1 Lẹ́yìn náà, gbogbo àwọn ẹ̀yà Israẹli tọ Dafidi lọ ní Heburoni, wọ́n sọ fún un pé, “Ara kan náà ni wá, ẹ̀jẹ̀ kan náà sì ni gbogbo wa.
2 Látẹ̀yìn wá, nígbà tí Saulu pàápàá wà lórí oyè, ìwọ ni o máa ń kó àwọn ọmọ Israẹli lọ sógun. OLUWA sì ti ṣèlérí fún ọ pé, ìwọ ni o óo jẹ́ aṣiwaju àwọn eniyan rẹ̀, ati ọba wọn.”
3 Gbogbo àwọn àgbààgbà Israẹli wá sí ọ̀dọ̀ ọba ní Heburoni, Dafidi ọba sì bá wọn dá majẹmu níbẹ̀ níwájú OLUWA. Wọ́n bá fi òróró yan Dafidi ní ọba lórí Israẹli.
4 Ẹni ọgbọ̀n ọdún ni, nígbà tí ó gorí oyè, ó sì jọba fún ogoji ọdún.
5 Ọdún meje ati oṣù mẹfa ni ó fi jọba lórí ẹ̀yà Juda ní Heburoni. Lẹ́yìn náà, ó wá sí Jerusalẹmu ó sì jọba lórí gbogbo Israẹli ati Juda fún ọdún mẹtalelọgbọn.
6 Nígbà tí ó yá, Dafidi ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ gbógun ti ìlú Jerusalẹmu. Àwọn ará Jebusi tí wọn ń gbé ibẹ̀ nígbà náà wí fún Dafidi pé, “O kò lè wọ inú ìlú yìí wá, àwọn afọ́jú ati àwọn arọ lásán ti tó láti lé ọ dànù.” Wọ́n lérò pé Dafidi kò le ṣẹgun ìlú náà.