Samuẹli Keji 22 BM

Orin Ìṣẹ́gun Tí Dafidi Kọ

1 Nígbà tí OLUWA gba Dafidi lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ ati lọ́wọ́ Saulu, Dafidi kọ orin yìí sí OLUWA pé:

2 “OLUWA ni àpáta mi,ààbò mi, ati olùgbàlà mi;

3 Ọlọrun mi, àpáta mi,ọ̀dọ̀ ẹni tí mo sá pamọ́ sí.Àpáta mi ati ìgbàlà mi,ààbò mi ati ibi ìpamọ́ mi,olùgbàlà mi, ìwọ ni o gbà mí lọ́wọ́ ìwà ipá.

4 Mo ké pe OLUWA, ẹni tí ìyìn yẹ,Ó sì gbà mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi.

5 “Ikú yí mi káàkiri, bí ìgbì omi;ìparun sì bò mí mọ́lẹ̀ bíi ríru omi;

6 isà òkú ya ẹnu sílẹ̀ dè mí,ewu ikú sì dojú kọ mí.

7 Ninu ìpọ́njú mi, mo ké pe OLUWAmo ké pe Ọlọrun mi,ó gbọ́ ohùn mi láti inú tẹmpili rẹ̀;ó sì tẹ́tí sí igbe mi.

8 “Ayé mì, ó sì wárìrì;ìpìlẹ̀ àwọn ọ̀run sì wárìrì,ó mì tìtì, nítorí ibinu Ọlọrun.

9 Èéfín jáde láti ihò imú rẹ̀,iná ajónirun sì jáde láti ẹnu rẹ̀;ẹ̀yinná tí ó pọ́n rẹ̀rẹ̀ ń ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ jáde.

10 Ó tẹ àwọn ọ̀run ba, ó sì sọ̀kalẹ̀;ìkùukùu tí ó ṣókùnkùn sì wà ní abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀.

11 Ó gun orí Kerubu, ó fò,afẹ́fẹ́ ni ó fi ṣe ìyẹ́ tí ó fi ń fò.

12 Ó fi òkùnkùn bo ara,ìkùukùu tí ó ṣókùnkùn,tí ó sì kún fún omi ni ó fi ṣe ìbòrí.

13 Ẹ̀yinná tí ń jó ń jáde,láti inú ìmọ́lẹ̀ tí ó wà níwájú rẹ̀.

14 “OLUWA sán ààrá láti ọ̀run wá,ayé sì gbọ́ ohùn ọ̀gá ògo.

15 Ó ta ọpọlọpọ ọfà, ó sì tú wọn ká.Ó tan mànàmáná, wọ́n sì ń sá.

16 Ìsàlẹ̀ òkun di gbangba, ìpìlẹ̀ ayé sì ṣí sílẹ̀,nígbà tí OLUWA bá wọn wí,tí ó sì fi ibinu jágbe mọ́ wọn.

17 “OLUWA nawọ́ sílẹ̀ láti òkè wá, ó dì mí mú,ó fà mí jáde kúrò ninu omi jíjìn.

18 Ó gbà mí lọ́wọ́ ọ̀tá mi, tí ó lágbára;ati lọ́wọ́ gbogbo àwọn tí wọ́n kórìíra mi;nítorí pé wọ́n lágbára jù mí lọ.

19 Nígbà tí mo wà ninu ìpọ́njú; wọ́n gbógun tì mí,ṣugbọn OLUWA dáàbò bò mí.

20 Ó ràn mí lọ́wọ́,ó kó mi yọ ninu ewu,ó sì gbà mí là,nítorí pé inú rẹ̀ dùn sí mi.

21 “OLUWA fún mi ní èrè òdodo mi,ó san ẹ̀san fún mi, nítorí pé mo jẹ́ aláìlẹ́bi.

22 Nítorí pé mo pa àwọn òfin OLUWA mọ́,n kò sì ṣe agídí, kí n yipada kúrò lọ́dọ̀ Ọlọrun mi.

23 Mo ti tẹ̀lé gbogbo òfin rẹ̀,n kò sì ṣe àìgbọràn sí àwọn ìlànà rẹ̀.

24 N kò lẹ́bi níwájú rẹ̀,mo sì ti yẹra fún ẹ̀ṣẹ̀ dídá.

25 Nítorí náà ni OLUWA ṣe san án fún mi, gẹ́gẹ́ bí òdodo mi,ati gẹ́gẹ́ bí mo ti jẹ́ mímọ́ níwájú rẹ̀.

26 “OLUWA, ò máa ṣe olóòótọ́ sí gbogbo àwọn tí wọ́n bá hu ìwà òtítọ́ sí ọ;ò sì máa fi ara rẹ hàn bí aláìlẹ́bi, fún gbogbo àwọn tí kò ní ẹ̀bi.

27 Ọlọrun, mímọ́ ni ọ́, sí gbogbo àwọn tí wọ́n bá mọ́,ṣugbọn o kórìíra gbogbo àwọn eniyan burúkú.

28 Ò máa gba àwọn onírẹ̀lẹ̀,o dójú lé àwọn agbéraga, láti rẹ̀ wọ́n sílẹ̀.

29 “OLUWA, ìwọ ni ìmọ́lẹ̀ mi,ìwọ ni o sọ òkùnkùn mi di ìmọ́lẹ̀.

30 Nípa agbára rẹ, mo lè ṣẹgun àwọn ọ̀tá mi,mo sì lè fo odi kọjá.

31 Ní ti Ọlọrun yìí, pípé ni ọ̀nà rẹ̀,òtítọ́ ni ìlérí OLUWA,ó sì jẹ́ apata fun gbogbo àwọn tí wọ́n bá sápamọ́ sábẹ́ ààbò rẹ̀.

32 Ta ni Ọlọrun bí kò ṣe OLUWA?Ta sì ni àpáta ààbò bí kò ṣe Ọlọrun wa?

33 Ọlọrun yìí ni ààbò mi tí ó lágbára,ó mú gbogbo ewu kúrò ní ọ̀nà mi.

34 Ó fún ẹsẹ̀ mi lókun láti sáré bí àgbọ̀nrín,ó sì mú kí n wà ní àìléwu lórí àwọn òkè.

35 Ó kọ́ mi ní ogun jíjà,tóbẹ́ẹ̀ tí mo lè lo ọrun idẹ.

36 “O fún mi ní àpáta ìgbàlà rẹ,ìrànlọ́wọ́ rẹ ni ó sọ mí di ẹni ńlá.

37 Ìwọ ni o kò jẹ́ kí ọwọ́ ọ̀tá tẹ̀ mí,bẹ́ẹ̀ ni o kò jẹ́ kí ẹsẹ̀ mí kí ó yẹ̀.

38 Mo lépa àwọn ọ̀tá mi,mo sì ṣẹgun wọnn kò pada lẹ́yìn wọn títí tí mo fi pa wọ́n run.

39 Mo pa wọ́n run, mo bì wọ́n lulẹ̀;wọn kò sì lè dìde mọ́;wọ́n ṣubú lábẹ́ ẹsẹ̀ mi.

40 Ìwọ ni o fún mi lágbára láti jagun,o jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi rì lábẹ́ mi.

41 O mú kí àwọn ọ̀tá mi sá fún mi,mo sì pa àwọn tí wọ́n kórìíra mi run.

42 Wọ́n wá ìrànlọ́wọ́ káàkiri,ṣugbọn kò sí ẹni tí ó lè gbà wọ́n;wọ́n pe OLUWA,ṣugbọn kò dá wọn lóhùn.

43 Mo fọ́ wọn túútúú, wọ́n sì dàbí erùpẹ̀ ilẹ̀;mo tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀, wọ́n sì dàbí ẹrọ̀fọ̀ lójú títì.

44 “Ìwọ ni o gbà mí lọ́wọ́ ìjà àwọn eniyan mi,o sì mú kí ìjọba mi dúró lórí àwọn orílẹ̀ èdè;àwọn eniyan tí n kò mọ̀ rí di ẹni tí ó ń sìn mí.

45 Àwọn àjèjì ń wólẹ̀ níwájú mi,ẹsẹ̀kẹsẹ̀ tí wọ́n bá ti gbúròó mi, ni wọ́n ń mú àṣẹ mi ṣẹ.

46 Ẹ̀rù ba àwọn àjèjì,wọ́n gbọ̀n jìnnìjìnnì jáde ní ibi ààbò wọn.

47 “OLUWA wà láàyè,ìyìn ni fún àpáta ààbò mi.Ẹ gbé Ọlọrun mi ga,ẹni tíí ṣe àpáta ìgbàlà mi.

48 Ọlọrun ti jẹ́ kí n gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá mi,ó ti tẹ orí àwọn orílẹ̀-èdè ba lábẹ́ mi;

49 ó sì fà mí yọ lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá mi.“OLUWA, ìwọ ni o gbé mi ga ju àwọn ọ̀tá mi lọ,o sì dáàbò bò mí, lọ́wọ́ àwọn oníwà ipá.

50 Nítorí náà, n óo máa yìn ọ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè,n óo máa kọ orin ìyìn sí orúkọ rẹ.

51 Ọlọrun fi ìṣẹ́gun ńlá fún ọba rẹ̀,ó sì fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ han ẹni tí ó fi àmì òróró yàn,àní Dafidi ati arọmọdọmọ rẹ̀ laelae!”

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24