1 Lẹ́yìn èyí, ni Nahaṣi, ọba Amoni kú, Hanuni, ọmọ rẹ̀ sì gorí oyè.
2 Dafidi ọba wí pé, “N óo ṣe ẹ̀tọ́ fún Hanuni, ọmọ Nahaṣi gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀ ti ṣe ẹ̀tọ́ fún mi.” Dafidi bá rán oníṣẹ́ lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ láti tù ú ninu, nítorí ikú baba rẹ̀.Nígbà tí àwọn oníṣẹ́ Dafidi dé Amoni,
3 àwọn àgbààgbà ìlú náà wí fún Hanuni ọba wọn pé, “Ṣé o rò pé baba rẹ ni Dafidi bu ọlá fún tóbẹ́ẹ̀, tí ó fi rán àwọn oníṣẹ́ láti wá tù ọ́ ninu? Rárá o! Amí ni ó rán wọn wá ṣe, kí wọ́n lè wo gbogbo ìlú wò, kí ó baà lè ṣẹgun wa.”
4 Hanuni bá ki àwọn oníṣẹ́ Dafidi mọ́lẹ̀, ó fá apá kan irùngbọ̀n ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn, ó gé aṣọ wọn ní déédé ìbàdí, ó sì tì wọ́n jáde.
5 Ìtìjú bá wọn tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí wọn kò lè pada sílé. Nígbà tí Dafidi gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wọn, ó ranṣẹ sí wọn pé kí wọ́n dúró ní Jẹriko títí tí irùngbọ̀n wọn yóo fi hù, kí wọ́n tó máa pada bọ̀.
6 Nígbà tí àwọn ará Amoni rí i pé àwọn ti di ọ̀tá Dafidi, wọ́n ranṣẹ lọ fi owó gba ọ̀kẹ́ kan (20,000) jagunjagun ninu àwọn ará Siria tí wọ́n ń gbé Betirehobu ati Soba. Wọ́n gba ẹgbẹrun (1,000) lọ́dọ̀ ọba Maaka ati ẹgbaafa (12,000) ninu àwọn ará Tobu.
7 Nígbà tí Dafidi gbọ́, ó rán Joabu ati gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀, láti lọ gbógun tì wọ́n.
8 Àwọn ará Amoni jáde sí àwọn ọmọ ogun Israẹli, wọ́n tò sí ẹnubodè wọn ní Raba, tíí ṣe olú ìlú wọn. Gbogbo àwọn ọmọ ogun, ará Siria tí wọ́n wá láti Soba ati Rehobu, ati àwọn ará Tobu ati ti Maaka, àwọn dá dúró ninu pápá.
9 Nígbà tí Joabu rí i pé àwọn ọ̀tá yóo gbógun ti àwọn níwájú ati lẹ́yìn, ó yan àwọn tí wọ́n jẹ́ akikanju jùlọ ninu àwọn ọmọ ogun Israẹli, ó ní kí wọ́n dojú kọ àwọn ará Siria.
10 Ó sì kó gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ yòókù sábẹ́ ọ̀gágun Abiṣai, tí ó jẹ́ arakunrin rẹ̀, Abiṣai bá fi olukuluku sí ipò rẹ̀, wọ́n dojú kọ àwọn ará Amoni.
11 Joabu wí fún un pé, “Bí o bá rí i pé àwọn ará Siria fẹ́ ṣẹgun mi, wá ràn mí lọ́wọ́. Bí èmi náà bá sì rí i pé àwọn ará Amoni fẹ́ ṣẹgun rẹ, n óo wá ràn ọ́ lọ́wọ́.
12 Múra gírí, jẹ́ kí á fi gbogbo agbára wa jà fún àwọn eniyan wa ati fún ìlú Ọlọrun wa. Kí OLUWA wa ṣe èyí tí ó dára lójú rẹ̀.”
13 Joabu ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ tẹ̀síwájú láti gbógun ti àwọn ará Siria, àwọn ará Siria sì sá.
14 Nígbà tí àwọn ará Amoni rí i pé àwọn ará Siria ń sá lọ, àwọn náà sá fún Abiṣai, wọ́n sì pada sinu ìlú. Joabu bá pada lẹ́yìn àwọn ará Amoni, ó sì lọ sí Jerusalẹmu.
15 Nígbà tí àwọn ará Siria rí i pé, àwọn ọmọ ogun Israẹli ti ṣẹgun àwọn, wọ́n kó gbogbo àwọn ọmọ ogun wọn jọ.
16 Hadadeseri ọba, bá ranṣẹ sí àwọn ará Siria tí wọ́n wà ní ìhà ìlà oòrùn odò Yufurate, wọ́n bá wá sí Helamu. Ṣobaki tí ó jẹ́ balogun àwọn ọmọ ogun Hadadeseri, ni aṣiwaju wọn.
17 Nígbà tí Dafidi gbọ́, ó kó gbogbo àwọn ọmọ ogun Israẹli jọ, ó la odò Jọdani kọjá lọ sí Helamu. Olukuluku àwọn ará Siria dúró ní ipò wọn, wọ́n dojú kọ Dafidi, wọ́n sì bá a jagun.
18 Àwọn ọmọ ogun Israẹli lé àwọn ọmọ ogun Siria pada, Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ pa ẹẹdẹgbẹrin (700) ninu àwọn tí wọ́n gun kẹ̀kẹ́ ogun Siria, ati ọ̀kẹ́ meji (40,000) ninu àwọn ẹlẹ́ṣin wọn. Wọ́n ṣá Ṣobaki tí ó jẹ́ balogun wọn lọ́gbẹ́, ó sì kú sójú ogun.
19 Nígbà tí àwọn ọba tí wọ́n wà lẹ́yìn Hadadeseri rí i pé, àwọn ọmọ Israẹli ti ṣẹgun àwọn, wọ́n bá Israẹli làjà, wọ́n sì ń sìn wọ́n. Láti ìgbà náà ni ẹ̀rù sì ti ń ba àwọn ará Siria láti ran àwọn ará Amoni lọ́wọ́.