Samuẹli Keji 18 BM

Wọ́n Ṣẹgun Absalomu, Wọ́n sì Pa Á

1 Dafidi kó gbogbo ọmọ ogun rẹ̀ jọ, ó pín wọn ní ọgọọgọrun-un (100) ati ẹgbẹẹgbẹrun (1,000), ó fi balogun kọ̀ọ̀kan ṣe olórí ìsọ̀rí kọ̀ọ̀kan.

2 Lẹ́yìn náà, ó rán wọn jáde ní ìpín mẹta, ó fi Joabu, ati Abiṣai, ọmọ Seruaya, àbúrò Joabu, ati Itai, ará Gati, ṣe ọ̀gágun àgbà ìpín kọ̀ọ̀kan. Ó ní òun pàápàá yóo bá wọn lọ.

3 Ṣugbọn wọ́n dá a lóhùn pé, “O kò ní bá wa lọ, nítorí pé bí a bá sá lójú ogun ní tiwa, tabi tí ìdajì ninu wa bá kú, kò jẹ́ ohunkohun fún àwọn ọ̀tá wa. Ṣugbọn ìwọ nìkan ju ẹgbaarun (10,000) wa lọ. Ohun tí ó dára ni pé kí o dúró ní ìlú, kí o sì máa fi nǹkan ranṣẹ sí wa láti fi ràn wá lọ́wọ́.”

4 Ọba dáhùn pé, “Ohunkohun tí ẹ bá ní kí n ṣe náà ni n óo ṣe.” Ọba bá dúró ní ẹnu ibodè, bí àwọn ọmọ ogun rẹ̀ tí ń tò kọjá lọ ní ọgọọgọrun-un (100) ati ẹgbẹẹgbẹrun (1,000).

5 Ó pàṣẹ fún Joabu, ati Abiṣai, ati Itai, ó ní, “Nítorí tèmi, ẹ má pa Absalomu lára.” Gbogbo àwọn ọmọ ogun sì gbọ́ nígbà tí Dafidi ń pa àṣẹ yìí fún àwọn ọ̀gágun rẹ̀.

6 Àwọn ọmọ ogun náà bá jáde lọ sinu pápá láti bá àwọn ọmọ ogun Israẹli jà, ní aṣálẹ̀ Efuraimu.

7 Àwọn ọmọ ogun Dafidi ṣẹgun àwọn ọmọ ogun Israẹli. Wọ́n pa wọ́n ní ìpakúpa ní ọjọ́ náà. Àwọn tí wọ́n kú lára wọn jẹ́ ọ̀kẹ́ kan (20,000).

8 Ogun náà tàn káàkiri gbogbo agbègbè; àwọn tí wọ́n sì sọnù sinu igbó pọ̀ ju àwọn tí wọ́n fi idà pa lójú ogun lọ.

9 Lójijì, Absalomu já sí ààrin àwọn ọmọ ogun Dafidi. Ìbaaka ni Absalomu gùn. Ìbaaka yìí gba abẹ́ ẹ̀ka igi Oaku ńlá kan, ẹ̀ka igi yìí sì dí tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi kọ́ Absalomu ní irun orí, Ìbaaka yọ lọ lábẹ́ rẹ̀, Absalomu sì ń rọ̀ dirodiro nítorí pé ẹsẹ̀ rẹ̀ kò tólẹ̀.

10 Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ ogun Dafidi rí i, ó bá lọ sọ fún Joabu pé òun rí Absalomu tí ó ń rọ̀ lórí igi Oaku.

11 Joabu dá a lóhùn pé, “Nígbà tí o rí i, kí ló dé tí o kò pa á níbẹ̀ lẹsẹkẹsẹ? Inú mi ìbá dùn láti fún ọ ní owó fadaka mẹ́wàá ati ìgbànú akikanju ninu ogun jíjà.”

12 Ṣugbọn ọmọ ogun náà dáhùn pé, “Ò báà tilẹ̀ fún mi ní ẹgbẹrun (1,000) owó fadaka, n kò ní ṣíwọ́ sókè pa ọmọ ọba. Gbogbo wa ni a gbọ́, nígbà tí ọba pàṣẹ fún ìwọ ati Abiṣai ati Itai pé, nítorí ti òun ọba, kí ẹ má pa Absalomu lára.

13 Tí mo bá ṣe àìgbọràn sí òfin ọba, tí mo sì pa Absalomu, ó pẹ́ ni, ó yá ni, ọba yóo gbọ́, bí ọba bá sì gbọ́, ìwọ gan-an kò ní gbà mí sílẹ̀.”

14 Joabu dáhùn pé, “N kò ní máa fi àkókò mi ṣòfò, kí n sọ pé mò ń bá ọ sọ̀rọ̀.” Joabu bá mú ọ̀kọ̀ mẹta, ó sọ wọ́n lu Absalomu ní igbá àyà lórí igi oaku tí ó há sí.

15 Mẹ́wàá ninu àwọn ọdọmọkunrin tí wọn ń ru ihamọra Joabu bá yí Absalomu po, wọ́n sì ṣá a pa.

16 Lẹ́yìn náà, Joabu fọn fèrè ogun, kí wọ́n dáwọ́ ogun jíjà dúró. Àwọn ọmọ ogun Dafidi bá pada lẹ́yìn àwọn ọmọ ogun Israẹli.

17 Wọ́n gbé òkú Absalomu jù sinu ihò jíjìn kan ninu igbó, wọ́n sì kó ọpọlọpọ òkúta jọ sórí òkú rẹ̀. Gbogbo àwọn ọmọ ogun Israẹli bá sá, olukuluku gba ilé rẹ̀ lọ.

18 Nígbà ayé Absalomu, ó ṣe ọ̀wọ̀n ìrántí kan fún ara rẹ̀ ní àfonífojì ọba, nítorí kò ní ọmọkunrin kankan tí ó le gbé orúkọ rẹ̀ ró. Nítorí náà ni ó ṣe sọ ọ̀wọ̀n náà ní orúkọ ara rẹ̀; ọ̀wọ̀n Absalomu ni wọ́n ń pe ọ̀wọ̀n náà, títí di òní olónìí.

Wọ́n Túfọ̀ Ikú Absalomu fún Dafidi

19 Ahimaasi, ọmọ Sadoku bá sọ fún Joabu pé, “Jẹ́ kí n sáré tọ ọba lọ, kí n sì fún un ní ìròyìn ayọ̀ náà, pé OLUWA ti gbà á lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀.”

20 Ṣugbọn Joabu dá a lóhùn pé, “Rárá o, kì í ṣe ìwọ ni o óo mú ìròyìn náà lọ lónìí, bí ó bá di ọjọ́ mìíràn, o lè mú ìròyìn ayọ̀ lọ. Kì í ṣe òní, nítorí pé ọmọ ọba ni ó kú.”

21 Joabu bá sọ fún ọ̀kan ninu àwọn ará Kuṣi pé, “Lọ sọ ohun tí o rí fún ọba.” Ará Kuṣi náà bá tẹríba fún Joabu, ó sì sáré lọ.

22 Ṣugbọn Ahimaasi ṣá tẹnu mọ́ ọn pé, “N kò kọ ohunkohun tí ó lè ṣẹlẹ̀, jọ̀wọ́ jẹ́ kí n sáré tẹ̀lé ará Kuṣi náà lọ.”Joabu bi í pé, “Kí ló dé tí o fi fẹ́ lọ, ọmọ mi? Kò sí èrè kankan fún ọ níbẹ̀.”

23 Ahimaasi dáhùn pé, “Mo ṣá fẹ́ lọ ni, ohun yòówù tí ó lè ṣẹlẹ̀.”Joabu dáhùn pé, “Ǹjẹ́ bí o bá fẹ́, máa lọ.” Ahimaasi bá sáré gba ọ̀nà pẹ̀tẹ́lẹ̀ lọ, ó sì ṣáájú ará Kuṣi náà.

24 Dafidi wà ní àlàfo tí ó wà ní ààrin ẹnu ọ̀nà tinú ati ti òde, ní ẹnu ibodè ìlú. Ẹ̀ṣọ́ tí ń ṣọ́ bodè gun orí odi lọ, ó dúró lé orí òrùlé ẹnubodè. Bí ó ṣe gbé ojú sókè, ó rí ẹyọ ẹnìkan ṣoṣo tí ó ń sáré bọ̀.

25 Ó pe ọba nísàlẹ̀, ó sì sọ fún un, ọba bá dáhùn pé, “Bí ó bá jẹ́ òun nìkan ni, ìròyìn ayọ̀ ni ó ń mú bọ̀.” Ẹni tí ń sáré bọ̀ náà túbọ̀ ń súnmọ́ tòsí.

26 Ẹ̀ṣọ́ náà tún rí ẹyọ ẹnìkan, tí òun náà ń sáré bọ̀. Ó tún ké sí ẹ̀ṣọ́ tí ó wà ní ẹnu ọ̀nà, ó ní, “Wò ó, ẹnìkan ni ó tún ń sáré bọ̀ yìí.”Ọba dáhùn pé, “Ìròyìn ayọ̀ ni òun náà ń mú bọ̀.”

27 Ẹ̀ṣọ́ tún ní, “Ẹni tí ó ṣáájú tí mo rí yìí jọ Ahimaasi.”Ọba dáhùn pé, “Eniyan dáradára ni, ìròyìn ayọ̀ ni ó sì ń mú bọ̀.”

28 Ahimaasi bá kígbe sókè pé, “Alaafia ni!” Ó wólẹ̀, ó dojúbolẹ̀ níwájú ọba, ó sì wí fún un pé, “Ìyìn ni fún OLUWA Ọlọrun rẹ tí ó fún ọ ní ìṣẹ́gun lórí àwọn tí wọ́n dìtẹ̀ mọ́ ọba, oluwa mi.”

29 Ọba bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ṣé nǹkankan kò ṣe Absalomu ọmọ mi?”Ahimaasi dá ọba lóhùn pé, “Kabiyesi, nígbà tí Joabu fi ń rán mi bọ̀, gbogbo nǹkan dàrú, ó sì rí rúdurùdu, nítorí náà n kò lè sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ gan-an.”

30 Ọba bá ní kí ó dúró ní ẹ̀gbẹ́ kan ná, ó bá dúró.

31 Lẹ́yìn náà, ará Kuṣi náà dé, ó sì wí fún ọba pé, “Ìròyìn ayọ̀ ni mo mú wá fún oluwa mi, ọba! Nítorí pé, OLUWA ti fún ọ ní ìṣẹ́gun lónìí lórí gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ pa ọ́.”

32 Ọba bi í pé, “Ṣé alaafia ni Absalomu, ọmọ mi wà?”Ará Kuṣi náà dáhùn pé, “Kí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Absalomu ṣẹlẹ̀ sí gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ, ati gbogbo àwọn tí wọ́n dìtẹ̀ mọ́ ọ.”

33 Ìbànújẹ́ ńlá dé bá ọba, ó bá gun òkè lọ sinu yàrá tí ó wà lókè ẹnu ọ̀nà ibodè, ó sì sọkún. Bí ó ti ń lọ, bẹ́ẹ̀ ni ó ń ké pé, “Ha! Ọmọ mi! Absalomu, ọmọ mi! Absalomu, ọmọ mi! Ọmọ mi! Kì bá ṣe pé ó ṣeéṣe ni, kí n kú dípò rẹ, Absalomu, ọmọ mi, ọmọ mi!”

orí

1 2 3 4 5 6 7 8 9 10 11 12 13 14 15 16 17 18 19 20 21 22 23 24