1 Igbagbọ ni ìdánilójú ohun tí à ń retí, ẹ̀rí tí ó dájú nípa àwọn ohun tí a kò rí.
2 Igbagbọ ni àwọn àgbà àtijọ́ ní, tí wọ́n fi ní ẹ̀rí rere.
3 Nípa igbagbọ ni ó fi yé wa pé ọ̀rọ̀ ni Ọlọrun fi dá ayé, tí ó fi jẹ́ pé ohun tí a kò rí ni ó fi ṣẹ̀dá ohun tí a rí.
4 Nípa igbagbọ ni Abeli fi rú ẹbọ tí ó dára ju ti Kaini lọ sí Ọlọrun. Igbagbọ rẹ̀ ni ẹ̀rí pé a dá a láre, nígbà tí Ọlọrun gba ọrẹ rẹ̀. Nípa igbagbọ ni ó fi jẹ́ pé bí ó tilẹ̀ ti kú, sibẹ ó ń sọ̀rọ̀.
5 Nípa igbagbọ ni a fi mú Enọku kúrò ní ayé láìjẹ́ pé ó kú. Ẹnikẹ́ni kò rí i mọ́ nítorí pé Ọlọrun ti mú un lọ. Nítorí kí ó tó mú un lọ, Ìwé Mímọ́ sọ nípa rẹ̀ pé, “Ó ṣe ohun tí ó wu Ọlọrun.”
6 Láìsí igbagbọ eniyan kò lè ṣe ohun tí ó wu Ọlọrun. Nítorí ẹni tí ó bá wá sọ́dọ̀ Ọlọrun níláti gbàgbọ́ pé Ọlọrun wà, ati pé òun ni ó ń fún àwọn tí ó bá ń wá a ní èrè.