mo ṣílẹ̀kùn fún olùfẹ́ mi,ṣugbọn ó ti yipada, ó ti lọ.Mo fẹ́rẹ̀ dákú, nígbà tí ó sọ̀rọ̀,mo wá a, ṣugbọn n kò rí i,mo pè é, ṣugbọn kò dáhùn.
7 Àwọn aṣọ́de rí mibí wọ́n ti ń rìn káàkiri ìlú;wọ́n lù mí, wọ́n ṣe mí léṣe,wọ́n sì gba ìborùn mi.
8 Mo rọ̀ yín, ẹ̀yin ọmọbinrin Jerusalẹmu,bí ẹ bá rí olùfẹ́ mi,ẹ bá mi sọ fún un pé:Àìsàn ìfẹ́ ń ṣe mí.