18 Àwọn ọmọ Seruaya mẹtẹẹta, Joabu, Abiṣai, ati Asaheli, wà lójú ogun náà. Ẹsẹ̀ Asaheli yá nílẹ̀ pupọ, àfi bí ẹsẹ̀ àgbọ̀nrín.
19 Asaheli bẹ̀rẹ̀ sí lé Abineri lọ, bí ó sì ti ń lé e lọ, kò wo ọ̀tún, bẹ́ẹ̀ ni kò wo òsì.
20 Abineri bá bojúwo ẹ̀yìn, ó bèèrè pé, “Asaheli, ṣé ìwọ ni ò ń lé mi?”Asaheli sì dá a lóhùn pé, “Èmi ni.”
21 Abineri wí fún un pé, “Yà sí ọ̀tún, tabi sí òsì, kí o mú ọ̀kan ninu àwọn ọdọmọkunrin, kí o sì kó gbogbo ìkógun rẹ̀.” Ṣugbọn Asaheli kọ̀, kò yipada kúrò lẹ́yìn rẹ̀.
22 Abineri tún pe Asaheli, ó tún sọ fún un pé, “Pada lẹ́yìn mi, má jẹ́ kí n pa ọ́? Ojú wo ni o sì fẹ́ kí n fi wo Joabu ẹ̀gbọ́n rẹ?”
23 Ṣugbọn Asaheli kọ̀, kò pada. Abineri bá sọ ọ̀kọ̀ ní àsọsẹ́yìn, ọ̀kọ̀ sì lọ bá Asaheli ní ikùn, ọ̀kọ̀ náà sì yọ jáde lẹ́yìn rẹ̀. Asaheli wó lulẹ̀, ó sì kú síbi tí ó ṣubú sí. Gbogbo àwọn tí wọ́n bá ti dé ibi tí Asaheli kú sí, ni wọ́n ń dúró.
24 Ṣugbọn Joabu ati Abiṣai ń lé Abineri lọ, bí oòrùn ti ń lọ wọ̀, wọ́n dé ara òkè Ama tí ó wà níwájú Gia ní ọ̀nà aṣálẹ̀ Gibeoni.