1 Ní ọjọ́ kan, Dafidi bèèrè pé, “Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni kù ninu gbogbo ìdílé Saulu tí mo lè ṣoore fún nítorí Jonatani?”
2 Ọkunrin kan wà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Siba, tí ó ti jẹ́ ọ̀kan ninu àwọn iranṣẹ Saulu nígbà ayé rẹ̀. Wọ́n pè é wá fún Dafidi, Dafidi sì bi í pé, “Ṣé ìwọ ni Siba?”Siba dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, oluwa mi, èmi ni.”
3 Ọba tún bi í pé, “Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni kù ninu ìdílé Saulu, tí mo lè fi àánú Ọlọrun hàn, gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣèlérí fún Ọlọrun pé n óo ṣe?”Siba dá a lóhùn pé, “Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ Jonatani wà láàyè, ṣugbọn arọ ni.”
4 Ọba bi í pé, “Níbo ni ó wà?”Siba dá ọba lóhùn pé, “Ó wà ní ilé Makiri, ọmọ Amieli, ní Lodebari.”
5 Dafidi ọba bá ranṣẹ lọ mú un lati ilé Makiri ọmọ Amieli, ní Lodebari.
6 Nígbà tí Mẹfiboṣẹti, ọmọ Jonatani, tíí ṣe ọmọ ọmọ Saulu dé, ó wólẹ̀ níwájú Dafidi, ó sì kí i tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Dafidi pè é, ó ní, “Mẹfiboṣẹti!” ó sì dá a lóhùn pé, “Èmi, iranṣẹ rẹ nìyí.”
7 Dafidi wí fún un pé, “Má bẹ̀rù, oore ni mo fẹ́ ṣe ọ́ nítorí Jonatani baba rẹ. Gbogbo ilẹ̀ tí ó ti jẹ́ ti Saulu baba baba rẹ rí, ni n óo dá pada fún ọ, a óo sì jọ máa jẹun lórí tabili mi nígbà gbogbo.”
8 Mẹfiboṣẹti tún wólẹ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, ó ní, “Kí ni èmi iranṣẹ rẹ fi sàn ju òkú ajá lọ, kí ló dé tí o fi ṣe mí ní oore tí ó tó báyìí?”
9 Ọba bá pe Siba, iranṣẹ Saulu, ó wí fún un pé, “Gbogbo ohun tí ó jẹ́ ti Saulu, ọ̀gá rẹ tẹ́lẹ̀, ati ti gbogbo ìdílé rẹ̀, ni n óo dá pada fún Mẹfiboṣẹti ọmọ ọmọ rẹ̀.
10 Ìwọ, àwọn ọmọ rẹ, ati àwọn iranṣẹ rẹ, ni ẹ óo máa ro gbogbo oko Saulu; ẹ ó máa kórè àwọn ohun ọ̀gbìn tí ẹ bá gbìn, kí ọmọ oluwa yín lè ní oúnjẹ tó, ṣugbọn Mẹfiboṣẹti alára, yóo máa wá jẹun lórí tabili mi nígbà gbogbo.” Àwọn ọmọkunrin tí Siba ní nígbà náà jẹ́ mẹẹdogun, àwọn iranṣẹ rẹ̀ sì jẹ́ ogún.
11 Siba dáhùn pé, gbogbo ohun tí ọba pa láṣẹ ni òun yóo ṣe.Mẹfiboṣẹti bá bẹ̀rẹ̀ sí jẹun lórí tabili ọba, gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan ninu àwọn ọmọ ọba.
12 Ó ní ọdọmọkunrin kan, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mika. Gbogbo àwọn ará ilé Siba sì di iranṣẹ Mẹfiboṣẹti.
13 Bẹ́ẹ̀ ni Mẹfiboṣẹti, ẹni tí ẹsẹ̀ rẹ̀ mejeeji ti rọ ṣe bẹ̀rẹ̀ sí gbé Jerusalẹmu, ó sì ń jẹun lọ́dọ̀ ọba nígbà gbogbo.