1 Lẹ́yìn náà, gbogbo àwọn ẹ̀yà Israẹli tọ Dafidi lọ ní Heburoni, wọ́n sọ fún un pé, “Ara kan náà ni wá, ẹ̀jẹ̀ kan náà sì ni gbogbo wa.
2 Látẹ̀yìn wá, nígbà tí Saulu pàápàá wà lórí oyè, ìwọ ni o máa ń kó àwọn ọmọ Israẹli lọ sógun. OLUWA sì ti ṣèlérí fún ọ pé, ìwọ ni o óo jẹ́ aṣiwaju àwọn eniyan rẹ̀, ati ọba wọn.”
3 Gbogbo àwọn àgbààgbà Israẹli wá sí ọ̀dọ̀ ọba ní Heburoni, Dafidi ọba sì bá wọn dá majẹmu níbẹ̀ níwájú OLUWA. Wọ́n bá fi òróró yan Dafidi ní ọba lórí Israẹli.
4 Ẹni ọgbọ̀n ọdún ni, nígbà tí ó gorí oyè, ó sì jọba fún ogoji ọdún.
5 Ọdún meje ati oṣù mẹfa ni ó fi jọba lórí ẹ̀yà Juda ní Heburoni. Lẹ́yìn náà, ó wá sí Jerusalẹmu ó sì jọba lórí gbogbo Israẹli ati Juda fún ọdún mẹtalelọgbọn.
6 Nígbà tí ó yá, Dafidi ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ gbógun ti ìlú Jerusalẹmu. Àwọn ará Jebusi tí wọn ń gbé ibẹ̀ nígbà náà wí fún Dafidi pé, “O kò lè wọ inú ìlú yìí wá, àwọn afọ́jú ati àwọn arọ lásán ti tó láti lé ọ dànù.” Wọ́n lérò pé Dafidi kò le ṣẹgun ìlú náà.
7 Ṣugbọn Dafidi jagun gba Sioni, ìlú olódi wọn. Sioni sì di ibi tí wọn ń pè ní ìlú Dafidi.
8 Dafidi bá sọ fún àwọn eniyan rẹ̀ ní ọjọ́ náà pé, “Jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ pa àwọn ará Jebusi gba ojú àgbàrá lọ pa àwọn afọ́jú ati àwọn arọ tí ọkàn Dafidi kórìíra.” (Ìdí nìyí tí wọ́n fi ń wí pé, “Àwọn afọ́jú ati àwọn arọ kò ní lè wọ ilé OLUWA.”)
9 Lẹ́yìn tí Dafidi ti ṣẹgun ìlú olódi náà, ó ń gbé inú rẹ̀, ó sì yí orúkọ ibẹ̀ pada sí “Ìlú Dafidi”. Ó kọ́ ìlú náà yíká, bẹ̀rẹ̀ láti Milo, níbi tí wọ́n ti kún ilẹ̀ ní ìhà ìwọ̀ oòrùn òkè náà.
10 Agbára Dafidi bẹ̀rẹ̀ sí pọ̀ sí i, nítorí pé OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun wà pẹlu rẹ̀.
11 Hiramu ọba Tire rán àwọn oníṣẹ́ sí Dafidi. Ó fi igi Kedari ranṣẹ sí i, pẹlu àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà, ati àwọn tí wọn ń fi òkúta kọ́ ilé, pé kí wọ́n lọ kọ́ ààfin Dafidi.
12 Dafidi wá mọ̀ pé, OLUWA ti fi ìdí òun múlẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ọba Israẹli, ó sì ti gbé ìjọba òun ga, nítorí Israẹli, àwọn eniyan rẹ̀.
13 Nígbà tí Dafidi kúrò ní Heburoni lọ sí Jerusalẹmu, ó fẹ́ àwọn obinrin mìíràn kún àwọn aya rẹ̀. Ó sì ní ọpọlọpọ ọmọ sí i, lọkunrin ati lobinrin.
14 Orúkọ àwọn tí wọ́n bí fún un ní Jerusalẹmu nìwọ̀nyí: Ṣamua ati Ṣobabu, Natani, ati Solomoni;
15 Ibihari ati Eliṣua, Nefegi ati Jafia;
16 Eliṣama, Eliada, ati Elifeleti.
17 Nígbà tí àwọn ará Filistia gbọ́ pé wọ́n ti fi Dafidi jọba Israẹli, gbogbo àwọn ọmọ ogun wọn jáde lọ láti mú un, ṣugbọn Dafidi gbọ́ pé wọ́n ń bọ̀ wá mú òun, ó bá lọ sí ibi ààbò.
18 Nígbà tí àwọn ará Filistia dé ibi àfonífojì Refaimu, wọ́n dúró níbẹ̀.
19 Dafidi bi OLUWA pé, “Ṣé kí n kọlu àwọn ará Filistia, ṣé o óo fún mi ní ìṣẹ́gun lórí wọn?”OLUWA dá a lóhùn pé, “Kọlù wọ́n, n óo fún ọ ní ìṣẹ́gun lórí wọn.”
20 Dafidi bá wá sí Baali Perasimu, ó sì ṣẹgun àwọn ará Filistia níbẹ̀. Ó ní, “Bí ìkún omi tí í ya bèbè rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni OLUWA fọ́n àwọn ọ̀tá mi ká níwájú mi.” Ó bá pe orúkọ ibẹ̀ ní Baali Perasimu.
21 Níbi tí àwọn ará Filistia ti ń sá lọ, wọ́n gbàgbé àwọn oriṣa wọn sílẹ̀, Dafidi ati àwọn eniyan rẹ̀ sì kó wọn lọ.
22 Àwọn ará Filistia pada, wọ́n tún dúró sí àfonífojì Refaimu.
23 Dafidi tún tọ OLUWA lọ láti bèèrè ohun tí yóo ṣe. OLUWA dá a lóhùn pé, “Má ṣe kọlù wọ́n níhìn-ín, ṣugbọn múra, kí o yípo lọ sẹ́yìn wọn, kí o sì kọlù wọ́n ní apá òdìkejì àwọn igi basamu.
24 Nígbà tí o bá gbọ́ ìró kan, tí ó bá dàbí ẹni pé, eniyan ń fi ẹsẹ̀ kilẹ̀ lọ lórí àwọn igi, ni kí o tó kọlù wọ́n, nítorí pé, OLUWA ti kọjá lọ níwájú rẹ láti ṣẹgun àwọn ọmọ ogun Filistini.”
25 Dafidi ṣe gbogbo ohun tí OLUWA pa láṣẹ fún un, ó sì pa àwọn ọmọ ogun Filistini láti Geba títí dé Geseri.