2 Ọmọkunrin mẹfa ni wọ́n bí fún Dafidi nígbà tí ó wà ní Heburoni. Aminoni tí ìyá rẹ̀ ń jẹ́ Ahinoamu, ará Jesireeli, ni àkọ́bí.
3 Ekeji ni Kileabu, ọmọ Abigaili, opó Nabali, ará Kamẹli. Ẹkẹta ni Absalomu, ọmọ Maaka, ọmọ Talimai, ọba Geṣuri.
4 Ẹkẹrin ni Adonija ọmọ Hagiti. Ẹkarun-un ni Ṣefataya ọmọ Abitali.
5 Ẹkẹfa sì ni Itireamu, ọmọ Egila. Heburoni ni wọ́n ti bí àwọn ọmọ náà fún Dafidi.
6 Ní àkókò tí ogun wà láàrin àwọn eniyan Dafidi ati àwọn eniyan Saulu, agbára Abineri bẹ̀rẹ̀ sí pọ̀ sí i láàrin àwọn tí wọ́n wà lẹ́yìn Saulu.
7 Ní ọjọ́ kan, Iṣiboṣẹti ọmọ Saulu fi ẹ̀sùn kan Abineri pé ó bá obinrin Saulu kan, tí wọn ń pè ní Risipa, ọmọ Aya, lòpọ̀.
8 Ọ̀rọ̀ náà bí Abineri ninu gidigidi, ó bi Iṣiboṣẹti pé, “Ṣé o rò pé mo jẹ́ hu ìwà ọ̀dàlẹ̀ sí Saulu laelae? Àbí ẹ̀yìn àwọn ará Juda ni ẹ rò pé mo wà ni? Láti ìbẹ̀rẹ̀ ni mo ti jẹ́ olóòótọ́ sí Saulu baba rẹ, àwọn arakunrin rẹ̀ ati àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, èmi ni n kò sì ti jẹ́ kí apá Dafidi ká ọ. Ṣugbọn lónìí ńkọ́, ò ń fi ẹ̀sùn kàn mí nípa obinrin.