3 Olùfẹ́ mi ló ni mí,èmi ni mo sì ni olùfẹ́ mi.Láàrin òdòdó lílì,ni ó ti ń da ẹran rẹ̀.
4 Olùfẹ́ mi, o dára bíi Tirisa.O lẹ́wà bíi Jerusalẹmu,O níyì bíi ọ̀wọ́ àwọn ọmọ ogun tí ń gbé ọ̀págun.
5 Yíjú kúrò lọ́dọ̀ mi,nítorí wọn kò jẹ́ kí n gbádùn.Irun orí rẹ dàbí ọ̀wọ́ ewúrẹ́ ninu agbo,tí ń sọ̀kalẹ̀ ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè Gileadi.
6 Eyín rẹ dàbí ọ̀wọ́ aguntan,tí wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ wẹ̀ tán,gbogbo wọn gún régé,kò sì sí ọ̀kan tí ó yọ ninu wọn,
7 Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ dàbí ìlàjì èso pomegiranate lábẹ́ ìbòjú rẹ.
8 Àwọn ayaba ìbáà tó ọgọta,kí àwọn obinrin mìíràn sì tó ọgọrin,kí àwọn iranṣẹbinrin sì pọ̀, kí wọn má lóǹkà,
9 sibẹ, ọ̀kan ṣoṣo ni àdàbà mi, olùfẹ́ mi tí ó péye.Ọmọlójú ìyá rẹ̀,ẹni tí kò ní àbààwọ́n lójú ẹni tí ó bí i.Àwọn iranṣẹbinrin ń pe ìyá rẹ̀ ní olóríire.Àwọn ayaba ati àwọn obinrin mìíràn ní ààfin sì ń yìn ín.