Samuẹli Keji 15:30 BM

30 Ṣugbọn Dafidi gun gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè olifi lọ, láì wọ bàtà, ó ń sọkún bí ó ti ń lọ, ó sì fi aṣọ bo orí rẹ̀ láti fi ìbànújẹ́ rẹ̀ hàn. Gbogbo àwọn eniyan tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀, tí wọ́n ń bá a lọ náà fi aṣọ bo orí wọn, wọ́n sì ń sọkún bí wọ́n ti ń lọ.

Ka pipe ipin Samuẹli Keji 15

Wo Samuẹli Keji 15:30 ni o tọ