Samuẹli Keji 16:4-10 BM

4 Ọba bá sọ fún Siba pé, “Gbogbo ohun tí ó jẹ́ ti Mẹfiboṣẹti di tìrẹ láti ìsinsìnyìí lọ.”Siba sọ fún ọba pé, “Kabiyesi, mo júbà, jọ̀wọ́, jẹ́ kí n máa bá ojurere rẹ pàdé nígbà gbogbo.”

5 Nígbà tí Dafidi ọba dé Bahurimu, ọkunrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ṣimei, ọmọ Gera, láti inú ìdílé Saulu, jáde sí i, bí ó sì ti ń bọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó ń ṣépè lemọ́lemọ́.

6 Ó ń sọ òkúta lu Dafidi ati gbogbo àwọn iranṣẹ rẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn eniyan ńláńlá ati ọpọlọpọ eniyan mìíràn wà ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji Dafidi ọba.

7 Ṣimei ń wí fún Dafidi bí ó ti ń ṣépè pé, “Kúrò lọ́dọ̀ mi! Kúrò lọ́dọ̀ mi! Ìwọ apànìyàn ati eniyan lásán!

8 Ìwọ tí o gba ìjọba mọ́ Saulu lọ́wọ́, OLUWA ń jẹ ọ́ níyà nisinsinyii, fún ọpọlọpọ eniyan tí o pa ninu ìdílé Saulu. OLUWA sì ti fi ìjọba rẹ fún Absalomu, ọmọ rẹ, ìparun ti dé bá ọ, nítorí pé apànìyàn ni ọ́.”

9 Abiṣai, ọmọ Seruaya wí fún ọba pé, “Kí ló dé tí òkú ajá lásánlàsàn yìí fi ń ṣépè lé ọba, oluwa mi? Jẹ́ kí n lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, kí n sì sọ orí rẹ̀ kalẹ̀ kúrò ní ọrùn rẹ̀.”

10 Ṣugbọn ọba dáhùn pé, “Kò sí ohun tí ó kan ẹ̀yin ọmọ Seruaya ninu ọ̀rọ̀ yìí. Kí ni n óo ti ṣe yín sí, ẹ̀yin ọmọ Seruaya? Bí ó bá jẹ́ pé OLUWA ni ó sọ fún un pé kí ó máa ṣépè lé mi, ta ló ní ẹ̀tọ́ láti bèèrè pé, kí ló dé tí ó fi ń ṣe bẹ́ẹ̀?”