Samuẹli Keji 3 BM

1 Àwọn tí wọ́n wà lẹ́yìn ìdílé Saulu, ati àwọn tí wọ́n wà lẹ́yìn ìdílé Dafidi bá ara wọn jagun fún ìgbà pípẹ́. Bí agbára Dafidi ti ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ ni agbára àwọn tí wọ́n wà lẹ́yìn Saulu ń dínkù.

Àwọn Ọmọ Dafidi

2 Ọmọkunrin mẹfa ni wọ́n bí fún Dafidi nígbà tí ó wà ní Heburoni. Aminoni tí ìyá rẹ̀ ń jẹ́ Ahinoamu, ará Jesireeli, ni àkọ́bí.

3 Ekeji ni Kileabu, ọmọ Abigaili, opó Nabali, ará Kamẹli. Ẹkẹta ni Absalomu, ọmọ Maaka, ọmọ Talimai, ọba Geṣuri.

4 Ẹkẹrin ni Adonija ọmọ Hagiti. Ẹkarun-un ni Ṣefataya ọmọ Abitali.

5 Ẹkẹfa sì ni Itireamu, ọmọ Egila. Heburoni ni wọ́n ti bí àwọn ọmọ náà fún Dafidi.

Abineri Darapọ̀ Mọ́ Dafidi

6 Ní àkókò tí ogun wà láàrin àwọn eniyan Dafidi ati àwọn eniyan Saulu, agbára Abineri bẹ̀rẹ̀ sí pọ̀ sí i láàrin àwọn tí wọ́n wà lẹ́yìn Saulu.

7 Ní ọjọ́ kan, Iṣiboṣẹti ọmọ Saulu fi ẹ̀sùn kan Abineri pé ó bá obinrin Saulu kan, tí wọn ń pè ní Risipa, ọmọ Aya, lòpọ̀.

8 Ọ̀rọ̀ náà bí Abineri ninu gidigidi, ó bi Iṣiboṣẹti pé, “Ṣé o rò pé mo jẹ́ hu ìwà ọ̀dàlẹ̀ sí Saulu laelae? Àbí ẹ̀yìn àwọn ará Juda ni ẹ rò pé mo wà ni? Láti ìbẹ̀rẹ̀ ni mo ti jẹ́ olóòótọ́ sí Saulu baba rẹ, àwọn arakunrin rẹ̀ ati àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, èmi ni n kò sì ti jẹ́ kí apá Dafidi ká ọ. Ṣugbọn lónìí ńkọ́, ò ń fi ẹ̀sùn kàn mí nípa obinrin.

9 Kí Ọlọrun lù mí pa, bí n kò bá ṣe gbogbo ohun tí ó wà ní ìkáwọ́ mi, láti mú ìlérí tí OLUWA ṣe fún Dafidi ṣẹ,

10 pé, òun yóo gba ìjọba kúrò lọ́wọ́ ìdílé Saulu, yóo sì fi Dafidi jọba lórí Juda jákèjádò, láti Dani títí dé Beeriṣeba.”

11 Iṣiboṣẹti kò sì lè dá Abineri lóhùn nítorí ó bẹ̀rù rẹ̀.

12 Abineri bá ranṣẹ sí Dafidi ní Heburoni pé, “Ṣebí ìwọ ni o ni ilẹ̀ yìí? Bá mi dá majẹmu, n óo wà lẹ́yìn rẹ, n óo sì mú kí gbogbo Israẹli pada sọ́dọ̀ rẹ.”

13 Dafidi bá dáhùn pé, “Ó dára, n óo bá ọ dá majẹmu. Ṣugbọn nǹkankan ni mo fẹ́ kí o ṣe, o kò ní fi ojú kàn mí, àfi bí o bá mú Mikali ọmọbinrin Saulu lọ́wọ́ nígbà tí o bá ń bọ̀ wá rí mi.”

14 Dafidi bá rán àwọn oníṣẹ́ kan sí Iṣiboṣẹti, ọmọ Saulu, pé kí ó dá Mikali, aya òun, tí òun san ọgọrun-un awọ orí adọ̀dọ́ àwọn ará Filistia lé lórí pada fún òun.

15 Iṣiboṣẹti bá ranṣẹ lọ gba Mikali lọ́wọ́ Palitieli, ọmọ Laiṣi, ọkọ rẹ̀.

16 Ṣugbọn bí ó ti ń lọ ni ọkọ rẹ̀ ń sọkún tẹ̀lé e títí tí ó fi dé Bahurimu, ibẹ̀ ni Abineri ti dá a pada, ó sì pada.

17 Abineri tọ àwọn àgbààgbà Israẹli lọ, ó ní, “Ó pẹ́ tí ẹ ti fẹ́ kí Dafidi jẹ́ ọba yín.

18 Àkókò nìyí láti ṣe ohun tí ẹ ti fẹ́ ṣe, nítorí pé OLUWA ti ṣe ìlérí fún Dafidi pé Dafidi ni òun óo lò láti gba àwọn ọmọ Israẹli kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Filistia ati gbogbo àwọn ọ̀tá wọn yòókù.”

19 Abineri bá àwọn ará Bẹnjamini sọ̀rọ̀ pẹlu. Lẹ́yìn náà ó lọ bá Dafidi ní Heburoni láti sọ ohun tí àwọn ará Bẹnjamini ati gbogbo ọmọ Israẹli ti gbà láti ṣe fún Dafidi.

20 Nígbà tí Abineri dé ọ̀dọ̀ Dafidi ní Heburoni pẹlu ogún ọkunrin tí ń bá a lọ, Dafidi se àsè ńlá fún wọn.

21 Abineri bá sọ fún Dafidi pé, “N óo lọ, n óo wá ọ̀nà tí gbogbo Israẹli yóo fi wà lẹ́yìn rẹ, oluwa mi, (ọba), tí wọn yóo bá ọ dá majẹmu tí o óo sì jọba lórí gbogbo ibi tí ọkàn rẹ bá fẹ́.” Dafidi ní kí ó máa lọ, ó sì lọ ní alaafia.

Wọ́n Pa Abineri

22 Kò pẹ́ pupọ lẹ́yìn náà, ni Joabu ati àwọn ọmọ ogun Dafidi pada dé láti ibi tí wọ́n ti lọ ja ogun kan, wọ́n sì kó ọpọlọpọ ìkógun bọ̀. Ṣugbọn Abineri kò sí lọ́dọ̀ Dafidi, ní Heburoni, nígbà tí wọ́n dé, nítorí pé Dafidi ti ní kí ó máa pada lọ, ó sì ti lọ ní alaafia.

23 Nígbà tí Joabu ati àwọn ọmọ ogun tí wọ́n tẹ̀lé e dé, wọ́n sọ fún Joabu pé, “Abineri ti wá sí ọ̀dọ̀ Dafidi ọba, ọba sì ti jẹ́ kí ó lọ ní alaafia.”

24 Joabu bá lọ sí ọ̀dọ̀ ọba, ó bèèrè pé, “Irú kí ni o ṣe yìí, Abineri wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, o sì jẹ́ kí ó lọ bẹ́ẹ̀?

25 Ṣebí o mọ̀ pé ó wá tàn ọ́ jẹ ni? Ó wá fi ọgbọ́n wádìí gbogbo ibi tí ò ń lọ, ati gbogbo ohun tí ò ń ṣe ni.”

26 Nígbà tí Joabu kúrò lọ́dọ̀ Dafidi, ó ranṣẹ lọ pe Abineri, wọ́n sì dá a pada láti ibi kànga Sira, ṣugbọn Dafidi kò mọ nǹkankan nípa rẹ̀.

27 Nígbà tí Abineri pada dé Heburoni, Joabu mú un lọ sí kọ̀rọ̀ kan, níbi ẹnubodè, bí ẹni pé ó fẹ́ bá a sọ ọ̀rọ̀ àṣírí, Joabu bá fi nǹkan gún un ní ikùn. Bẹ́ẹ̀ ni Abineri ṣe kú, nítorí pé ó pa Asaheli arakunrin Joabu.

28 Nígbà tí Dafidi gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ó ní, “OLUWA mọ̀ pé, èmi ati àwọn eniyan mi kò lọ́wọ́ sí ikú Abineri rárá, ọwọ́ wa mọ́ patapata ninu ọ̀ràn náà.

29 Orí Joabu ati ìdílé baba rẹ̀ ni ẹ̀bi ìjìyà ikú yìí yóo dà lé. Láti ìrandíran rẹ̀, kò ní sí ẹnikẹ́ni tí kò ní kó àtọ̀sí, tabi kí ó ní àrùn ẹ̀tẹ̀, tabi tí kò ní jẹ́ pé iṣẹ́ obinrin nìkan ni wọn yóo lè ṣe, tabi kí wọ́n pa wọ́n lójú ogun, tabi kí wọ́n máa tọrọ jẹ.”

30 Bẹ́ẹ̀ ni Joabu ati Abiṣai, arakunrin rẹ̀, ṣe pa Abineri tí wọ́n sì gbẹ̀san ikú Asaheli, arakunrin wọn, tí Abineri pa lójú ogun Gibeoni.

Wọ́n Sin Òkú Abineri

31 Dafidi pàṣẹ pé kí Joabu ati àwọn tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀ fa aṣọ wọn ya, kí wọ́n wọ aṣọ ọ̀fọ̀, kí wọ́n sì ṣọ̀fọ̀ Abineri. Nígbà tí ó tó àkókò láti sìnkú Abineri, Dafidi ọba pàápàá tẹ̀lé òkú rẹ̀.

32 Heburoni ni wọ́n sin òkú Abineri sí, ọba sọkún létí ibojì rẹ̀, gbogbo àwọn eniyan sì sọkún pẹlu.

33 Dafidi kọ orin arò kan fún Abineri báyìí pé:“Kí ló dé tí Abineri fi kú bí aṣiwèrè?

34 Wọn kò dì ọ́ lọ́wọ́,bẹ́ẹ̀ ni wọn kò dì ọ́ lẹ́sẹ̀;o ṣubú bí ìgbà tí eniyan ṣubú níwájú ìkà.”Gbogbo eniyan sì tún bú sẹ́kún.

35 Gbogbo eniyan rọ Dafidi, pé kí ó jẹun ní ọ̀sán ọjọ́ náà ṣugbọn ó búra pé kí Ọlọrun pa òun bí òun bá fi ẹnu kan nǹkankan títí tí ilẹ̀ yóo fi ṣú.

36 Gbogbo àwọn eniyan ṣe akiyesi ohun tí ọba ṣe yìí, ó sì dùn mọ́ wọn. Gbogbo ohun tí ọba ṣe patapata ni ó dùn mọ́ àwọn eniyan.

37 Gbogbo àwọn eniyan Dafidi, ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ni ó hàn sí gbangba pé, ọba kò lọ́wọ́ ninu pípa tí wọ́n pa Abineri.

38 Ọba bi àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé, “Ṣé ẹ kò mọ̀ pé eniyan ńlá, ati alágbára kan ni ó ṣubú lónìí, ní ilẹ̀ Israẹli?”

39 Ó ní, “Agbára mi dínkù lónìí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òróró ni a fi yàn mí ní ọba. Ìwà ipá àwọn ọmọ Seruaya yìí ti le jù fún mi. OLUWA nìkan ni ó lè san ẹ̀san fún eniyan burúkú gẹ́gẹ́ bí ìwà ìkà rẹ̀.”

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24