19 Nítorí kò sí ohun tí òfin sọ di pípé. A wá ṣe ètò ìrètí tí ó dára ju òfin lọ nípa èyí tí a lè fi súnmọ́ Ọlọrun.
20 Ìrètí yìí ní ìbúra ninu. Àwọn ọmọ Lefi di alufaa láìsí ìbúra.
21 Ṣugbọn pẹlu ìbúra ni, nígbà tí Ọlọrun sọ fún un pé,“Oluwa ti búra,kò ní yí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pada:‘Ìwọ máa jẹ́ alufaa títí lae.’ ”
22 Báyìí ni Jesu ṣe di onígbọ̀wọ́ majẹmu tí ó dára ju ti àtijọ́ lọ.
23 Àwọn alufaa ìdílé Lefi pọ̀ nítorí ikú kò jẹ́ kí èyíkéyìí ninu wọn lè wà títí ayé.
24 Ṣugbọn ní ti Jesu, ó wà títí. Nítorí náà kò sí ìdí tí a óo fi tún yan alufaa mìíràn dípò rẹ̀.
25 Ìdí nìyí tí ó fi lè gba àwọn tí wọ́n bá súnmọ́ Ọlọrun nípasẹ̀ rẹ̀ là, lọ́nà gbogbo títí lae nítorí pé ó wà láàyè títí láti máa bẹ̀bẹ̀ fún wọn.