9 sibẹ, ọ̀kan ṣoṣo ni àdàbà mi, olùfẹ́ mi tí ó péye.Ọmọlójú ìyá rẹ̀,ẹni tí kò ní àbààwọ́n lójú ẹni tí ó bí i.Àwọn iranṣẹbinrin ń pe ìyá rẹ̀ ní olóríire.Àwọn ayaba ati àwọn obinrin mìíràn ní ààfin sì ń yìn ín.
10 Ta ni ń yọ bọ̀ bí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ yìí,tí ó mọ́ bí ọjọ́,tí ó lẹ́wà bí òṣùpá.Tí ó sì bani lẹ́rù,bí àwọn ọmọ ogun tí wọn dira ogun?
11 Mo lọ sinu ọgbà igi eléso,mo lọ wo ẹ̀ka igi tútù ní àfonífojì,pé bóyá àwọn àjàrà ti rúwé,ati pé bóyá àwọn igi èso pomegiranate tí ń tanná.
12 Kí n tó fura,ìfẹ́ tí ṣe mí bí ẹni tí ó wà ninu ọkọ̀ ogun,tí ara ń wá bíi kí ó bọ́ sójú ogun.