13 Ẹni tí à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí wá láti inú ẹ̀yà mìíràn. Ninu ẹ̀yà yìí ẹ̀wẹ̀, kò sí ẹnikẹ́ni tí ó ní nǹkankan ṣe pẹlu ẹbọ rírú.
14 Nítorí ó hàn gbangba pé láti inú ẹ̀yà Juda ni Oluwa wa ti wá. Mose kò sì sọ ohunkohun tí ó jẹ mọ́ iṣẹ́ alufaa nípa ẹ̀yà yìí.
15 Ohun tí à ń sọ hàn kedere nígbà tí a rí i pé a yan alufaa mìíràn gẹ́gẹ́ bí àwòrán Mẹlikisẹdẹki,
16 ẹni tí ó di alufaa nípa agbára ìyà tí kò lópin, tí kì í ṣe nípa ìlànà àṣẹ tí a ti ọwọ́ eniyan ṣe ètò.
17 Nítorí a rí ẹ̀rí níbìkan pé,“Ìwọ yóo jẹ́ alufaa títí lae,gẹ́gẹ́ bíi ti Mẹlikisẹdẹki.”
18 A pa àṣẹ ti àkọ́kọ́ tì nítorí kò lágbára, kò sì wúlò.
19 Nítorí kò sí ohun tí òfin sọ di pípé. A wá ṣe ètò ìrètí tí ó dára ju òfin lọ nípa èyí tí a lè fi súnmọ́ Ọlọrun.