1 Níbo ni olùfẹ́ rẹ lọ,ìwọ, arẹwà jùlọ láàrin àwọn obinrin?Níbo ni olùfẹ́ rẹ yà sí,kí á lè bá ọ wá a?
2 Olùfẹ́ mi ti lọ sinu ọgbà rẹ̀,níbi ebè igi turari,ó da ẹran rẹ̀ lọ sinu ọgbà,ó lọ já òdòdó lílì.
3 Olùfẹ́ mi ló ni mí,èmi ni mo sì ni olùfẹ́ mi.Láàrin òdòdó lílì,ni ó ti ń da ẹran rẹ̀.
4 Olùfẹ́ mi, o dára bíi Tirisa.O lẹ́wà bíi Jerusalẹmu,O níyì bíi ọ̀wọ́ àwọn ọmọ ogun tí ń gbé ọ̀págun.
5 Yíjú kúrò lọ́dọ̀ mi,nítorí wọn kò jẹ́ kí n gbádùn.Irun orí rẹ dàbí ọ̀wọ́ ewúrẹ́ ninu agbo,tí ń sọ̀kalẹ̀ ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Gileadi.
6 Eyín rẹ dàbí ọ̀wọ́ aguntan,tí wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ wẹ̀ tán,gbogbo wọn gún régé,kò sì sí ọ̀kan tí ó yọ ninu wọn,
7 Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ dàbí ìlàjì èso pomegiranate lábẹ́ ìbòjú rẹ.